JANUARY 30, 2017
ERITREA
Ẹlẹ́rìí Jèhófà Míì Tó Jẹ́ Ọmọ Ilẹ̀ Eritrea Kú Lẹ́yìn tí Wọ́n Dá A Sílẹ̀ Lẹ́wọ̀n
Tsehaye Tesfamariam kú sílùú Asmara ní November 30, 2016. Wọ́n dá a sílẹ̀ lẹ́wọ̀n ní September 10, 2015 torí pé ara rẹ̀ ò yá rárá, wọn ò sì tọ́jú ẹ̀ ní gbogbo ìgbà tó fi wà lẹ́wọ̀n. Ọdún 1941 ni wọ́n bí i, nílùú Nefasit, lórílẹ̀-èdè Eritrea. Ó ṣì níyàwó, Hagosa Kebreab lorúkọ ẹ̀, ọdún 1973 ni wọ́n ṣègbéyàwó. Wọ́n bí ọmọbìnrin mẹ́rin àti ọmọkùnrin mẹ́ta. Lọ́dún 1958, ó ṣèrìbọmi, ó sì di Ẹlẹ́rìí Jèhófà.
Ní January 2009, àwọn aláṣẹ mú Ọ̀gbẹ́ni Tesfamariam, àmọ́ wọn ò sọ ohun tí wọ́n ló ṣe táwọn fi mú un. Wọ́n wá fi sẹ́wọ̀n ní Ọgbà Ẹ̀wọ̀n Meitir. Ní October 5, 2011, àwọn aláṣẹ kó Ọ̀gbẹ́ni Tesfamariam àtàwọn ọkùnrin mẹ́rìnlélógún [24] míì tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń ṣẹ̀wọ̀n ní Ọgbà Ẹ̀wọ̀n Meitir lọ sínú ilé kan tí wọ́n fi irin ṣe, wọ́n láwọn fẹ́ fi fìyà tó ṣàrà ọ̀tọ̀ jẹ wọ́n. Ìdajì ilé onírin yìí ni wọ́n rì mọ́lẹ̀, ibẹ̀ làwọn ọkùnrin yìí sì wà títí di August 2012. Nǹkan nira gan-an fún wọn lásìkò ẹ̀ẹ̀rùn, torí ooru mú gan-an nígbà yẹn, oúnjẹ àti omi tí wọ́n ń fún wọn ò sì tó. Èyí kó bá ìlera ọ̀pọ̀ nínú wọn, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàìsàn gan-an.
Ojú wọn rí nǹkan! Ó ṣeni láàánú pé Misghina Gebretinsae àti Yohannes Haile kú sí Ọgbà Ẹ̀wọ̀n Meitir, Kahssay Mekonnen àti Goitom Gebrekristos sì kú lẹ́yìn tí wọ́n dá wọn sílẹ̀ lẹ́wọ̀n. Ọ̀gbẹ́ni Tesfamariam náà ti kú báyìí.