Kí Nìdí Táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Kì Í Fèsì Gbogbo Ẹ̀sùn Táwọn Èèyàn Fi Ń Kàn Wọ́n?
Ìmọ̀ràn Bíbélì làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń tẹ̀ lé, pé kì í ṣe gbogbo àwọn tó bá fẹ̀sùn kàn wá tàbí tó ń fi wá ṣẹlẹ́yà ni ká máa fún lésì. Bí àpẹẹrẹ, òwe inú Bíbélì kan sọ pé: “Ẹni tí ó bá ń tọ́ olùyọṣùtì sọ́nà ń gba àbùkù fún ara rẹ̀.” (Òwe 9:7, 8; 26:4) Dípò ká máa bá ẹnì kan tó fẹ̀sùn irọ́ kàn wá fa ọ̀rọ̀ torí pé a ò fẹ́ kó bà wá lórúkọ jẹ́, bá a ṣe máa ṣèfẹ́ Ọlọ́run la máa ń gbájú mọ́.—Sáàmù 119:69.
Ká sòótọ́, “ìgbà dídákẹ́ jẹ́ẹ́ àti ìgbà sísọ̀rọ̀” wà. (Oníwàásù 3:7) A máa ń bá àwọn tó wù látọkàn wá kí wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ sọ̀rọ̀, àmọ́ a kì í bá àwọn èèyàn jiyàn lórí ọ̀rọ̀ tí kò lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀. Ohun tí Jésù àtàwọn Kristẹni ìṣáájú fi kọ́ni, táwọn náà sì ṣe nìyẹn, àpẹẹrẹ wọn làwa náà ń tẹ̀ lé.
Jésù ò fèsì nígbà tí wọ́n fẹ̀sùn irọ́ kàn án níwájú Pílátù. (Mátíù 27:11-14; 1 Pétérù 2:21-23) Bákan náà, nígbà táwọn èèyàn pè é ní ọ̀mùtí àti alájẹkì, Jésù ò fún wọn lésì. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìwà rẹ̀ ló jẹ́ kó sọ̀rọ̀, bí ohun tí Bíbélì sọ pé: “A fi ọgbọ́n hàn ní olódodo nípasẹ̀ àwọn iṣẹ́ rẹ̀.” (Mátíù 11:19) Àmọ́ nígbà míì, tó bá gbà bẹ́ẹ̀, Jésù máa ń fìgboyà dá àwọn tó ń bà á lórúkọ jẹ́ lóhùn.—Mátíù 15:1-3; Máàkù 3:22-30.
Jésù kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ pé kí wọ́n má banú jẹ́ táwọn èèyàn bá fẹ̀sùn èké kàn wọ́n. Ó sọ pé: “Aláyọ̀ ni yín nígbà tí àwọn ènìyàn bá gàn yín, tí wọ́n sì ṣe inúnibíni sí yín, tí wọ́n sì fi irọ́ pípa sọ gbogbo onírúurú ohun burúkú sí yín nítorí mi.” (Mátíù 5:11, 12) Àmọ́ Jésù tún sọ pé tí àyè bá yọ fún wọn láti wàásù nígbà táwọn èèyàn bá ń fẹ̀sùn kàn wọ́n, òun máa ṣe ohun tóun ṣèlérí fún wọn, pé: “Èmi yóò fún yín ni ẹnu àti ọgbọ́n, tí gbogbo àwọn alátakò yín lápapọ̀ kì yóò lè dúró tiiri lòdì sí tàbí bá ṣe awuyewuye.”—Lúùkù 21:12-15.
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gba àwọn Kristẹni nímọ̀ràn pé kí wọ́n má ṣe bá àwọn tó ń ta kò wọ́n fa ọ̀rọ̀ tí kò lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀. Pọ́ọ̀lù pe irú àwọn àríyànjiyàn bẹ́ẹ̀ ní “aláìlérè àti ìmúlẹ̀mófo.”—Títù 3:9; Róòmù 16:17, 18.
Àpọ́sítélì Pétérù rọ àwọn Kristẹni pé kí wọ́n gbèjà ìgbàgbọ́ wọn tí àyè ẹ̀ bá yọ. (1 Pétérù 3:15) Àmọ́ ó gbà pé ìwà èèyàn ló dùn wàásù ju ọ̀rọ̀ ẹnu lọ. Ó sọ pé: “Nípa ṣíṣe rere kí ẹ lè dí ọ̀rọ̀ àìmọ̀kan mọ́ àwọn aláìlọ́gbọ́n-nínú lẹ́nu.”—1 Pétérù 2:12-15.