Ṣé Ẹ̀ṣẹ̀ Ni Kí Èèyàn Mu Sìgá tàbí Igbó?
Ohun tí Bíbélì sọ
Bíbélì ò sọ̀rọ̀ nípa sìgá mímu a kò sì mẹ́nu kan àwọn nǹkan míì táwọn èèyàn máa ń mu lónìí. Àmọ́ àwọn ìlànà kan wà nínú Bíbélì tó jẹ́ ká mọ̀ pé ẹ̀ṣẹ̀ ni tẹ́nì kan bá ń mu sìgá, Ọlọ́run ò fọwọ́ sí i, àṣà tí kò dáa ni, ó sì máa ń sọ èèyàn di ẹlẹ́gbin.
Ọ̀wọ̀ fún ẹ̀mí. “Ọlọ́run . . . fún gbogbo ènìyàn ní ìyè àti èémí.” (Ìṣe 17:24, 25) Ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni ẹ̀mí, torí náà kò yẹ ká ṣe ohun tó máa pa ẹ̀mí yẹn lára, irú bí i ká máa mu sìgá. Ká sọ pé àwọn èèyàn lè jáwọ́ nínú sìgá mímu ni, àwọn èèyàn tó ń kú níbi gbogbo láyé máa dín kù.
Ìfẹ́ aládùúgbò. “Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.” (Mátíù 22:39) Ẹni tó bá ń mu sìgá níbi táwọn míì wà ò fìfẹ́ hàn. Àwọn tó máa ń fa èéfín sìgá símú níbi tẹ́nì kan ti ń mu sìgá máa ń ní àwọn àìsàn kan náà tí ẹni tó máa ń mu sìgá máa ń ní.
Ìdí tó fi yẹ ká jẹ́ mímọ́. “Ẹ fi ara yín fún Ọlọ́run ní ẹbọ ààyè, mímọ́, tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà.” (Róòmù 12:1) “Ẹ jẹ́ kí a wẹ ara wa mọ́ kúrò nínú gbogbo ẹ̀gbin ti ẹran ara àti ti ẹ̀mí, kí a máa sọ ìjẹ́mímọ́ di pípé nínú ìbẹ̀rù Ọlọ́run.” (2 Kọ́ríńtì 7:1) Sìgá ò dáa fún ara, ẹni tó bá sì ń mu ú ò lè jẹ́ mímọ́, irú ẹni bẹ́ẹ̀ máa di ẹlẹ́gbin, torí pé ńṣe làwọn tó ń fa sìgá ń mọ̀ọ́mọ̀ fa àwọn nǹkan tó máa ṣe ìpalára fún wọn sínú ara wọn.
Ṣe Bíbélì sọ ohunkóhun nípa mímu igbó àbí àwọn oògùn olóró míì?
Bíbélì ò dárúkọ igbó tàbí àwọn oògùn olóró míì. Àmọ́, ó fún wa láwọn ìlànà tó jẹ́ ká mọ̀ pé kò dáa kéèyàn máa mu àwọn nǹkan tó máa ń di bárakú fún èèyàn. Yàtọ̀ sí àwọn ìlànà tá a ti mẹ́nu bà tẹ́lẹ̀, àwọn ìlànà míì wà tó kan ọ̀rọ̀ yìí:
Ìdí tó fi yẹ ká lo agbára ìrònú wa. “Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run . . . pẹ̀lú gbogbo èrò inú rẹ.” (Mátíù 22:37, 38) “Ẹ pa agbára ìmòye yín mọ́ lọ́nà pípé pérépéré.” (1 Pétérù 1:13) Èèyàn ò lè lo ọpọlọ ẹ̀ bó ṣe yẹ tó bá ń lo àwọn oògùn nílòkulò, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ló sì ti di bárakú fún. Dípò kí wọ́n máa ro àwọn èrò tó máa ṣe èèyàn láǹfààní bí wọ́n ṣe máa rí oògùn tí wọ́n fẹ́ mu ló máa gbà wọ́n lọ́kàn.—Fílípì 4:8.
Ìgbọràn sí òfin ìlú. “Jẹ́ onígbọràn sí àwọn ìjọba àti àwọn aláṣẹ.” (Títù 3:1) Ní àwọn orílẹ̀-èdè kan, òfin ò gba àwọn èèyàn láyè láti lo àwọn oògùn olóró kan. Tá a bá fẹ́ ṣe ohun tó máa múnú Ọlọ́run dùn, ó yẹ ká máa ṣègbọràn sáwọn aláṣẹ.—Róòmù 13:1.
a Sìgá Mímu tá à ń sọ níbí ń tọ́ka sí àwọn tó ń mu ewé tábà, sìgá, ìkòkò. Àmọ́, àwọn ìlànà Bíbélì tá a máa gbé yẹ̀ wò níbí tún kan àwọn tó máa ń mu sìgá ìgbàlódé tó ń lo bátìrì tàbí àwọn tó ń jẹ ewé tábà tàbí tó ń fín áṣáà.