Ibo Làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ti Ń Rówó Tí Wọ́n Ń Ná?
Ọrẹ àtinúwá táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe ló pọ̀ jù lára owó tá à ń ná lórí iṣẹ́ wa kárí ayé. a Àpótí ọrẹ máa ń wà láwọn ilé ìpàdé wa, èèyàn tún lè ṣètìlẹyìn ní apá tá a pè ní Ọrẹ lórí ìkànnì wa. Oríṣiríṣi ọ̀nà lẹnì kan lè gbà fi owó ránṣẹ́ níbẹ̀, yálà láti ṣètìlẹyìn fún iṣẹ́ kárí ayé tàbí fún ìnáwó ìjọ, ó sì lè jẹ́ fún méjèèjì.
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í san ìdámẹ́wàá, wọn ò sì retí pé kéèyàn ya iye kan sọ́tọ̀ láti máa fi ṣètìlẹyìn. (2 Kọ́ríńtì 9:7) A ò kì í gbé igbá ọrẹ tàbí gba owó ìwọlé, bákan náà àwọn òjíṣẹ́ wa kì í gbowó tí wọ́n bá ṣèrìbọmi fún ẹnì kan, tí wọ́n bá bójú tó ètò ìsìnkú, tí wọ́n bá so tọkọtaya pọ̀ tàbí tí wọ́n bá darí àwọn ètò ìsìn míì. A kì í ná ọjà bàsá, a kì í ṣe àwọn ayẹyẹ tàbí àjọ̀dún láti fi kówó jọ, a kì í sì í tọrọ owó lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni. A kì í kéde orúkọ àwọn tó bá ṣètìlẹyìn. (Mátíù 6:2-4) A kì í bá àwọn oníṣòwò polówó ọjà lórí ìkànnì wa tàbí nínú àwọn ìtẹ̀jáde wa.
Oṣooṣù làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń ka ìsọfúnni nípa bí wọ́n ṣe náwó nínú ìjọ. Wọ́n máa ń tọ́jú àkọsílẹ̀ nípa bí wọ́n ṣe ń náwó, wọ́n sì ń ṣàyẹ̀wò ẹ̀ lóòrèkóòrè kí wọ́n lè rí i pé wọ́n ná owó táwọn èèyàn fi ṣètìlẹyìn bó ṣe yẹ.—2 Kọ́ríńtì 8:20, 21.
Bá A Ṣe Ń Ṣètọrẹ
Àpótí ọrẹ: A máa ń fi owó tàbí sọ̀wédowó sínú àpótí ní Gbọ̀ngàn Ìjọba, Gbọ̀ngàn Àpéjọ tàbí àwọn ibi míì tá a ti ń ṣèpàdé.
Ọrẹ látorí íńtánẹ́ẹ̀tì: Lọ́pọ̀ orílẹ̀-èdè, èèyàn lè fowó ránṣẹ́, èèyàn lè lo káàdì tí wọ́n fi ń rajà tàbí èyí tí wọ́n fi ń gba owó ní báǹkì, èèyàn sì lè lo àwọn ọ̀nà míì láti ṣètìlẹyìn ní abala “Ṣe Ọrẹ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà” lórí ìkànnì wa. b Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan máa ń ṣètò pé kí wọ́n máa yọ iye kan pàtó nínú owó wọn lóṣooṣù látorí ọ̀kan lára àwọn apá tó wà lórí ìkànnì wa.—1 Kọ́ríńtì 16:2.
Ọrẹ téèyàn ṣètò sílẹ̀: Àwọn ọrẹ kan gba pé kéèyàn ṣètò ẹ̀ sílẹ̀ tàbí kéèyàn fi tó agbẹjọ́rò létí. Ó ṣeé ṣe kírú ètò bẹ́ẹ̀ dín owó orí tẹ́nì kan máa san kù tàbí kẹ́ni náà má tiẹ̀ san án rárá. Ọ̀pọ̀ ló ti rí i pé ó máa ṣe àwọn láǹfààní táwọn bá ṣètò láti máa fi ohun ìní àwọn ṣètìlẹyìn nígbà táwọn ṣì wà láàyè tàbí kó di tẹlòmíì táwọn bá kú. O lè kàn sí ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà nítòsí rẹ tó o bá fẹ́ mọ bó o ṣe lè fowó ránṣẹ́ nípasẹ̀:
àkáǹtì owó ní báǹkì
owó ìbánigbófò àti owó ìfẹ̀yìntì
ilẹ̀ àti ilé
ìpín ìdókòwò, ẹ̀tọ́ orí owó ìdókòwò àti ti ètò ẹ̀yáwó
ìwé ìhágún àti ohun ìní téèyàn fi síkàáwọ́ onígbọ̀wọ́
Tó o bá fẹ́ mọ púpọ̀ sí i nípa ọ̀nà míì tó o lè gbà fi owó ṣètìlẹyìn ládùúgbò rẹ, lọ sí abala “Ṣe Ọrẹ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà.”
a Ẹni tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà náà lè fi owó ránṣẹ́ láti ti iṣẹ́ wa lẹ́yìn.
b Tó o bá fẹ́ mọ púpọ̀ sí i, wo fídíò Àlàyé Lórí Bá A Ṣe Lè Fi Ọrẹ Ṣètìlẹ́yìn Látorí Íńtánẹ́ẹ̀tì.