Turkmenistan
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Turkmenistan
-
Àwọn Ẹlẹ́rìí tí Wọ́n Fi Sẹ́wọ̀n Torí Ohun tí Wọ́n Gbà Gbọ́—0
Orílẹ̀-Èdè Turkmenistan Gbójú Fo Òmìnira Láti Ṣe Ohun Tó Bá Ẹ̀rí Ọ̀kan Ẹni Mu
Wọ́n ju méjì lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sẹ́wọ̀n torí pé wọ́n kọ̀ láti ṣiṣẹ́ ológun torí ohun tí wọ́n gbà gbọ́. Orílẹ̀-èdè Turkmenistan ò tíì gbà pé èèyàn ní ẹ̀tọ́ láti kọ ohun tí ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ ò gbà bí wọ́n bá ní kó wá ṣe iṣẹ́ ológun, kò sì ṣètò iṣẹ́ àṣesìnlú míì dípò iṣẹ́ ológun.
Ṣé Ìjọba Turkmenistan Máa Tẹ̀ Lé Àwọn Ìpinnu tí Ìgbìmọ̀ Tó Ń Rí sí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn Lábẹ́ Ìdarí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-èdè Ṣe?
Wọ́n ní kí ìjọba Turkmenistan tẹ̀ lé àdéhùn tí wọ́n ṣe láti má fi ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn du ẹnikẹ́ni, kí wọ́n sì jẹ́ káwọn èèyàn lómìnira èrò, ẹ̀rí ọkàn àti ẹ̀sìn.
Ṣé Wọ́n Máa Dá Bahram Hemdemov Sílẹ̀ Nígbà Tí Ìjọba Bá Tún Ń Dá Àwọn Ẹlẹ́wọ̀n Sílẹ̀?
Àwọn Ẹlẹ́rìí ń retí pé kí ààrẹ orílẹ̀-èdè Turkmenistan, ìyẹn Gurbanguly Berdimuhamedov dá Bahram sílẹ̀ lẹ́wọ̀n nígbà tó bá tún ń dá àwọn ẹlẹ́wọ̀n sílẹ̀.
Orílẹ̀-èdè Turkmenistan Yẹ Kó Wá Nǹkan Ṣe sí Bí Wọ́n Ṣe Tẹ Òfin Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn Lójú
Nínú ìpinnu mẹ́rin kan tí Ìgbìmọ̀ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè Tó Ń Rí sí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ṣe lẹ́nu àìpẹ́ yìí, wọ́n sọ pé ìjọba orílẹ̀-èdè Turkmenistan fìyà tí kò tọ́ jẹ àwọn ọkùnrin tó kọ̀ láti ṣe ohun tí ẹ̀rí ọkàn wọn ò fàyè gbà.
Ìjọba Orílẹ̀-èdè Turkmenistan Dá Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí Wọ́n Fi Sẹ́wọ̀n Torí Ohun tí Wọ́n Gbà Gbọ́ Sílẹ̀
Ní October 22, 2014, lórílẹ̀-èdè Turkmenistan, Ààrẹ Berdimuhamedov dá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mẹ́jọ tí wọ́n fi sẹ́wọ̀n torí ohun tí wọ́n gbà gbọ́ sílẹ̀.
Wọ́n Dá Ìyá Ọlọ́mọ Sílẹ̀ Lẹ́wọ̀n ní Turkmenistan
Wọ́n dá Bibi Rahmanova sílẹ̀ lẹ́wọ̀n ní September 2, 2014, láì retí pé wọ́n á ṣe bẹ́ẹ̀. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé kárí ayé làwọn èèyàn ò ti fara mọ́ ẹ̀sùn èké tí wọ́n fi kan obìnrin yìí, àwọn adájọ́ ṣì sọ pé ó jẹ̀bi ẹ̀sùn yìí.