Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

DECEMBER 2, 2020
ÌRÒYÌN KÁRÍ AYÉ

Ìjì Líle Iota Ṣọṣẹ́ ní Kòlóńbíà, Ó sì Tún Ba Ọ̀pọ̀ Nǹkan Jẹ́ ní Central America àti Mẹ́síkò

Ìjì Líle Iota Ṣọṣẹ́ ní Kòlóńbíà, Ó sì Tún Ba Ọ̀pọ̀ Nǹkan Jẹ́ ní Central America àti Mẹ́síkò

Ibi tó ti ṣẹlẹ̀

Central America, Kòlóńbíà àti Mẹ́síkò

Ohun tó ṣẹlẹ̀

  • Ní November 15 sí 16, 2020, ìjì líle Iota ba ọ̀pọ̀ nǹkan jẹ́ lápá àríwá orílẹ̀-èdè Kòlóńbíà, ní pàtàkì lérékùṣù San Andrés àti Providencia tó wà lórí Òkun Caribbean

  • Ìjì líle yìí àti òjò àrọ̀ọ̀rọ̀dá fa omíyalé, ó sì mú kí ilẹ̀ ya

  • Ní November 16, 2020, ìjì líle Iota mú kí ilẹ̀ ya ní Nikarágúà, lẹ́yìn náà ó ṣọṣẹ́ láwọn apá ibì kan ní Central America, ó sì ba ọ̀pọ̀ nǹkan jẹ́ láfikún sí ohun tí ìjì líle Eta ti bà jẹ́ níbẹ̀rẹ̀ oṣù yẹn

Bí ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn ṣe kan àwọn ará wa

Central America

  • Costa Rica

    • Àwọn akéde méjìlélógún (22) fi ilé wọn sílẹ̀

  • Guatemala

    • Àwọn akéde mẹ́tàléláàádọ́rùn-ún (93) fi ilé wọn sílẹ̀

  • Honduras

    • Àwọn akéde tó tó ẹgbẹ̀rún kan, ọgọ́rùn-ún márùn-ún àti mọ́kànlélọ́gbọ̀n (1,531) fi ilé wọn sílẹ̀

    • Àwọn akéde méjì fara pa díẹ̀

  • Nikarágúà

    • Àwọn akéde márùndínlọ́gọ́rin (75) fi ilé wọn sílẹ̀

  • Panama

    • Àwọn akéde mẹ́rìndínlógún (16) fi ilé wọn sílẹ̀

Kòlóńbíà

    • Akéde kan kán lápá ní Providencia

    • Akéde kan fara pa díẹ̀ ní San Andrés

Mẹ́síkò

    • Àwọn akéde tó tó ẹgbẹ̀rún kan, ọgọ́rùn-ún méjì àti méjìdínláàádọ́ta (1,248) fi ilé wọn sílẹ̀ ní Tabasco àti Veracruz

Àwọn nǹkan tó bà jẹ́

Central America

  • Costa Rica

    • Ilé mẹ́sàn-án bà jẹ́

  • Guatemala

    • Ilé méjìdínlógún (18) bà jẹ́

    • Gbọ̀ngàn Ìjọba méje bà jẹ́ díẹ̀

    • Gbọ̀ngàn Ìjọba méjì bà jẹ́ kọjá àtúnṣe

  • Honduras

    • Gbọ̀ngàn Ìjọba méje bà jẹ́ díẹ̀

    • Ilé ọgọ́rùn-ún méjì àti mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n (227) bà jẹ́

  • Nikarágúà

    • Ilé ọgọ́rùn-ún kan ó lé mẹ́fà (106) bà jẹ́

    • Gbọ̀ngàn Ìjọba mẹ́ta bà jẹ́ díẹ̀

  • Panama

    • Ilé márùn-ún bà jẹ́ díẹ̀

    • Gbọ̀ngàn Ìjọba méjì bà jẹ́ kọjá àtúnṣe

Kòlóńbíà

    • Ìròyìn tá a kọ́kọ́ gbọ́ ni pé èyí tó pọ̀ jù lára àwọn ará wa ní Providencia nilé wọn bà jẹ́ gan-an àti pé Gbọ̀ngàn Ìjọba kan bà jẹ́ kọjá àtúnṣe. Àmọ́ látìgbà yẹn, kò tíì rọrùn fún wa láti gbọ́ nǹkan kan látọ̀dọ̀ àwọn ará tó wà lérékùṣù yẹn torí pé ìjì yẹn ti ba iná mànàmáná wọn jẹ́ àti ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ wọn

    • Ní San Andrés, ilé tó tó ogún (20) àti Gbọ̀ngàn Ìjọba kan bà jẹ́ díẹ̀

Mẹ́síkò

    • Ilé ọgọ́rùn-ún kan àti mẹ́rìnlélọ́gọ́rin (184) ló bà jẹ́

Gbọ̀ngàn Ìjọba Providencia ní Kòlóńbíà ṣáájú kí ìjì líle Iota tó jà àti lẹ́yìn tó jà

Bá a ṣe ran àwọn ará wa lọ́wọ́

  • Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka orílẹ̀-èdè Kòlóńbíà ti yan Ìgbìmọ̀ Tó Ń Ṣètò Ìrànwọ́ Nígbà Àjálù láti ran àwọn ará wa lọ́wọ́. Ìgbìmọ̀ yìí àti alábòójútó àyíká tó wà lágbègbè yẹn ń ṣiṣẹ́ pa pọ̀ láti pèsè ìrànwọ́ fáwọn ará, wọ́n sì ń fi Bíbélì tù wọ́n nínú

  • Ẹ̀ka ọ́fíìsì Central America yan Ìgbìmọ̀ mẹ́rin tó ń pèsè ìrànwọ́ fáwọn ará tó wà níbi tí ìjì líle Eta àti Iota ti ṣọṣẹ́ ní Central America àti Mẹ́síkò. Àwọn alábòójútó àyíká ń fi Bíbélì tú àwọn ìdílé tọ́rọ̀ kàn nínú, wọ́n sì ń fún wọn láwọn ìmọ̀ràn tó lè ràn wọ́n lọ́wọ́. Bákan náà, àwọn ìjọ tó wà nítòsí ibi tọ́rọ̀ náà ti ṣẹlẹ̀ ti fi ohun tó ju ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (400) ẹrù oúnjẹ ránṣẹ́ sáwọn ará ní Honduras àti Nikarágúà. Tí wọ́n bá rí i pé ó pọn dandan, àwọn tó ń gbé níbi tí ìjì yẹn ò dé ń gba àwọn tí ìjì náà ba ilé wọn jẹ́ sílé

  • Àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin tó wà lára àwọn tó ń pèsè ìrànwọ́ rí i pé àwọn ń tẹ̀ lé gbogbo òfin táwọn elétò ààbò ṣe lórí àrùn Corona

Kò sí báwọn ará wa ò ṣe ní fara gbá àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ayé yìí, títí kan àjálù bí irú èyí. Síbẹ̀ wọn gbára lé Jèhófà pé ó máa dáàbò bo àwọn.​—Sáàmù 142:5.