Ìyè àti Ikú
Ìgbé Ayé
Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Fi Dá Wa?
Ǹjẹ́ o máa ń ronú pé, ‘Kí nìdí tí Ọlọ́run fi dá wa?’ Wo bí Bíbélì ṣe dáhùn ìbéèrè yìí.
Kí Ni Ọlọ́run Fẹ́ Kí N Fi Ayé Mi Ṣe?
Ǹjẹ́ o nílò kí Ọlọ́run fi àmì àrà ọ̀tọ̀ kan hàn ọ́ tàbí kí Ọlọ́run bá ọ sọ̀rọ̀ kó o tó mọ bí wàá ṣe máa ṣe ìfẹ́ rẹ̀? Ka ohun tí Bíbélì sọ.
Báwo Lo Ṣe Lè Wà Láàyè Títí Láé?
Bíbélì ṣèlérí pé àwọn tó bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run máa wà láàyè títí láé. Wo ohun mẹ́ta tí Ọlọ́run fẹ́ ká ṣe.
Kí Ni Ọkàn?
Ṣé ohun kan tó wà nínú rẹ ni? Ṣé ọkàn máa ń kú?
Orúkọ Àwọn Wo Ni Wọ́n Kọ Sínú “Ìwé Ìyè”?
Ọlọ́run ṣèlérí pé òun máa rántí àwọn jẹ́ olóòótọ́ sí i. Ṣé orúkọ tìrẹ náà wà nínú “ìwé ìyè” rẹ̀?
Ikú
Kí Nìdí Tí Àwa Èèyàn Fi Ń Kú?
Ohun tí Bíbélì sọ nípa ìbéèrè yìí máa tù ọ́ nínú, yóò sì jẹ́ kó o ní ìrètí.
Kí Ló Ń Ṣẹlẹ̀ Nígbà Téèyàn Bá Kú?
Ṣé àwọn tó ti kú mọ ohun tó ń lọ láyìíká wọn?
Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Sísun Òkú?
Ṣé ọ̀nà kan ṣoṣo tó dáa ló wà tá a lè gbà palẹ̀ òkú mọ́?
Báwo Ni Bíbélì Ṣe Lè Ran Àwọn Tó Ń Ronú Àtipa Ara Wọn Lọ́wọ́?
Àwọn ìmọ̀ràn wo nínú Bíbélì ló wúlò fún ẹni táyé ti sú?
Báwo Lo Ṣe Lè Borí Ìbẹ̀rù Ikú?
Wàá gbádùn ìgbésí ayé rẹ tó o bá borí ìbẹ̀rù ikú tí kò bọ́gbọ́n.
Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Ohun Tí Àwọn Èèyàn Tó Sún Mọ́ Bèbè Ikú Sọ Pé Ó Ṣẹlẹ̀ sí Àwọn?
Ṣe bí ìwàláàyè lẹ́yìn ikú ṣe rí lohun tí wọ́n rí? Ohun tí Bíbélì sọ nípa àjíǹde Lásárù mú kí ọ̀rọ̀ yìí ṣe kedere.
Se Olorun Ti Kadara Igba Ti A Maa Ku?
Ki nidi ti Bibeli fi so pe “igba kiku” wa?
Kí ni Bíbélì Sọ Nípa Gbígba Ẹ̀mí Ẹnìkan Tó Ń Jẹ̀ Ìrora?
Ká sọ pé ẹnì kan ń ṣàìṣàn gbẹ̀mí-gbẹ̀mí ńkọ́? Ṣé pon dandan kí n ṣe gbogbo ohun tó bá gbà láti dá ẹ̀mí mi sí?
Ọ̀run Àpáàdì àti Ọ̀run
Ibo Là Ń Pè Ní Ọ̀run?
Bí Bíbélì ṣe lò o, ohun mẹ́ta ni ọ̀rọ̀ náà túmọ̀ sí.
Àwọn Wo Ló Ń Lọ sí Ọ̀run?
Ọ̀pọ̀ èèyàn ló gbà pé gbogbo èèyàn rere ló ń lọ sọ́run. Kí ni Bíbélì fi kọ́ni gan-an?
Ṣé Ọ̀run Àpáàdì Wà Lóòótọ́? Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Ọ̀run Àpáàdì?
Ohun tí àwọn ìsìn fi ń kọ́ni ni pé, ọ̀run àpáàdì jẹ́ ibi tí a ti ń fi iná dá àwọn èèyàn burúkú lóró títí ayérayé. Àmọ́, ṣe ohun tí Bíbélì fi kọ́ni nìyẹn?
Àwọn Wo Ló Ń Lọ sí Ọ̀run Àpáàdì?
Ǹjẹ́ àwọn èèyàn rere ń lọ sí ọ̀run àpáàdì? Ǹjẹ́ èèyàn lè kúrò ní ọ̀run àpáàdì? Ǹjẹ́ ọ̀run àpáàdì á wà títí láé? Bíbélì dáhùn àwọn ìbéèrè yìí.
Ta Ni Ọkùnrin Ọlọ́rọ̀ Náà àti Lásárù?
Ṣé àkàwé Jésù yìí fi hàn pé àwọn ẹni rere máa lọ sọ́run, àwọn èèyàn burúkú sì máa joró nínú iná ọ̀run àpáàdì?
Ṣé Pọ́gátórì Wà Nínú Bíbélì?
Ibi tí ẹ̀kọ́ yìí ti ṣẹ̀ wá lè yà ẹ́ lẹ́nu.
Ṣé Àwọn Ẹranko Ń Lọ sí Ọ̀run?
Kò síbì kankan tí Bíbélì ti sọ̀rọ̀ nípa ọ̀run èyíkéyìí tó wà fún ẹran ọ̀sìn, ó sì nídìí tó fi rí bẹ́ẹ̀.
Ìrètí fún Àwọn Òkú
Kí Ni Àjíǹde?
Ó lè yà ẹ́ lẹ́nu tó o bá mọ àwọn tí Bíbélì sọ pé Ọlọ́run máa jí dìde.
Ṣé Bíbélì Kọ́ni Pé Èèyàn Máa Ń Tún Ayé Wá?
Kí ló máa ń ṣẹlẹ̀ sí ẹni tó bá kú?