Bí Ìgbésí Ayé Mi Ṣe Rí Kò Mú Inú Mi Dùn, Ṣé Ìsìn, Ọlọ́run Tàbí Bíbélì Lè Ràn Mí Lọ́wọ́?
Ohun tí Bíbélì sọ
Bẹ́ẹ̀ ni. Bíbélì tí í ṣe ìwé ọgbọ́n tó ti wà tipẹ́tipẹ́ dáhùn àwọn ìbéèrè pàtàkì nípa ìgbésí ayé, yóò mú kí inú rẹ dùn, ara á sì tù ọ́ pẹ̀sẹ̀. Wo díẹ̀ lára àwọn ìbéèrè tí Bíbélì dáhùn.
Ǹjẹ́ ẹnì kan wà tó jẹ́ Ẹlẹ́dàá? Bíbélì sọ pé Ọlọ́run “ni ó dá ohun gbogbo.” (Ìṣípayá 4:11) Ọlọ́run tó dá wa, mọ àwọn nǹkan tí a nílò tó máa múnú wa dùn tó sì máa jẹ́ kí ìgbésí-ayé wa nítumọ̀.
Ṣé Ọlọ́run bìkítà nípa mi? Bíbélì kò sọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run bí ẹni tó rorò tí kì í sì í fẹ́ kí àwa èèyàn sún mọ́ òun. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó sọ pé: “Kò jìnnà sí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa.” (Ìṣe 17:27) Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ rẹ, ọ̀rọ̀ rẹ sì jẹ ẹ́ lógún gan-an torí ó fẹ́ ràn ọ́ lọ́wọ́ kó o lè ṣe àṣeyọrí nígbèésí ayé rẹ.—Aísáyà 48:17, 18; 1 Pétérù 5:7.
Tí mo bá mọ Ọlọ́run, báwo nìyẹn ṣe máa jẹ́ kí n láyọ̀? Ọlọ́run dá “àìní . . . ti ẹ̀mí” mọ́ wa, ìyẹn ni pé ó máa ń wù wá láti mọ ìdí tá a fi wà láyé. (Mátíù 5:3) Ara ohun tí àìní nípa ti ẹ̀mí tá a ní wé mọ́ ni pé kó máa wù wá láti mọ Ẹlẹ́dàá wa ká sì ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú rẹ̀. Inú Ọlọ́run máa dùn gan-an tó o bá ń sapá láti mọ̀ ọ́n, torí Bíbélì sọ pé: “Ẹ sún mọ́ Ọlọ́run, yóò sì sún mọ́ yín.”—Jákọ́bù 4:8.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn ti wá rí i pé bí àwọn ṣe ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run ló jẹ́ kí ìgbésí ayé àwọn nítumọ̀, tó sì jẹ́ kí ọkàn àwọn balẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé tó o bá mọ Ọlọ́run, ìyẹn kò túmọ̀ sí pé o kò ní ní ìṣòro rárá, àmọ́ ọgbọ́n Ọlọ́run tó wà nínú Bíbélì yóò jẹ́ kí o
Ní ìdílé aláyọ̀.
Wà ní àlàáfíà pẹ̀lú àwọn èèyàn.
Lè yanjú àwọn ìṣòro bí ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn, ìdààmú ọkàn tí ọ̀rọ̀ owó ń fà àti àìsàn ọlọ́jọ́ pípẹ́.
Ọ̀pọ̀ ìsìn ni kì í tẹ̀ lé ohun tí wọ́n kọ́ nínú Bíbélì. Àmọ́ ìsìn tòótọ́ tó ń tẹ̀ lé ohun tí Bíbélì sọ yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti mọ Ọlọ́run.