Ìgbà Wo Ni Òpin Ayé Máa Dé?
Ohun tí Bíbélì sọ
Láti mọ ìgbà tí òpin ayé máa dé, ó yẹ ká mọ ohun tí ọ̀rọ̀ náà “ayé” tó wà nínú Bíbélì máa ń túmọ̀ sí. Ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà, koʹsmos, tó túmọ̀ sí “ayé,” sábà máa ń tọ́ka sí aráyé, pàápàá àwọn tó kẹ̀yìn sí Ọlọ́run, tí wọn ò sì ṣe ìfẹ́ rẹ̀. (Jòhánù 15:18, 19; 2 Pétérù 2:5) Nígbà míì, koʹsmos máa ń tọ́ka sí ètò ìgbésí ayé ẹ̀dá èèyàn.—1 Kọ́ríńtì 7:31; 1 Jòhánù 2:15, 16. a
Kí ni “òpin ayé”?
Ọ̀pọ̀ ìtúmọ̀ Bíbélì lo ọ̀rọ̀ náà, “òpin ayé,” a sì tún lè pè é ní “ìparí ètò àwọn nǹkan” tàbí “ìparí igbeaye yìí.” (Mátíù 24:3; Bibeli Yoruba Atọ́ka) Kì í ṣe ìparun ayé tàbí gbogbo aráyé ló ń tọ́ka sí, òpin ètò ìgbésí ayé ẹ̀dá èèyàn ló ń tọ́ka sí.—1 Jòhánù 2:17.
Bíbélì fi kọ́ni pé “àwọn aṣebi ni a óò ké kúrò” kí àwọn èèyàn rere lè máa gbádùn lórí ilẹ̀ ayé. (Sáàmù 37:9-11) Ìparun yìí máa wáyé nígbà “ìpọ́njú ńlá,” èyí tó máa yọrí sí ogun Amágẹ́dọ́nì.—Mátíù 24:21, 22; Ìṣípayá 16:14, 16.
Ìgbà wo ni òpin ayé máa dé?
Jésù sọ pé: “Ní ti ọjọ́ àti wákàtí yẹn, kò sí ẹnì kankan tí ó mọ̀ ọ́n, àwọn áńgẹ́lì ọ̀run tàbí Ọmọ pàápàá kò mọ̀ ọ́n, bí kò ṣe Baba nìkan.” (Mátíù 24:36, 42) Ó tún sọ pé òjijì ni òpin máa dé, “ní wákàtí tí ẹ kò ronú pé yóò jẹ́.”—Mátíù 24:44.
Bó tiẹ̀ jẹ́ pé a ò lè mọ ọjọ́ àti wákàtí náà gan-an, Jésù jẹ́ ká mọ “àmì” tàbí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀, tó máa jẹ́ ká mọ àwọn ohun tó máa wáyé kí òpin ayé tó dé. (Mátíù 24:3, 7-14) Bíbélì pé àkókò tí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ náà máa wáyé ní “àkókò òpin,” “ìgbà ìkẹyìn,” àti “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn.”—Dáníẹ́lì 12:4; Bíbélì Mímọ́; 2 Tímótì 3:1-5.
Ṣé ohunkóhun máa ṣẹ́ kù lẹ́yìn tí òpin ayé bá dé?
Bẹ́ẹ̀ ni. Ayé tá à ń gbé yìí ò ní pa run, torí Bíbélì sọ pé “kò lè ṣípò padà láéláé.” (Sáàmù 104:5, Bíbélì Mímọ́) Àwọn èèyàn á sì kún ayé, bí ìlérí tó wà nínú Bíbélì, tó ní: “Àwọn olódodo ni yóò ni ilẹ̀ ayé, wọn yóò sì máa gbé títí láé lórí rẹ̀.” (Sáàmù 37:29) Ọlọ́run máa wá ṣe àwọn ohun tó ti ní lọ́kàn láti ṣe:
Párádísè.—Aísáyà 35:1; Lúùkù 23:43.
Ààbò máa wà, nǹkan á sì máa lọ dáadáa fún wa.—Míkà 4:4.
Gbogbo èèyàn máa ní iṣẹ́ tó dáa, tó sì tẹ́ wọn lọ́rùn.—Aísáyà 65:21-23.
Kò ní sí àìsàn àti ọjọ́ ogbó.—Jóòbù 33:25; Aísáyà 33:24.
a Àwọn Bíbélì kan tún túmọ̀ ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà, ai·onʹ sí “ayé”. Tí wọ́n bá túmọ̀ rẹ̀ lọ́nà yìí, ìtumọ̀ ai·onʹ àti koʹsmos máa ń jọra, òun náà máa ń tọ́ka sí ètò ìgbésí ayé ẹ̀dá èèyàn.