ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ
Kí Ni Mo Lè Ṣe Tí Àjálù Bá Dé Bá Mi?
Kò sẹ́ni tí àjálù ò lè dé bá. Bíbélì sọ pé, “Eré ìje kì í ṣe ti ẹni yíyára, bẹ́ẹ̀ ni ìjà ogun kì í ṣe ti àwọn alágbára ńlá . . . ìgbà àti ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò rí tẹ́lẹ̀ ni ó ń ṣẹlẹ̀ sí gbogbo wọn.” (Oníwàásù 9:11) Àjálù ti dé bá àwọn ọ̀dọ́ kan náà rí. Kí ni wọ́n ṣe kí wọ́n lè fara da ohun tó ṣẹlẹ̀ sí wọn? Wo àpẹẹrẹ ẹni méjì.
REBEKAH
Àwọn òbí mi kọ ara wọn sílẹ̀ nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún mẹ́rìnlá (14).
Ṣe ló ń ṣe mí bí àlá nígbà tí àwọn òbí mi kọ ara wọn sílẹ̀. Mo wá ń sọ lọ́kàn ara mi pé bàbá mi ò lọ ibì kankan, wọ́n kàn fẹ́ dá wà fúngbà díẹ̀ ni. Wọ́n ṣáà nífẹ̀ẹ́ Mọ́mì, báwo ni wọ́n á ṣe wá fi Mọ́mì sílẹ̀? Ṣé wọ́n á wá fi èmi náà sílẹ̀ ni?
Mi ò kì ń fẹ́ sọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ fún ẹnì kankan. Mi ò tiẹ̀ fẹ́ máa rò ó. Inú máa ń bí mi nígbà yẹn, bó tiẹ̀ jẹ́ pé mi ò kì ń mọ̀ pé mò ń bínú. Ọkàn mi ò wá balẹ̀ mọ́, mi ò sì rí oorun sùn dáadáa.
Ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún (19) ni mí nígbà tí àrùn jẹjẹrẹ pa ìyá mi. Kò sí ọ̀rẹ́ tó dà bí ìyá mi.
Inú mi ò dùn rárá nígbà táwọn òbí mi kọ ara wọn sílẹ̀. Ikú mọ́mì mi ló tiẹ̀ wá le jù, ó bà mí lọ́kàn jẹ́ gan-an. Ìbànújẹ́ ọ̀hún ò tíì tán lọ́kàn mi títí di báyìí. Àtirí oorun sùn ti wá di ìṣòro ńlá fún mi, ọkàn mi ò sì balẹ̀.
Lẹ́sẹ̀ kan náà, ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan ló ti ràn mí lọ́wọ́. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì kìlọ̀ fún wa nínú Òwe 18:1 pé ká má ṣe máa ya ara wa sọ́tọ̀, mo sì ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn yẹn.
Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni mí, torí náà, mo tún máa ń ka àwọn ìwé wa tó dá lórí Bíbélì, wọ́n sì máa ń tù mí nínú. Ọ̀kan lára àwọn ìwé náà ni Awọn Ìbéèrè Tí Awọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Awọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, ó ràn mí lọ́wọ́ nígbà táwọn òbí mi kọra wọn sílẹ̀. Mo rántí pé mo ka ibì kan nínú Apá Kejì ìwé náà tí àkòrí ẹ̀ sọ pé “Báwo Ni Mo Ṣe Lè Láyọ̀ Bí Òbí Mi Bá Jẹ́ Anìkàntọ́mọ?”
Ọ̀kan lára ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí mo fẹ́ràn jù tó máa ń jẹ́ kí ọkàn mi balẹ̀ ni Mátíù 6:25-34. Ní ẹsẹ kẹtàdínlọ́gbọ̀n (27), Jésù béèrè pé: “Ta ni nínú yín, nípa ṣíṣàníyàn, tí ó lè fi ìgbọ̀nwọ́ a kan kún ìwọ̀n gígùn ìwàláàyè rẹ̀?”
Gbogbo wa ni nǹkan burúkú lè ṣẹlẹ̀ sí, àmọ́ mo kẹ́kọ̀ọ́ lára mọ́mì mi pé ọwọ́ tá a bá fi mú àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ yẹn ṣe pàtàkì. Ojú wọn rí o, ọkọ kọ̀ wọ́n sílẹ̀, àìsàn tí kò gbóògùn tún ṣe wọ́n, àmọ́ wọn ò sọ̀rètí nù jálẹ̀ gbogbo ìgbà tí wọ́n fi wà nínú ìṣòrò, títí wọ́n sì fi kú, ìgbàgbọ́ tí wọ́n ní nínú Ọlọ́run ò yẹ̀. Mi ò lè gbàgbé gbogbo ohun tí wọ́n kọ́ mi nípa Jèhófà.
Ronú nípa èyí: Tó o bá ń ka Bíbélì àti àwọn ìwé tó dá lórí Bíbélì, báwo ló ṣe lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè fara da nǹkan burúkú tó bá ṣẹlẹ̀ sí ẹ?—Sáàmù 94:19.
CORDELL
Ojú mi báyìí ni bàbá mi gbẹ́mìí mì nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún mẹ́tàdínlógún (17). Ohun tó burú jù lọ tó tíì ṣẹlẹ̀ sí mi láyé yìí nìyẹn. Inú mi bà jẹ́ gan-an, ó wá dà bíi pé ó ti tán fún mi.
Nígbà tí wọ́n ń fi aṣọ bo dádì mi lójú, mò ń rò ó lọ́kàn pé wọn ò tíì kú, mò ń sọ pé kì í ṣe àwọn ni wọ́n ń faṣọ bò yẹn. Mò ń sọ lọ́kàn ara mi pé, ‘Wọ́n ń sùn ni, wọ́n á jí lọ́la.’ Inú mi ò dùn rárá, ayé sì sú mi.
Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni èmi àti ìdílé mi, àwọn ará wa sì dúró tì wá gan-an nígbà tí bàbá mi kú. Wọ́n fún wa lóúnjẹ, wọ́n wá dúró tì wá nílé, wọn ò sì fí wá sílẹ̀ nígbà kankan. Ohun tí wọ́n ṣe fún wa jẹ́ kí n mọ̀ pé Kristẹni tòótọ́ ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.—Jòhánù 13:35.
Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan tó tù mí nínú gidigidi ni 2 Kọ́ríńtì 4:17, 18. Ó sọ pé: “Nítorí bí ìpọ́njú náà tilẹ̀ jẹ́ fún ìgbà díẹ̀, tí ó sì fúyẹ́, fún àwa, ó ń ṣiṣẹ́ yọrí sí ògo tí ó jẹ́ ti ìwọ̀n títayọ síwájú àti síwájú sí i, tí ó sì jẹ́ àìnípẹ̀kun; nígbà tí àwa kò tẹ ojú wa mọ́ àwọn ohun tí a ń rí, bí kò ṣe àwọn ohun tí a kò rí. Nítorí àwọn ohun tí a ń rí jẹ́ fún ìgbà díẹ̀, ṣùgbọ́n àwọn ohun tí a kò rí jẹ́ fún àìnípẹ̀kun.”
Ẹsẹ tó kẹ́yìn yẹn nítumọ̀ sí mi gan-an. Ohun tó ṣe dádì mi kàn ṣẹlẹ̀ fúngbà díẹ̀ ni, àmọ́ ohun rere tí Ọlọ́run máa ṣe lọ́jọ́ iwájú máa wà títí láé, kò sì ní nípẹ̀kun. Ikú dádì mi ti jẹ́ kí n lè ronú nípa bí mo ṣe ń lo ìgbésí ayé mi, kí n sì mọ ohun tó yẹ kí n fayé mi ṣe.
Ronú nípa èyí: Tí àjálù kan bá dé bá ẹ, báwo ló ṣe lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè ronú jinlẹ̀, kó o sì mọ àwọn ohun tó yẹ kí o fi ayé ẹ ṣe?—1 Jòhánù 2:17.
a Ìgbọ̀nwọ́ kan jẹ́ nǹkan bíi sẹ̀ǹtímítà 45 tàbí nǹkan bíi ẹsẹ̀ bàtà kan àti ààbọ̀.