Báwo Ni Mo Ṣe Lè Máa Ṣe Ìpinnu Tó Mọ́gbọ́n Dání?
Ohun Tí Bíbélì Sọ
Bíbélì jẹ́ ká mọ ọ̀nà tó dáa jù lọ tí a lè gbà ṣe ìpinnu. Ó lè jẹ́ ká “ní ọgbọ́n [àti] òye.” (Òwe 4:5) Láwọn ìgbà míì, ó máa ń sọ ìpinnu tó dáa jù lọ tá a lè ṣe fún wa. Nígbà míì sì rèé, ìmọ̀ràn tó máa jẹ́ ká lè ṣe ìpinnu tó mọ́gbọ́n dání ló máa fún wa.
Nínú àpilẹ̀kọ yìí
Àwọn ohun tó máa jẹ́ kó o lè ṣe ìpinnu tó mọ́gbọ́n dání
Má kánjú ṣèpinnu. Bíbélì sọ pé: “Aláròjinlẹ̀ máa ń ronú lórí ìgbésẹ̀ kọ̀ọ̀kan.” (Òwe 14:15) Tó o bá kánjú ṣèpinnu, o lè má fọkàn sáwọn ohun tó ṣe pàtàkì. Torí náà, ronú dáadáa nípa àwọn ohun tó o fẹ́ ṣe kó o tó ṣèpinnu.—1 Tẹsalóníkà 5:21.
Má fi bí nǹkan ṣe rí lára ẹ ṣèpinnu. Bíbélì kìlọ̀ fún wa pé ọkàn wa ò ṣeé fìgbà gbogbo gbẹ́kẹ̀ lé. (Òwe 28:26; Jeremáyà 17:9) Bí àpẹẹrẹ, tá a bá ń bínú, tá a rẹ̀wẹ̀sì, tí nǹkan tojú sú wa, tára wa ò balẹ̀ tàbí tó rẹ̀ wá tẹnutẹnu a lè má ṣèpinnu tó dáa nírú àwọn àkókò yìí.—Òwe 24:10; 29:22.
Máa gbàdúrà fún ọgbọ́n. (Jémíìsì 1:5) Irú àdúrà tí Ọlọ́run máa ń fẹ́ dáhùn nìyẹn. Bàbá onífẹ̀ẹ́ ni, kò sì fẹ́ káwọn ọmọ ẹ̀ kó sínú ìṣòro bó bá ti lè ṣeé ṣe tó. “Jèhófà fúnra rẹ̀ ló ń fúnni ní ọgbọ́n; ẹnu rẹ̀ ni ìmọ̀ àti ìfòyemọ̀ ti ń wá.” a (Òwe 2:6) Inú Bíbélì tó jẹ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, ló ti ń fún wa ní ọgbọ́n yìí.—2 Tímótì 3:16, 17.
Ṣe ìwádìí. Kó o tó lè ṣèpinnu tó mọ́gbọ́n dání, ó yẹ kó o mọ àwọn ohun tó ṣe pàtàkì. Bíbélì sọ pé, “ọlọ́gbọ́n máa ń fetí sílẹ̀, á sì kọ́ ẹ̀kọ́ sí i.” (Òwe 1:5) Ibo lo ti lè rí àlàyé tó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ tó sì ṣeé gbára lé?
Kọ́kọ́ wo ohun tí Bíbélì sọ nípa ohun tí o fẹ́ ṣe. Ẹlẹ́dàá wa mọ ohun tó dáa jù lọ fún wa, inú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ la sì ti lè rí ìmọ̀ràn tó ṣeé gbára lé jù lọ. (Sáàmù 25:12) Tá a bá fẹ́ ṣe àwọn ìpinnu kan, Bíbélì sọ òfin tàbí àṣẹ tá a máa tẹ̀ lé, ìyẹn sì lè jẹ́ ká mọ ohun tó yẹ ká ṣe ní tààràtà. (Àìsáyà 48:17, 18) Bẹ́ẹ̀ sì rèé, lọ́pọ̀ ìgbà, Bíbélì lè má sọ ohun tó yẹ ká ṣe ní tààràtà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó lè fi àwọn ìlànà kan tọ́ wa sọ́nà. Èyí máa jẹ́ ká lè ṣèpinnu tó tọ́, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ohun tá a yàn lè yàtọ̀ sí ti ẹlòmíì. Tó o bá fẹ́ rí ìmọ̀ràn tó wúlò nínú Bíbélì, ṣèwádìí nínú àwọn àpilẹ̀kọ tàbí ìtẹ̀jáde tó dá lórí Bíbélì, irú àwọn tó wà lórí ìkànnì yìí. b
Kó o tó ṣe àwọn ìpinnu kan, ó lè gba pé kó o wo ohun táwọn míì sọ àmọ́, rí i dájú pé ọ̀rọ̀ wọn ṣeé gbára lé. Bí àpẹẹrẹ, kó o tó kówó lé ọjà kan pàápàá tó bá jẹ́ olówó ńlá, ó máa dáa kó o kọ́kọ́ ṣèwádìí nípa ẹ̀ àtàwọn tó ṣe é, títí kan àdéhùn tó wà lórí ẹ̀ bóyá wọ́n máa gbà á pa dà tí ò bá dáa àti iye ọdún tó máa lò kó tó nílò àtúnṣe. Bákan náà, ó yẹ kó dá ẹ lójú bóyá ohun tó o fẹ́ rà náà máa lè ṣe ohun tó o fẹ́.
Bíbélì sọ pé: “Láìsí ìfinúkonú, èrò á dasán.” (Òwe 15:22) Torí náà, kó o tó ṣèpinnu, fọ̀rọ̀ lọ àwọn tó ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé. Bí àpẹẹrẹ, ó máa bọ́gbọ́n mu kó o fọ̀rọ̀ lọ dókítà tó o bá fẹ́ yan irú ìtọ́jú tó yẹ kó o gbà. (Mátíù 9:12) Nígbà míì, ó lè gba pé kó o fọ̀rọ̀ lọ àwọn tó ti ṣe irú nǹkan tíwọ náà fẹ́ ṣe rí. Àmọ́ fi sọ́kàn pé, ìwọ ló máa pinnu ohun tó o máa ṣe, ìwọ náà lo sì máa kórè àbájáde ẹ̀, kì í ṣe àwọn tó o fọ̀rọ̀ lọ̀.—Gálátíà 6:4, 5.
Gbé gbogbo ohun tó jẹ mọ́ ọ̀rọ̀ náà yẹ̀ wò dáadáa. Látinú ìwádìí tó o bá ṣe, o lè kọ àwọn ohun tó o lè ṣe sílẹ̀, kó o sì tún kọ àǹfààní àtàwọn ìṣòro tó máa yọjú lórí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn. Tún ronú nípa àwọn ohun tó ṣeé ṣe kí ìpinnu tó o ṣe yọrí sí. (Diutarónómì 32:29) Bí àpẹẹrẹ, ipa wo ni ohun tó o fẹ́ yìí máa ní lórí ẹ, ìdílé ẹ, àtàwọn míì? (Òwe 22:3; Róòmù 14:19) Tó o bá fi ohun tí Bíbélì sọ ṣàyẹ̀wò ìdáhùn rẹ sáwọn ìbéèrè yìí, ó máa jẹ́ kó o lè ṣèpinnu tó mọ́gbọ́n dání tó sì máa fi hàn pé o nífẹ̀ẹ́ àwọn míì.
Pinnu ohun tó o máa ṣe. Nígbà míì, a lè má fẹ́ ṣèpinnu torí pé ohun tá a fẹ́ ṣe ò dá wa lójú. Àmọ́ tá ò bá ṣèpinnu, àǹfààní tá a ní lè bọ́ mọ́ wa lọ́wọ́, kí ohun tí a ò fẹ́ sì ṣẹlẹ̀ sí wa. Torí náà, a lè sọ pé, bí ìpinnu tí kò dáa ò ṣe bọ́gbọ́n mu náà ni àìṣe ìpinnu kankan ò ṣe bọ́gbọ́n mu. Bíbélì fi ẹni tó fẹ́ ṣiṣẹ́ ọ̀gbìn ṣàpèjúwe ọ̀rọ̀ yìí pé: “Ẹni tí ń wo ojú afẹ́fẹ́ kò ní fún irúgbìn kankan, ẹni tí ó bá sì ń wo ṣúṣú òjò kò ní kórè.”—Oníwàásù 11:4, Bíbélì Ìròhìn Ayọ̀.
Máa rántí pé kò sí bí ìpinnu kan ṣe dáa tó, tí ò ní níbi tó kù sí. Tá a bá ti yan ohun kan, ó lè gba pé ká pa ìkejì tì. Ohun tá ò retí sì lè ṣàdédé ṣẹlẹ̀. (Oníwàásù 9:11) Torí náà, fi ohun tó o rí nínú ìwádìí rẹ pinnu èyí tó o rí pé ó máa ṣàṣeyọrí.
Ṣé kí n yí ìpinnu tí mo ti ṣe pa dà?
Kì í ṣe gbogbo ìpinnu ni kò ṣeé yí pa dà. Nǹkan lè yí pa dà, tàbí kó jẹ́ pé ibi tó o fojú sí, ọ̀nà ò gbabẹ̀. Torí náà, ó lè gba pé kó o tún ọ̀rọ̀ náà gbé yẹ̀ wò, kó o sì yan ohun míì tó máa jẹ́ kọ́wọ́ ẹ lè tẹ ohun tó o fẹ́.
Àmọ́, àwọn ìpinnu kan wà tí kò yẹ kó o yí pa dà. (Sáàmù 15:4) Bí àpẹẹrẹ, Ọlọ́run retí pé káwọn tọkọtaya má yẹ àdéhùn tí wọ́n ṣe nínú ẹ̀jẹ́ ìgbéyàwó wọn. c (Málákì 2:16; Mátíù 19:6) Tíṣòro bá dé nínú ìdílé, ńṣe ló yẹ kí àwọn méjèèjì sa gbogbo ipá wọn láti yanjú ẹ̀ dípò kí wọ́n tú ìgbéyàwó wọn ká.
Tí mo bá ti ṣe ìpinnu kan tí kò dáa, tí mi ò sì lè yí i pa dà ńkọ́?
Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, gbogbo wa la máa ń ṣe ìpinnu tí kò dáa tàbí tí kò bọ́gbọ́n mu. (Jémíìsì 3:2, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé) Èyí sì lè jẹ́ ká kábàámọ̀ tàbí ká máa dá ara wa lẹ́bi, kò burú tó bá ń ṣe wá bẹ́ẹ̀. (Sáàmù 69:5) Kódà, tí ọkàn wa bá ń dá wa lẹ́bi lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ó lè má jẹ́ ká ṣàṣìṣe kan náà nígbà míì! (Òwe 14:9) Àmọ́, Bíbélì gbà wá níyànjú pé ká má máa dá ara wa lẹ́bi kọjá bó ṣe yẹ lọ, torí ó lè mú kí nǹkan tojú sú wa tàbí ká má lè ronú bó ṣe tọ́. (2 Kọ́ríńtì 2:7) d Bíbélì sọ pé: “Aláàánú ni Jèhófà, ó sì ń gba tẹni rò.” (Sáàmù 103:8-13) Nítorí náà, kẹ́kọ̀ọ́ látinú ìpinnu tí kò dáa tí kò sì ṣeé yí pa dà tó o ṣe, kó o sì sapá láti ṣe ohun tágbára ẹ gbé kó o lè máa ṣe nǹkan lọ́nà tó dáa sí i.
a Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run.—Sáàmù 83:18.
b O lè fi ọ̀rọ̀ tàbí gbólóhùn kan tó jẹ mọ́ ìpinnu náà ṣèwádìí lórí ìkànnì jw.org. Wà á rí ìmọ̀ràn lóríṣiríṣi tó dá lórí Bíbélì níbẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, o lè wá àwọn ọ̀rọ̀ kan pàtó lábẹ́ apá tá a pè ní “Atọ́ka Ọ̀rọ̀ inú Bíbélì” nínú Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun.
c Ọlọ́run fẹ́ kí àwọn tọkọtaya tó ti ṣègbéyàwó jọ máa gbé pọ̀ ní gbogbo ọjọ́ ayé wọn. Àfi ti ọ̀kan lára wọn bá ṣe àgbèrè ni wọ́n fi lè tú ká, kí wọ́n sì fẹ́ ẹlòmíì. (Mátíù 19:9) Tó o bá níṣòro nínú ìdílé ẹ, Bíbélì lè jẹ́ kó o mọ ọ̀nà tó o fi lè fọgbọ́n àti ìfẹ́ yanjú ẹ̀.
d Tó o bá fẹ́ àlàyé sí i, wo àpilẹ̀kọ “Mò Ń Dá Ara Mi Lẹ́bi—Ṣé Bíbélì Lè Mú Kára Tù Mí?”