Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÌDÍLÉ | ỌMỌ TÍTỌ́

Bó O Ṣe Lè Bá Ọmọ Rẹ Sọ̀rọ̀ Nípa Kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà

Bó O Ṣe Lè Bá Ọmọ Rẹ Sọ̀rọ̀ Nípa Kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà

 Ó ṣeé ṣe kó o ti kíyè sí i pé àtikékeré ni ọmọ rẹ ti ń rí i báwọn kan ṣe ń ṣe sáwọn míì torí àwọ̀ wọn tàbí ibi tí wọ́n ti wá. Báwo lo ṣe lè ran ọmọ rẹ lọ́wọ́ tí kò fi ní máa hùwà kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà bíi tàwọn míì? Kí lo lè ṣe tí wọ́n bá ń hùwà tí ò dáa sí ọmọ rẹ torí ẹ̀yà tàbí tó ti wá?

Nínú àpilẹ̀kọ yìí

 Bó o ṣe lè bá ọmọ rẹ sọ̀rọ̀ nípa onírúurú ẹ̀yà tó wà

 Ohun tó ò lè sọ. Onírúurú àwọ̀ àti àṣà ìbílẹ̀ tó ṣàrà ọ̀tọ̀ ló wà kárí ayé. Èyí ti wá jẹ́ káwọn kan máa hùwà tí ò dáa sáwọn míì torí bí àwọ̀ àti ìṣe wọn ṣe yàtọ̀ sí tiwọn.

 Àmọ́, Bíbélì fi kọ́ni pé ọ̀dọ̀ ẹnì kan ni gbogbo wa ti wá. Lédè míì, a lè sọ pé ọmọ bàbá kan náà ni gbogbo wa.

“Láti ara ọkùnrin kan [ni Ọlọ́run] ti dá gbogbo orílẹ̀-èdè àwọn èèyàn.”​—Ìṣe 17:26.

 “A ti kíyè sí i pé táwọn ọmọ wa bá ń bá àwọn ọmọ míì tí ẹ̀yà wọn yàtọ̀ sí tiwa ṣeré, wọ́n á rí i pé gbogbo èèyàn ló yẹ ká bọ̀wọ̀ fún ká sì fìfẹ́ hàn sí.”​—Karen.

 Báwo lo ṣe lè ṣàlàyé ohun tí kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà jẹ́ fún ọmọ rẹ

 Bópẹ́ bóyá, ọmọ rẹ lè gbọ́ ìròyìn nípa ìwà ìkà táwọn kan ń hù sáwọn míì nítorí ọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà. Báwo lo ṣe lè ṣàlàyé ohun tó ń ṣẹlẹ̀ fún un? Ọjọ́ orí rẹ̀ ló máa pinnu ohun tí wàá sọ fún un.

  •   Ọmọ ilé ẹ̀kọ́ jẹ́lé-ó-sinmi. Dókítà Allison Briscoe-Smith tá a fa ọ̀rọ̀ ẹ̀ yọ nínú ìwé ìròyìn Parents sọ pé: “Àwọn ọmọ kékeré tètè máa ń mọ ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́, o lè lo àǹfààní yẹn láti bá a sọ̀rọ̀ nípa ìwà ti ò dáa táwọn èèyàn ń hù.”

“Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú, àmọ́ ní gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tó bá bẹ̀rù rẹ̀, tó sì ń ṣe ohun tí ó tọ́ ni ẹni ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ rẹ̀.”​—Ìṣe 10:​34, 35.

  •   Ọmọ tí ò tíì pé ọmọ ọdún mẹ́tàlá. Àwọn ọmọ tí ọjọ́ orí wọn wà láàárín ọdún mẹ́fà sí méjìlá máa ń fẹ́ mọ ọ̀pọ̀ nǹkan, torí náà wọ́n máa ń béèrè àwọn ìbéèrè tó ṣòro láti dáhùn nígbà míì. Rí i dájú pé o ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe kó o lè dáhùn àwọn ìbéèrè náà lọ́nà tó máa yé wọn. Tó o bá ń bá ọmọ rẹ sọ̀rọ̀ nípa ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nílé ìwé wọn tàbí ohun tí wọ́n rí lórí tẹlifíṣọ̀n, lo àǹfààní yẹn láti ṣàlàyé fún wọn bí ìwà kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà ṣe burú tó.

“Kí èrò . . . yín ṣọ̀kan, kí ẹ máa bára yín kẹ́dùn, kí ẹ máa ní ìfẹ́ ará, kí ẹ lójú àánú, kí ẹ sì jẹ́ onírẹ̀lẹ̀.”​—1 Pétérù 3:8.

  •   Àwọn Ọ̀dọ́. Ó máa ń rọrùn fáwọn ọ̀dọ́ láti lóye ìdí táwọn nǹkan kan fi ń ṣẹlẹ̀ ju igbà tí wọ́n ṣì kéré lọ. Torí náà, àsìkò yìí ló dáa jù láti bá ọmọ rẹ sọ̀rọ̀ nípa bí wọ́n ṣe ń hùwà ìkà sáwọn èèyàn tórí ẹ̀yà wọn.

“Àwọn tó dàgbà . . . ti kọ́ agbára ìfòyemọ̀ wọn nípa bí wọ́n ṣe ń lò ó láti fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tó tọ́ àti ohun tí kò tọ́.”​—Hébérù 5:14.

 “A máa ń bá àwọn ọmọ wa sọ̀rọ̀ nípa ìwà kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà torí a mọ̀ pé kò sí ibi tí wọ́n lè gbé tí wọn ò ti ní rí irú ìwà bẹ́ẹ̀. Èyí sì ṣe pàtàkì torí tá ò bá jọ sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ kí wọ́n tó kúrò nílé, àwọn náà lè bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe bíi tàwọn tó ń hùwà ìkà sáwọn tí ẹ̀yà tàbí àwọ̀ wọ́n yàtọ̀. Tá a bá ti kọ́ wọn láti ilé, wọn ò ní lè gba irọ́ táwọn kan bá pa fún wọn gbọ́.”​—Tanya.

 Bó o ṣe lè jẹ́ àpẹẹrẹ rere fún ọmọ rẹ

 Ó máa ń rọrùn fáwọn ọmọdé láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ tí wọ́n bá rí, torí náà ó ṣe pàtàkì kó o máa ṣọ́ ohun tó o bá ń sọ àtohun tó ò ń ṣe. Bí àpẹẹrẹ:

  •   Ṣé o máa ń fi àwọn tó wá láti ẹ̀yà míì ṣe yẹ̀yẹ́ tàbí kó o máa bú wọn? Ẹgbẹ́ Onímọ̀ Nípa Ìrònú àti Ìhùwà Àwọn Ọmọdé Àtàwọn Ọ̀dọ́ ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà sọ pé: “Rántí pé ohun tó o bá ń ṣe àti ohun tó o bá ń sọ làwọn ọmọ rẹ á máa fi hùwà.”

  •   Ṣé ó máa ń wù ẹ́ láti wà pẹ̀lú àwọn tó jẹ́ ẹ̀yà míì? Dókítà Alanna Nzoma tó ń bójú tó ọ̀rọ̀ ìlera àwọn ọmọdé sọ pé: “Tó o bá fẹ́ kí àwọn ọmọ rẹ . . . ní àjọṣe tó [dáa] pẹ̀lú àwọn tó wá láti ẹ̀yà míì, ìwọ náà gbọ́dọ̀ máa ṣe bẹ́ẹ̀.”

“Ẹ máa bọlá fún onírúurú èèyàn.”​—1 Pétérù 2:17.

 “Ọ̀pọ̀ ọdún ni ìdílé wa ti máa ń gba onírúurú èèyàn kárí ayé lálejò. A kọ́ orin wọn, oúnjẹ wọn kódà a tún wọ aṣọ ìbílẹ̀ wọn. Tá a bá ń bá àwọn ọmọ wa sọ̀rọ̀ nípa àwọn èèyàn, ohun tó dáa la máa ń sọ nípa wọn, a kì í tẹnu mọ́ bí ẹ̀yà wọ́n ṣe yàtọ̀ sí tiwa tàbí ká máa fọ́nnu nípa àṣà ìbílẹ̀ wa.”​—Katarina.

 Tí wọ́n bá kórìíra ọmọ rẹ nítorí ẹ̀yà tó ti wá

 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ gbà pé ó yẹ kí gbogbo èèyàn wà lọ́gbọọgba, síbẹ̀ ìwà kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà ló gbòde kan. Èyí fi hàn pé, wọ́n lè hùwà ìkà sí ọmọ tiẹ̀ náà pàápàá tó bá jẹ́ pé ẹ̀yà tí ò fi bẹ́ẹ̀ pọ̀ ló ti wá. Tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀ . . .

 Wádìí ohun tó ṣẹlẹ̀ gan-an. Ṣé ẹni náà mọ̀ọ́mọ̀ hùwà tí ò dáa yẹn ni tàbí ṣe ló kàn sọ̀rọ̀ tàbí hùwà láìronú? (Jémíìsì 3:2) Ṣé ó pọn dandan kó o pé àkíyèsí ẹni yẹn sí ohun tó ṣe tàbí kó o gbójú fò ó?

 Ká sòótọ́, ó yẹ ká fara balẹ̀. Bíbélì fún wa ní ìmọ̀ràn ọlọ́gbọ́n kan pé: “Má ṣe máa yára bínú.” (Oníwàásù 7:9) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà kì í ṣe ọ̀rọ̀ ṣeréṣeré, síbẹ̀ má ṣe yára gbà pé tẹ́nì kan bá bú ẹ tàbí tó hùwà tí ò dáa sí ẹ, ṣe lẹni náà kórìíra ẹ torí ẹ̀yà tó o ti wá.

 Fi sọ́kàn pé, ipò kọ̀ọ̀kan yàtọ̀ síra. Torí náà, kó o tó gbé ìgbésẹ̀ kankan rí i dájú pé o mọ ohun tó ṣẹlẹ̀.

“Tí ẹnì kan bá ń fèsì ọ̀rọ̀ láì tíì gbọ́ kúlẹ̀kúlẹ̀ rẹ̀, ìwà òmùgọ̀ ni, ó sì ń kó ìtìjú báni.”​—Òwe 18:13.

 Tó o bá ti wá mọ ohun tó ṣẹlẹ̀, bi ara ẹ pé:

  •   ‘Ṣé ìgbésẹ̀ tí mo fẹ́ gbé yìí ò ní jẹ́ kí ọmọ mi máa ronú pé, gbogbo èèyàn ló ń ṣe ẹ̀tanú tàbí kó gbà pé gbogbo ẹni tó bá bú òun ló ṣe bẹ́ẹ̀ torí ẹ̀yà tòun ti wá?’

  •   ‘Àǹfààní wo ni ìmọ̀ràn tó wà nínú ẹsẹ Bíbélì yìí máa ṣe ọmọ mi: “Má ṣe máa fọkàn sí gbogbo ọ̀rọ̀ tí àwọn èèyàn bá sọ”?’​—Oníwàásù 7:21.

“Ẹ jẹ́ kí gbogbo èèyàn rí i pé ẹ̀ ń fòye báni lò.”​—Fílípì 4:5.

 Tó bá jẹ́ pé ẹni náà mọ̀ọ́mọ̀ ṣe é ńkọ́? Jẹ́ kí ọmọ rẹ mọ̀ pé ohun tó bá sọ ló máa pinnu bóyá ọ̀rọ̀ náà máa lójútùú tàbí á le sí i. Nígbà míì, ṣe ni ẹni tó bá ń bú èèyàn, tó ń fi ṣe yẹ̀yẹ́ tàbí tó ń kàn án lábùkù ń retí ohun tẹni náà máa ṣe. Nírú ipò bẹ́ẹ̀, ohun tó dáa jù ni pé kéèyàn má ṣe irú ẹni bẹ́ẹ̀ lóhùn.

“Níbi tí kò bá sí igi, iná á kú.”​—Òwe 26:20.

 Nígbà míì sì rèé, ọmọ rẹ lè fún ẹni náà lésì tí kò bá léwu. Ó lè sọ (tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀) pé, “Mi ò rò pé ohun tó o sọ (tàbí ṣe) yẹn dáa tó.”

 Tó o bá fẹ́ fi ẹjọ́ náà sùn ńkọ́? Tí ẹ̀mí ọmọ ẹ bá wà nínú ewu tàbí tó o kíyè sí pé ọ̀rọ̀ náà gbẹgẹ́, o lè fọ̀rọ̀ náà tó àwọn aláṣẹ ilé-ìwé létí tàbí àwọn ọlọ́pàá tó bá pọn dandan.