Báwo Lo Ṣe Lè Borí Ìbẹ̀rù Ikú?
Ohun tí Bíbélì sọ
A máa ń bẹ̀rù ikú lóòótọ́ torí ọ̀tá wa ni, a sì máa n sa gbogbo ipá wa ká lè dáàbò bo ẹ̀mí wa. (1 Kọ́ríńtì 15:26) Àmọ́, ìbẹ̀rù ikú tí kò bọ́gbọ́n mu nítorí ìtàn èké tàbí ìgbàgbọ́ nínú àwọn ohun asán ti fi àwọn èèyàn “sábẹ́ ìsìnrú ní gbogbo ìgbésí ayé wọn.” (Hébérù 2:15) Tó o bá ń bẹ̀rù ikú ju bó ṣe yẹ lọ, o kò ní gbádùn ìgbésí ayé rẹ, àmọ́ tó o bá mọ òtítọ́, wàá bọ́ lọ́wọ́ ìbẹ̀rù ikú.—Jòhánù 8:32.
Òtítọ́ nípa ohun tí ikú jẹ́
Àwọn òkú kò mọ nǹkan kan. (Sáàmù 146:4) Má ṣe máa bẹ̀rù pé wàá jìyà tàbí joró lẹ́yìn tó o bá kú, torí pé Bíbélì fi ikú wé oorun.—Sáàmù 13:3; Jòhánù 11:11-14.
Àwọn òkú kò lè pa wá lára. Kódà, àwọn oníjàgídíjàgan tó jẹ́ ọ̀tá wa tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ tí di “aláìlè-ta-pútú nínú ikú.” (Òwe 21:16) Bíbélì sọ pé: “ìkórìíra wọn àti owú wọn ti ṣègbé.”—Oníwàásù 9:6.
Ikú kì í ṣe òpin ìrìn àjò ẹ̀dá láyé. Ọlọ́run yóò jí àwọn èèyàn tó ti ku dìde nípasẹ̀ àjíǹde.—Jòhánù 5:28, 29; Ìṣe 24:15.
Ọlọ́run ṣèlérí pé ìgbà kan ń bọ̀ tí ‘ikú kì yóò sí mọ́.’ (Ìṣípayá 21:4) Nígbà yẹn, àwọn èèyàn á ti bọ́ pátápátá lọ́wọ́ ìbẹ̀rù ikú èyíkéyìí. Bíbélì sọ pé: “Àwọn olódodo ni yóò ni ilẹ̀ ayé, wọn yóò sì máa gbé títí láé lórí rẹ̀.”—Sáàmù 37:29.