Ǹjẹ́ Ọlọ́run Fọwọ́ Sí I Pé Kí Ọkùnrin Fẹ́ Ju Ìyàwó Kan Lọ?
Ohun tí Bíbélì sọ
Láwọn ìgbà kan, Ọlọ́run fàyè gba ọkùnrin kan láti ní ju ìyàwó kan lọ. (Jẹ́nẹ́sísì 4:19; 16:1-4; 29:18–29) Àmọ́ Ọlọ́run kọ́ ló dá àṣà kí ọkùnrin máa fẹ́ ju ìyàwó kan lọ sílẹ̀. Ìyàwó kan ṣoṣo ló fún Ádámù.
Ọlọ́run ní kí Jésù Kristi fìdí ohun tí òun ní lọ́kàn ní ìbẹ̀rẹ̀ múlẹ̀ pa dà, ohun náà ni pé kí ọkùnrin fẹ́ ìyàwó kan ṣoṣo. (Jòhánù 8:28) Nígbà táwọn èèyàn béèrè ọ̀rọ̀ nípa ìgbéyàwó lọ́wọ́ Jésù, ó ní: “Ẹni tí ó dá wọn láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ṣe wọ́n ní akọ àti abo, ó sì wí pé, ‘Nítorí ìdí yìí ọkùnrin yóò fi baba rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀, yóò sì fà mọ́ aya rẹ̀, àwọn méjèèjì yóò sì di ara kan.’”—Mátíù 19:4, 5.
Nígbà tó yá, Ọlọ́run mí sí ọ̀kan lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù láti sọ pé: “Kí olúkúlùkù ọkùnrin ní aya tirẹ̀, kí olúkúlùkù obìnrin sì ní ọkọ tirẹ̀.” (1 Kọ́ríńtì 7:2) Bíbélì tún sọ pé, Kristẹni ọkùnrin èyíkéyìí tó ti gbéyàwó tí wọ́n bá fún ní iṣẹ́ àrà ọ̀tọ̀ nínú ìjọ Ọlọ́run gbọ́dọ̀ jẹ́ “ọkọ aya kan.”—1 Tímótì 3:2, 12.