Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

JANUARY 30, 2017
KÒLÓŃBÍÀ

Àjọ Àwọn Atúmọ̀ Èdè Adití ní Kòlóńbíà Fún Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ní Àmì Ẹ̀yẹ

Àjọ Àwọn Atúmọ̀ Èdè Adití ní Kòlóńbíà Fún Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ní Àmì Ẹ̀yẹ

Àmì ẹ̀yẹ tí wọ́n fún àwọn Ẹlẹ́rìí torí pé mọrírì bí wọ́n ṣe ń ṣe àwọn ohun tó dá lórí Bíbélì jáde fáwọn adití tó wà ní Kòlóńbíà.

ÌLÚ BOGOTA, lórílẹ̀-èdè Kòlóńbíà—Níbi ìpàdé àpérò tó wáyé ní October 7-9, 2016, àjọ ANISCOL, ìyẹn Àjọ Àwọn Atúmọ̀ Èdè Adití àti Àwọn Tó Ń Ṣèrànwọ́ Lẹ́nu Iṣẹ́ Ìtúmọ̀ Èdè ní Kòlóńbíà, pẹ̀lú àwọn àjọ méjì míì, fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní àmì ẹ̀yẹ torí àwọn ohun tí wọ́n ń ṣe jáde lédè adití. Ìpàdé àpérò àkọ́kọ́ tí wọ́n máa ṣètò lórílẹ̀-èdè náà nìyí, fáwọn tó ń túmọ̀ èdè adití àtàwọn tó ń ṣèrànwọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìtúmọ̀ èdè, tí wọ́n ń ṣèrànwọ́ fáwọn tó fọ́jú tí wọ́n sì tún dití lórílẹ̀-èdè Kòlóńbíà.

Wọ́n ní káwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wá síbi ìpàdé àpérò náà kí wọ́n lè fún wọn ní àmì ẹ̀yẹ torí wọ́n mọrírì “iṣẹ́ àrà ọ̀tọ̀ tí wọ́n ń ṣe láti ṣe ìwé àti fídíò tó dá lórí ẹ̀sìn jáde fáwọn adití àti ipa rere tí wọ́n ń ní lórí ayé àwọn adití tó wà ní Kòlóńbíà.” Ricardo Valencia López wà lára àwọn tó ṣètò ìpàdé àpérò yìí, òun sì tún ni ààrẹ àjọ ASINTEC, ìyẹn Àjọ Àwọn Atúmọ̀ Èdè Adití Lọ́nà ti Kòlóńbíà àti Àwọn Tó Ń Ṣèrànwọ́ Lẹ́nu Iṣẹ́ Ìtúmọ̀ Èdè lágbègbè tí wọ́n ti ń gbin igi kọfí lórílẹ̀-èdè Kòlóńbíà. Ọ̀gbẹ́ni náà ṣàlàyé pé ara ohun tó mú kí wọ́n pe àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wá sípàdé náà ni bí wọ́n ṣe “pa kún ìtẹ̀síwájú iṣẹ́ ìtúmọ̀ èdè adití pẹ̀lú àwọn ohun tí wọ́n ń fara balẹ̀ ṣe jáde lédè adití, èyí táwọn tó ń wá ìsọfúnni lè kàn sí, tó sì ṣeé tọ́ka sí pé ó jẹ́ àpẹẹrẹ tó dáa.”

Ọ̀rọ̀ táwọn Ẹlẹ́rìí sọ wú àwọn èèyàn lórí gan-an, ni ìgbìmọ̀ tó ṣètò ìpàdé náà bá tún fún wọn ní àmì ẹ̀yẹ míì.

Nínú ìpàdé yẹn, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sọ àwọn ìrírí tí wọ́n ti ní lẹ́nu iṣẹ́ ìtúmọ̀ èdè. Àwọn ìrírí wọn wú àwọn tó wà níbẹ̀ lórí débi pé ìgbìmọ̀ tó ṣètò ìpàdé náà fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní àmì ẹ̀yẹ míì, torí ọ̀rọ̀ rere táwọn tó wá síbi àpérò náà ń sọ nípa ohun tí àwọn Ẹlẹ́rìí ṣe.

Cristian David Valencia láti ìlú Pereira, tó máa ń fi kọ̀ǹpútà ṣe àwòrán àtàwọn ohun àtẹ́tísí, wá síbi ìpàdé náà. Ó sọ pé “ó ya òun lẹ́nu pé ẹ̀sìn kan lè ṣètò láti máa dá àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ lọ́nà tó yarantí báyìí,” pàápàá bó tún ṣe jẹ́ pé wọn kì í fi iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe yìí pawó.

Wilson Torres, tó jẹ́ agbẹnusọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Kòlóńbíà sọ pé: “Àtọdún 2000 la ti ń ṣe àwọn ohun kan jáde lédè adití lórílẹ̀-èdè yìí. Lórí ìkànnì wa lásán, fídíò tó lé ní ọgọ́rùn-ún mẹ́rin [400] ló wà níbẹ̀ fáwọn àgbàlagbà, àwọn ọ̀dọ́ àtàwọn ọmọdé tó ń sọ Èdè Àwọn Adití Lọ́nà ti Kòlóńbíà. Àá túbọ̀ máa ṣe àwọn ohun tó dá lórí Bíbélì yìí jáde lọ́fẹ̀ẹ́, bíi ti gbogbo ìwé, fídíò àti ohun àtẹ́tísí tá à ń ṣe jáde.”

Èdè méjìdínláàádọ́rùn-ún [88] tó jẹ́ tàwọn adití làwọn atúmọ̀ èdè tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi ń ṣe fídíò jáde kárí ayé, tí wọ́n sì ń pín in fáwọn èèyàn. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tún ti ṣe ètò kan tó ń ṣiṣẹ́ lórí fóònù àti kọ̀ǹpútà, ìyẹn JW Library Sign Language app, tó jẹ́ kó rọrùn láti wa fídíò jáde tàbí kéèyàn wò ó látorí ìkànnì wọn, jw.org.

Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:

Kárí Ayé: David A. Semonian, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, +1-845-524-3000

Kòlóńbíà: Wilson Torres, +57-1-8911530