ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ
Ṣé Mo Lè Yan Orin Tó Bá Ṣáà Ti Wù Mí?
“Tí n bá ti fẹ́ bẹ̀rẹ̀ ìgbòkègbodò mi láàárọ̀, mo máa ń gbọ́ orin. Tí n bá wọnú ọ̀kọ̀, mo máa ń gbọ́ orin. Kódà tí n bá wà nílé tí mò ń sinmi, tí mò ń tún ilé ṣe tàbí kàwé, orin ni mo máa ń gbọ́. Gbogbo ìgbà ni mo máa ń gbọ́ orin.”—Carla.
Ṣé bí Carla ṣe fẹ́ràn orin gan-an ni ìwọ náà ṣe fẹ́ràn ẹ̀? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, àpilẹ̀kọ yìí máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti mọ àwọn àǹfààní tó wà nínú gbígbọ́ orin, bó o ṣe lè yẹra fún ewu tó wà níbẹ̀ àti bó o ṣe lè fọgbọ́n yan irú orin tí wàá máa gbọ́.
Àwọn àǹfààní tó wà níbẹ̀
Kéèyàn máa gbọ́ orin dà bí ìgbà tí èèyàn ń jẹun. Bóyá èèyàn ń gbọ́ orin tàbí ó ń jẹun, ohun tó dáa jù ni pé kéèyàn ṣe èyí tó dáa, kó sì jẹ́ ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì. Àwọn àǹfààní tó wà nínú orin rèé:
Orin lè múnú ẹ dùn.
“Lọ́jọ́ tí inú mi ò bá dùn, tí mo bá ti gbọ́ orin tí mo fẹ́ràn, ńṣe ni ara mi á yá gágá lójú ẹsẹ̀.”—Mark.
Orin lè jẹ́ kó o rántí àwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn.
“Lọ́pọ̀ ìgbà, tí n bá ti gbọ́ àwọn orin kan, ó máa ń jẹ́ kí n rántí àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà kan, inú mi sì máa ń dùn pé mo gbọ́ irú orin bẹ́ẹ̀.”—Sheila.
Orin máa ń jẹ́ kí ìṣọ̀kan àwa àtàwọn ẹlòmíì lágbára.
“Bí mo ṣe ń gbọ́ táwọn àlejò tó wá sí àpéjọ àgbáyé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń kọrin ìparí ní àpéjọ náà, ńṣe ni orí mi wú tí omijé sì ń bọ́ lójú mi. Èdè wa yàtọ̀ síra lóòótọ́, àmọ́ orin tá a jọ kọ yẹn mú ká wà níṣọ̀kan.”—Tammy.
Orin lè jẹ́ kó o ní àwọn ànímọ́ tó ṣeyebíye.
“Tó o bá ń kọ́ bí wọ́n ṣe ń lo ohun èlò orin kan, o lè wá di ẹni tó ń fara balẹ̀ ṣe nǹkan, tó sì ní sùúrù. Torí pé díẹ̀díẹ̀ ni wàá mọ ohun èlò orin yẹn lò. Bó o bá ṣe ń fi ohun èlò orin náà dánra wò ni wàá máa mọ̀ ọ́n lò.”—Anna.
Ǹjẹ́ o mọ̀? Ìwé Sáàmù ló gùn jù lọ nínú àwọn ìwé tó wà nínú Bíbélì, àádọ́jọ orin [150] ló sì wà nínú ẹ̀.
Àwọn ewu tó wà níbẹ̀
Àwọn orin kan dà bí oúnjẹ tí wọ́n da májèlé sí, ó lè pa èèyàn. Jẹ́ ká wo ìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀.
Àwọn orin kan ní ọ̀rọ̀ ìṣekúṣe nínú.
“Ó jọ pé gbogbo àwọn orin tó gbajúmọ̀ ló dá lórí ìṣekúṣe. Àwọn èèyàn ò tiẹ̀ fi bò mọ́.”—Hannah.
Bíbélì sọ pé: “Kí a má tilẹ̀ mẹ́nu kan àgbèrè àti ìwà àìmọ́ onírúurú gbogbo tàbí ìwà ìwọra láàárín yín.” (Éfésù 5:3) Bi ara rẹ pé, ‘Ṣé irú orin tí mò ń gbọ́ fi hàn pé mò ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn yìí?’
Àwọn orin kan lè kó ìbànújẹ́ bá ẹ.
“Nígbà míì tí oorun bá dá lójú mi lóru, mo máa ń tẹ́tí sí àwọn orin tó máa ń jẹ́ kí n ronú nípa àwọn nǹkan tó lè bà mí lọ́kàn jẹ́. Orin burúkú máa ń gbé èròkerò sọ́kàn mi.”—Tammy.
Bíbélì sọ pé: “Ju gbogbo ohun mìíràn tí a ní láti ṣọ́, fi ìṣọ́ ṣọ́ ọkàn-àyà rẹ.” (Òwe 4:23) Bi ara rẹ pé, ‘Ṣé irú orin tí mò ń gbọ́ máa ń gbé èròkerò sí mi lọ́kàn?’
Àwọn orin kan lè sọ ẹ́ di oníbìínú èèyàn.
“Ewu tí mi ò tètè fura sí ni àwọn orin tó jẹ́ kí inú máa bí mi àti èyí tó jẹ́ kí n máa kórìíra ara mi. Mo rí i pé inú mi kì í dùn tí n bá ti gbọ́ irú àwọn orin bẹ́ẹ̀ tán. Àwọn ara ilé mi pàápàá kíyè sí i bẹ́ẹ̀.”—John.
Bíbélì sọ pé: “Ẹ mú gbogbo wọn kúrò lọ́dọ̀ yín, ìrunú, ìbínú, ìwà búburú, ọ̀rọ̀ èébú, àti ọ̀rọ̀ rírùn kúrò lẹ́nu yín.” (Kólósè 3:8) Bi ara rẹ pé, ‘Ṣé orin tí mò ń gbọ́ ti jẹ́ kí n di onínú fùfù tàbí ẹni tó burú gan-an sí àwọn èèyàn?’
Kí ló yẹ kó o fi sọ́kàn? Máa fọgbọ́n yan irú orín tí wàá máa gbọ́. Ohun tí ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Julie ṣe nìyẹn, ó sọ pé: “Gbogbo ìgbà ni mo máa ń ṣàyẹ̀wò àwọn orin tí mò ń gbọ́, tí n bá ti rí èyí tí ò dáa nínú wọn, ńṣe ni màá yọ ọ́ dànù. Lóòótọ́ kò rọrùn, àmọ́ mo mọ̀ pé ohun tó yẹ kí n ṣe nìyẹn.”
Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Tara náà ti ń ṣe bíi ti Julie. Ó sọ pé: “Nígbà míì, wọ́n máa gbé orin tó ní àwọn àlùjó tó dùn gan-an sáfẹ́fẹ́ lórí rédíò, àmọ́ tí n bá ti gbọ́ ọ̀rọ̀ orin náà tí mo sì rí i pé kò dáa, ńṣe ni màá tètè yí ìkànnì rédíò náà síbòmíì. Ohun tí mò ń ṣe yìí dà bí ìgbà tí mo tọ́ oyin wò tán tí mo wá dà á nù! Tí mo bá lè pinnu pé mi ò ní gbọ́ orin tó dá lórí ìṣekúṣe, kò ní ṣòro fún mi láti sá fún ṣíṣe ìṣekúṣe ṣáájú ìgbéyàwó. Mí ò fẹ́ máa ronú pé irú orin tí mò ń gbọ́ ò lè ní ipa búburú lórí mi.”