ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÌDÍLÉ
Bó o Ṣe Lè Kápá Ìbínú Rẹ
Ká sọ pé ọkọ tàbí ìyàwó rẹ sọ̀rọ̀ kan tàbí ṣe ohun kan tó múnú bí ẹ, o wá gbìyànjú láti pa ìbínú yẹn mọ́ra, nígbà tí ẹnì kejì rẹ kíyè sí pé inú ń bí ẹ, ó tún wá ń bi ẹ ní ìbéèrè, ìyẹn wá múnú bí ẹ sí i. Báwo lo ṣe lè kápá ìbínú rẹ̀ tí irú nǹkan báyìí bá ṣẹlẹ̀?
Ohun tó yẹ kó o mọ̀
Ìbínú lè ṣàkóbá fún ìlera rẹ. Ìwádìí ti fi hàn pé ó máa rọrùn fún ẹni tí kì í kápá ìbínú rẹ láti ní àrùn ọkàn, ìsoríkọ́, ẹ̀jẹ̀ ríru àti àwọn àìsàn tí kì í jẹ́ kí oúnjẹ dà bó ṣe yẹ. Ìbínú tún máa ń fa àìsàn tí kì í jẹ́ kí èèyàn rí oorun sùn, ó máa ń fa àníyàn, ó lè fa àìsàn sí àwọ̀ ara tàbí àrùn rọpárọsẹ̀. Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi sọ pé: “Jáwọ́ nínú ìbínú” torí ìpalára ló máa ń yọrí sí.—Sáàmù 37:8.
Kò dáa kí èèyàn máa di ìbínú sínú. Tó o bá ń fi ìbínú rẹ pamọ́, ṣe ló máa dà bí ìgbà tí àrùn kan ń ba ẹ jà láti inú wá. Bí àpẹẹrẹ, ó lè jẹ́ kó o máa ṣe àríwísí àwọn míì. Irú ìwà bẹ́ẹ̀ máa jẹ́ kó ṣòro fún àwọn èèyàn láti bá ẹ gbé torí pé, àjọgbé yín kò ní wọ̀, ó sì lè ba ìgbéyàwó rẹ jẹ́.
Ohun tó o lè ṣe
Àwọn ìwà dáadáa rẹ̀ ni kó o máa wò. Kọ àwọn nǹkan mẹ́ta tó o fẹ́ràn nípa ẹnì kejì rẹ sílẹ̀. Nígbà míì tó bá ṣe nǹkan tó múnú bí ẹ, ronú nípa àwọn ìwà dáadáa tó o kọ sílẹ̀ lọ́jọ́sí. Èyí máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti kápá ìbínú rẹ.
Ìlànà Bíbélì: ‘Ẹ fi ara yín hàn ní ẹni tí ó kún fún ọpẹ́.’—Kólósè 3:15.
Kọ́ bó o ṣe lè máa dárí jini. Lákọ̀ọ́kọ́ ná, fi ojú tí ẹnì kejì rẹ fi ń wo nǹkan wò ó. Èyí máa jẹ́ kó o mọ bí nǹkan ṣe rí lára rẹ̀, ìyẹn ni Bíbélì pè ní “ìmọ̀lára fún ọmọnìkejì.” (1 Pétérù 3:8) Lẹ́yìn náà, bi ara rẹ pé, ‘Ṣé ohun tó ṣe burú tó bẹ́ẹ̀ ti mi ò fi lè dárí jì í?’
Ìlànà Bíbélì: “Ẹwà ni ó jẹ́ ... láti gbójú fo ìrélànàkọjá.”—Òwe 19:11.
Fi sùúrù àti ọgbọ́n sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ. Máa lo ọ̀rọ̀ náà “Mo” tó o bá ń sọ̀rọ̀. Bí àpẹẹrẹ, dípò tí wà á fi sọ pé, “O ò kì í ń ro ti ẹlòmíì mọ́ tìẹ rárá, oò pè mí kí n lè mọ ibi tó o wà,” o lè sọ pé, “Ọkàn mi kì í balẹ̀ tí mi ò bá mọ ibi tó o wà, pàápàá tí ilẹ̀ bá ti ṣú, mi ò mọ̀ bóyá àlááfíà lo wà.” Tó o bá ń fi sùúrù sọ̀rọ̀, ìyẹn máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti kápá ìbínú rẹ.
Ìlànà Bíbélì: “Ẹ jẹ́ kí àsọjáde yín máa fìgbà gbogbo jẹ́ pẹ̀lú oore ọ̀fẹ́, tí a fi iyọ̀ dùn.”—Kólósè 4:6.
Fara balẹ̀ tẹ́tí sílẹ̀. Lẹ́yìn tó o bá ti sọ bí ọ̀rọ̀ ṣe rí lára rẹ, fara balẹ̀ tẹ́tí sí ohun tí ẹnì kejì rẹ fẹ́ sọ, kó o má sì dá ọ̀rọ̀ mọ́ ọn lẹ́nu. Tó bá ti sọ̀rọ̀ tán, tún àwọn kókó tó wà nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ sọ, kó o bàa lè rí i dájú pé ọ̀rọ̀ tó sọ yé ẹ dáadáa. Tó o bá ń ṣe báyìí, ó máa rọrùn fún ẹ láti kápá ìbínú rẹ.
Ìlànà Bíbélì: “Yára nípa ọ̀rọ̀ gbígbọ́, lọ́ra nípa ọ̀rọ̀ sísọ.”—Jákọ́bù 1:19.