A Pè Ẹ́ Kó O Wá Wo Àwọn Ọ́fíìsì Wa Tó Wà ní Bẹ́tẹ́lì Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà
“Títí láé la ó máa rántí àkókò alárinrin tá a lò ní Bẹ́tẹ́lì nígbà tá a lọ ṣèbẹ̀wò síbẹ̀.” Ohun tí tọkọtaya kan láti orílẹ̀-èdè Vanuatu sọ nìyẹn lẹ́yìn tí wọ́n wá wo ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Bó ṣe máa ń rí lára ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn tó ń wá síbẹ̀ lọ́dọọdún nìyẹn.
Ṣé o ti wá wo àwọn ọ́fíìsì wa mẹ́ta tó wà ní Bẹ́tẹ́lì orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà? Tó ò bá tíì wá, a rọ̀ ẹ́ pé kó o wá.
Kí lo máa rí ní ọ́fíìsì mẹ́tẹ̀ẹ̀ta?
Oríléeṣẹ́, nílùú Warwick, ní New York. O máa rí àtẹ ńlá mẹ́ta tó o lè wò fúnra ẹ láìsí ẹni tó ń mú ẹ yí ká. Àkòrí ọ̀kan nínú wọn ni “The Bible and the Divine Name,” tó o ti máa rí àwọn Bíbélì tó ṣọ̀wọ́n, tó sì máa jẹ́ kó o mọ bí Ọlọ́run ò ṣe jẹ́ kí wọ́n yọ orúkọ òun kúrò nínú Bíbélì. Òmíì ni, “A People for Jehovah’s Name,” tó dá lórí ìtàn àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ìkẹta ni, “World Headquarters—Faith in Action,” tó ṣàlàyé bí a ṣe ṣètò àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà láti máa pàdé pọ̀, láti máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, láti máa sọ̀rọ̀ Bíbélì fáwọn èèyàn àti bá a ṣe ń fìfẹ́ hàn sí ara wa. Ètò tún wà láti fi ogún 20 ìṣẹ́jú mú ẹ rìn yí ká àwọn ibì kan ní Àwọn Ọ́fíìsì àti Ilé Tó Wà fún Onírúurú Iṣẹ́, pẹ̀lú ọgbà Warwick.
Ibùdó Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ti Watchtower, ní Patterson, New York. Wàá mọ̀ nípa àwọn ilé ẹ̀kọ́ tó wà níbẹ̀, bí Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì àti Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka Àtàwọn Ìyàwó Wọn. Wàá tún rí àwọn àwòrán àtàwọn fídíò tó sọ̀rọ̀ nípa iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe ní àwọn ẹ̀ka kan, bíi Ẹ̀ka Iṣẹ́ Ọnà àti Ẹ̀ka Ìgbohùnsílẹ̀ àti Fídíò.
Ibi Tá A Ti Ń Tẹ̀wé, Tá A sì Ń Kó O Ránṣẹ́, nílùú Wallkill, ní New York. A máa mú ẹ rìn yí ká kó o lè rí bá a ṣe ń tẹ Bíbélì àtàwọn ìwé tó dá lórí Bíbélì, tá à ń dì í, tá a sì ń kó o ránṣẹ́ sí àwọn ìjọ lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, àgbègbè Caribbean àtàwọn ibòmíì láyé.
Báwo ni mo ṣe lè forúkọ sílẹ̀ pé mo fẹ́ wá?
Kó o tó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣètò bó o ṣe máa wá, jọ̀ọ́ kọ́kọ́ lọ sí abala ìsọfúnni nípa Ọ́fíìsì àti Rírìn Yí Ká Ọgbà lórí ìkànnì wa. Ní abala yìí, wàá rí àlàyé sí i nípa àwọn ọ́fíìsì wa tó wà ní Bẹ́tẹ́lì ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, títí kan ibi tí wọ́n wà àti àkókò tó máa gbà ẹ́ láti ṣèbẹ̀wò sí ọ́fíìsì ọ̀kọ̀ọ̀kan.
Àwọn wo ló máa mú ẹ yí ká ibẹ̀?
Àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ní Bẹ́tẹ́lì ló máa ń mú àwọn èèyàn yí ká, oríṣiríṣi ẹ̀ka sì ni wọ́n ti ń ṣiṣẹ́. Wọ́n gbà pé bí àwọn ṣe ń mú àwọn èèyàn rìn yí ká àwọn ọ́fíìsì yìí, ṣe làwọn ń kọ́wọ́ ti iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ tá à ń ṣe kárí ayé. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ èdè ni wọ́n fi máa ń ṣàlàyé bí ọ́fíìsì wa ṣe rí fáwọn tó wá wo ibẹ̀.
Èló ni màá san tí mo bá fẹ́ wá wo ibẹ̀?
A kì í gba owó.
Ṣé dandan ni kó o jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà kó o tó lè wá?
Rárá o. Ọ̀pọ̀ àwọn tó máa ń wá kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Gbogbo àwọn tó bá wá, ì báà jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà tàbí ẹlẹ́sìn míì, ló máa rí bí àwọn èèyàn ṣe ń sapá láti ti iṣẹ́ táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe kárí ayé lẹ́yìn.
Obìnrin kan láti Íńdíà wá wo ọ́fíìsì wa ní Patterson. Mùsùlùmí ni. Lẹ́yìn tó rìn yí ká ibẹ̀, ó sọ pé: “Èmi náà á fẹ́ kọ́wọ́ ti iṣẹ́ yìí. Ẹ ṣeun gan-an tẹ́ ẹ fọ̀wọ̀ mi wọ̀ mí o.”
Ṣé àwọn ọmọdé lè wá?
Bẹ́ẹ̀ ni! Táwọn ọmọ tí kò tíì dàgbà bá wá síbẹ̀, ó lè nípa rere lórí wọn. John, tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, tóun náà wá wo ọ́fíìsì wa, kọ̀wé pé: “Látìgbà tá a ti pa dà délé láti Bẹ́tẹ́lì, àwọn ọmọdé tá a jọ lọ ò yéé sọ̀rọ̀ nípa bí ọ̀hún ṣe rí. Kó tó di pé a lọ, wọn ò mọ bó ṣe rí kéèyàn máa ṣiṣẹ́ ní Bẹ́tẹ́lì. Àmọ́ ní báyìí, wọ́n ti ní in lọ́kàn pé táwọn bá dàgbà, àwọn á lọ máa ṣiṣẹ́ ní Bẹ́tẹ́lì.”
Ṣé ó ṣeé ṣe kéèyàn lọ wo ọ́fíìsì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà láwọn orílẹ̀-èdè míì?
Bẹ́ẹ̀ ni. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè ni ètò ti wà pé káwọn èèyàn wá wo ọ́fíìsì wa. Tó o bá fẹ́ mọ ibi tí ọ́fíìsì wa wà ní orílẹ̀-èdè kan, lọ sí abala ìsọfúnni nípa Ọ́fíìsì àti Rírìn Yí Ká Ọgbà lórí ìkànnì wa. Tayọ̀tayọ̀ la pè ẹ́ kó o wá wo ọ̀kan lára ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà.