Ǹjẹ́ Ẹ Máa Ń Yẹra Fún Àwọn Tí Kò Ṣe Ẹ̀sìn Yín Mọ́?
A kì í yẹra fún àwọn tó ti ṣèrìbọmi tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọn kò wàásù mọ́, títí kan àwọn tó tiẹ̀ jáwọ́ nínú dídara pọ̀ mọ́ àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́. Kódà a máa ń wá irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lọ ká lè mú kí ìfẹ́ tí wọ́n ní fún ìjọsìn Ọlọ́run sọ jí.
A kì í ṣàdédé yọ ẹni tó hùwà àìtọ́ tó burú jáì lẹ́gbẹ́. Àmọ́ ṣá o, bí Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan tó ti ṣe ìrìbọmi bá sọ ọ́ di àṣà láti máa rú àwọn ìlànà inú Bíbélì, tí kò sì ronú pìwà dà, a máa yẹra fún onítọ̀hún tàbí ká yọ ọ́ lẹ́gbẹ́. Bíbélì sọ ní kedere pé: “Ẹ mú ènìyàn burúkú náà kúrò láàárín ara yín.”—1 Kọ́ríńtì 5:13.
Tó bá jẹ́ ọkùnrin kan ni wọ́n yọ lẹ́gbẹ́ tí ìyàwó àti ọmọ rẹ̀ ṣì jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà ńkọ́? Ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn kò pa òun àti ìdílé rẹ̀ pọ̀ mọ́, àmọ́ àjọṣe wọn nínú ìdílé kò yí pa dà. Èyí kò ní fòpin sí ìgbéyàwó wọn, ìfẹ́ tó sì wà láàárín ìdílé àti àjọṣe wọn á máa bá a nìṣó.
Ẹni tí wọ́n ti yọ lẹ́gbẹ́ lè máa wá sí àwọn ìpàdé wa. Bí wọ́n bá fẹ́ wọ́n lè gba ìmọ̀ràn tó dá lórí àjọṣe wọn pẹ̀lú Ọlọ́run lọ́dọ̀ àwọn alàgbà ìjọ. Àfojúsùn wa ni pé ká ran irú ẹni bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́ láti tún pa dà di ọ̀kan lára àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. A máa ń gba ẹni tá a yọ lẹ́gbẹ́ pa dà sínú ìjọ tó bá ti jáwọ́ nínú àwọn ìwà tí kò bójú mu, tó sì tún fi hàn látọkàn wá pé òun fẹ́ máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì.