Ki Nidi Ti Awon Elerii Jehofa Ki I Fi I Lowo si Iselu?
Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í lọ́wọ́ sí ọ̀rọ̀ ìṣèlú torí pé ìgbàgbọ́ wa tó bá Bíbélì mu kò fàyè gbà wa láti ṣe bẹ́ẹ̀. A kì í ṣe ẹgbẹ́ tó ń wá ojúure ìjọba, a kì í dìbò fún àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú tàbí ẹni tí ẹgbẹ́ òṣèlú fà kalẹ̀, a kì í du ipò lọ́dọ̀ ìjọba tàbí ká lọ́wọ́ sí ohunkóhun tó bá jẹ mọ́ bí ìjọba ṣe máa di ti àwọn ẹlòmíì. Bíbélì fún wa ní àwọn ìdí tó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ tí kò fi yẹ ká lọ́wọ́ sí ọ̀rọ̀ ìṣèlú, a sì gbà á gbọ́.
Àpẹẹrẹ Jésù là ń tẹ̀ lé torí kò tẹ́wọ́ gba ipò ìṣèlú kankan. (Jòhánù 6:15) Ó kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n má ṣe jẹ́ “apá kan ayé,” ó sì jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé kò yẹ kí wọ́n gbè sẹ́yìn apá kankan tó bá dọ̀rọ̀ ìṣèlú.—Jòhánù 17:14, 16; 18:36; Máàkù 12:13-17.
Ìjọba Ọlọ́run la fara mọ́, òun ni Jésù sọ nípa rẹ̀ nígbà tó sọ pé: “A ó sì wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé.” (Mátíù 24:14) Aṣojú Ìjọba Ọlọ́run ni wá, Ọlọ́run yàn wá pé ká máa polongo dídé Ìjọba náà, torí ìdí èyí, a kì í lọ́wọ́ sí ọ̀rọ̀ ìṣèlú tó ń lọ ní gbogbo orílẹ̀-èdè tó fi mọ́ ìṣèlú ibi tí à ń gbé.—2 Kọ́ríńtì 5:20; Éfésù 6:20.
Torí pé a kì í dá sí ọ̀rọ̀ ìṣèlú, a lómìnira láti bá àwọn èèyàn tó fara mọ́ ìṣèlú sọ̀rọ̀ nípa ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. À ń fi ọ̀rọ̀ ẹnu wa àti ìṣe wa jẹ́ kí àwọn èèyàn mọ̀ pé Ìjọba Ọlọ́run la gbẹ́kẹ̀ lé pé yóò bá wa yanjú ìṣòro gbogbo ayé.—Sáàmù 56:11.
A wà ní ìṣọ̀kan kárí ayé gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ ará torí pé a kì í lọ́wọ́ sí ìṣèlú tó ń mú kí àwọn èèyàn yapa sí ara wọn. (Kólósè 3:14; 1 Pétérù 2:17) A yàtọ̀ sí àwọn ẹlẹ́sìn táwọn ọmọ ìjọ wọn tí kò sí níṣọ̀kan torí pé wọ́n ń lọ́wọ́ sí ìṣèlú.—1 Kọ́ríńtì 1:10.
A bọ̀wọ̀ fún ìjọba. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a kì í lọ́wọ́ sí ìṣèlú, à ń bọ̀wọ̀ fún àṣẹ ìjọba tó ń darí orílẹ̀-èdè tí à ń gbé. Èyí bá àṣẹ tí Bíbélì pa fún wa mu, Bíbélì sọ pé: “Kí olúkúlùkù ọkàn wà lábẹ́ àwọn aláṣẹ onípò gíga.” (Róòmù 13:1) A máa ń tẹ̀ lé òfin, a máa ń sanwó orí, a sì máa ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ìjọba kí ipá tí wọ́n ń sà láti mú kí àwọn aráàlú gbé ìgbé ayé ìdẹ̀rùn lè yọ. Dípò tí a ó fi máa ṣe àwọn nǹkan tó máa dojú ìjọba dé, ńṣe là ń tẹ̀ lé ọ̀rọ̀ ìyànjú inú Bíbélì tó sọ pé ká máa gbàdúrà fún “àwọn ọba àti gbogbo àwọn tí ó wà ní ipò gíga,” ní pàtàkì tí ìjọba bá ń ṣe àwọn ìpinnu tó máa nípa lórí òmìnira ìjọsìn.—1 Tímótì 2:1, 2.
A tún máa ń bọ̀wọ̀ fún ẹ̀tọ́ táwọn ẹlòmíì ní láti ṣèpinnu tó bá dọ̀rọ̀ ìṣèlú. Bí àpẹẹrẹ, a kì í da ètò ìdìbò rú tàbí ká dí àwọn tó fẹ́ dìbò lọ́wọ́.
Ṣé nǹkan tuntun ni bí a kì í ṣe dá sí ọ̀rọ̀ ìṣèlú? Rárá. Àwọn àpọ́sítélì àtàwọn Kristẹni ní ọgọ́rùn ún ọdún kìíní náà bọ̀wọ̀ fún ìjọba, wọn ò sì lọ́wọ́ sí ìṣèlú. Ìwé náà, Beyond Good Intentions sọ pé: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn tó kọ́kọ́ di Kristẹni gbà pé àwọn ní láti bọ̀wọ̀ fún àwọn ìjọba tó ń ṣàkóso, síbẹ̀ wọ́n gbà pé kò yẹ káwọn máa lọ́wọ́ sí àwọn ọ̀ràn ìṣèlú.” Bákan náà, ìwé On the Road to Civilization sọ nípa àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ pé wọn “kì í gba ipò èyíkéyìí tó bá ti jẹ́ ti olóṣèlú.”
Ǹjẹ́ ọ̀tá àlàáfíà ni àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà bí a kì í ṣe lọ́wọ́ sí ìṣèlú? Rárá. A kì í ṣe ọ̀tá àlàáfíà, ará ìlú tó nífẹ̀ẹ́ àlàáfíà ni wá, torí náà kò sí ìdí tí àwọn ìjọba fi ní láti máà bẹ̀rù wa. Bí àpẹẹrẹ, a rí ìròyìn kan lọ́dún 2001 látọ̀dọ̀ ẹgbẹ́ National Academy of Sciences of Ukraine. Ìròyìn náà dá lórí bí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í ṣe lọ́wọ́ sí òṣèlú, ó ní: “Àwọn èèyàn lóde òní lè má nífẹ̀ẹ́ sí bí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í ṣe lọ́wọ́ sí ìṣèlú, ìyẹn gan-an sì ni ìdí tí ìjọba Násì apàṣẹwàá àti Kọ́múníìsì ìgbà yẹn fi fẹ̀sùn kàn wọ́n.” Síbẹ̀ náà, “ará ìlú tó ń pa òfin mọ́” ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà tí ìjọba ilẹ̀ Soviet Union ń ni wọ́n lára. Wọ́n fi òótọ́ inú àti àìmọtara ẹni nìkan ṣiṣẹ́ nínú àwọn oko àtàwọn ilé iṣẹ́ ńlá, wọn kì í sì í ṣe ọ̀tá ìjọba Kọ́múníìsì.” Ní ìparí, ìròyìn náà sọ pé, bákan náà ló rí lóde òní, ìgbàgbọ́ àti ohun tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe kò “jin àlàáfíà àti ìṣọ̀kan orílẹ̀-èdè èyíkéyìí lẹ́sẹ̀.”