Kí Ló Túmọ̀ Sí Láti ‘Bọlá fún Baba àti Ìyá Rẹ’?
Ohun tí Bíbélì sọ
Àṣẹ Ọlọ́run tó sọ pé ‘bọlá fún baba àti ìyá rẹ’ fara hàn ní ọ̀pọ̀ ìgbà nínú Bíbélì. (Ẹ́kísódù 20:12; Diutarónómì 5:16; Mátíù 15:4; Éfésù 6:2, 3) Àṣẹ yẹn gba pé kéèyàn ṣe nǹkan mẹ́rin kan.
Mọyì wọn. Wàá fi hàn pé ò ń bọlá fún bàbá àti ìyá rẹ tó o bá ń dúpẹ́ gbogbo ohun tí wọ́n ti ṣe fún ẹ. O lè fi hàn pó o mọyì wọn tó o bá ń tẹ̀lé ìmọ̀ràn tí wọ́n fún ẹ. (Òwe 7:1, 2; 23:26) Bíbélì sọ pé kó o máa rí àwọn òbí rẹ bí “ẹwà” rẹ, ìyẹn ni pé kó o máa rí wọn dunnú.—Òwe 17:6.
Gbọ́ràn sí wọn lẹ́nu. Ọlọ́run ló fún àwọn òbí ẹ ní ọlá àṣẹ lórí ẹ, torí náà ó yẹ kó o bọlá fún bàbá àti ìyá rẹ, pàápàá nígbà tó o ṣì kéré yìí. Kólósè 3:20 sọ fún àwọn ọmọ pé: “Ẹ jẹ́ onígbọràn sí àwọn òbí yín nínú ohun gbogbo, nítorí èyí dára gidigidi nínú Olúwa.” Kódà, Jésù náà gbọ́ràn sáwọn òbí ẹ̀ lẹ́nu nígbà tó wà lọ́mọdé.—Lúùkù 2:51.
Bọ̀wọ̀ fún wọn. (Léfítíkù 19:3; Hébérù 12:9) Èyí kan irú ọ̀rọ̀ tó o máa ń sọ sí wọn àti bó o ṣe máa ń sọ ọ́. Lóòótọ́, nígbà míì àwọn òbí kan máa ń ṣe ohun tó lè mú kó ṣòro láti bọ̀wọ̀ fún wọn. Láìka ìyẹn sí, àwọn ọmọ ṣì lè rí i pé àwọn ò sọ̀rọ̀ àrínfín tàbí hùwà àìlọ́wọ̀ sí wọn, ìyẹn máa fi hàn pé wọ́n ń bọlá fún àwọn òbí wọn. (Òwe 30:17) Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ẹ̀ṣẹ̀ ńlá ni téèyàn bá ń sọ̀rọ̀ àwọn òbí ẹ̀ láìda.—Mátíù 15:4.
Pèsè ohun tí wọ́n nílò. Táwọn òbí ẹ bá darúgbó, wọ́n máa nílò kó o ṣe àwọn nǹkan kan fún wọn. Wàá fi hàn pó o bọlá fún wọn tó o bá ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe láti pèsè ohun tí wọ́n bá nílò. (1 Tímótì 5:4, 8) Bí àpẹẹrẹ, nígbà tó ku díẹ̀ kí Jésù kú, ó ṣètò ẹni táá máa tọ́jú ìyá rẹ̀.—Jòhánù 19:25-27.
Àwọn àṣìlóye lórí ọ̀rọ̀ bíbọlá fún bàbá àti ìyá ẹni
Àṣìlóye: Kó o lè fi hàn pó o bọlá fún bàbá àti ìyá rẹ, àfi kó o jẹ́ kí wọ́n máa sọ ohun tó yẹ kó o ṣe nínú ìdílé rẹ.
Òótọ́: Bíbélì kọ́ wa pé ìdè tó wà nínú ìgbéyàwó lágbára ju ọ̀rọ̀ ẹbí lọ. Jẹ́nẹ́sísì 2:24 sọ pé: ‘Ọkùnrin yóò fi baba rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀ tí yóò sì fà mọ́ aya rẹ̀.’ (Mátíù 19:4, 5) Lóòótọ́, àwọn tọkọtaya lè jàǹfààní látinú ìmọ̀ràn táwọn òbí tàbí àna wọn bá fún wọn. (Òwe 23:22) Àmọ́, tọkọtìyàwó kan lè yàn láti fi ìwọ̀n sí bí àwọn mọ̀lẹ́bí á ṣe máa dá sí ọ̀rọ̀ ìdílé wọn.—Mátíù 19:6.
Àṣìlóye: Bàbá àti ìyá rẹ ló láṣẹ lórí rẹ jù.
Òótọ́: Lóòótọ́ Ọlọ́run fún àwọn òbí ní ọlá àṣẹ nínú ìdílé, síbẹ̀ gbogbo èèyàn ló ní ibi táṣẹ rẹ̀ mọ, kò sì sí èyí tó ju ọlá àṣẹ Ọlọ́run lọ. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tílé ẹjọ́ gíga pàṣẹ fún àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù pé kí wọ́n ṣe ohun tí Ọlọrun kò fẹ́, wọ́n fèsì pé: “Àwa gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso dípò àwọn ènìyàn.” (Ìṣe 5:27-29) Bákan náà, àwọn ọmọ gbọ́dọ̀ máa gbọ́ràn sáwọn òbí wọn lẹ́nu “ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Olúwa,” ìyẹn nínú gbogbo nǹkan tí kò bá ti ta ko òfin Ọlọrun.—Éfésù 6:1.
Àṣìlóye: Tó o bá fẹ́ fi hàn pé ò ń bọlá fún bàbá àti ìyá rẹ, o gbọ́dọ̀ ṣe ẹ̀sìn tí wọ́n ń ṣe.
Òótọ́: Bíbélì gbà wá níyànjú pé ká máa gbé àwọn nǹkan tí wọ́n ń kọ́ wa yẹ̀wò bóyá wọ́n jẹ́ òótọ́. (Ìṣe 17:11; 1 Jòhánù 4:1) Ẹni tó bá ṣe bẹ́ẹ̀ lè wá yàn láti ṣe ẹ̀sìn míì tó yàtọ̀ sí tàwọn òbí rẹ̀. Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run olóòótọ́ kan tí wọn ò ṣe ẹ̀sìn táwọn òbí wọn ń ṣe, irú bí Ábúráhámù, Rúùtù àti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù.—Jóṣúà 24:2, 14, 15; Rúùtù 1:15, 16; Gálátíà 1:14-16, 22-24.
Àṣìlóye: Kó o lè bọlá fún bàbá àti ìyá rẹ, o gbọ́dọ̀ lọ́wọ́ sí àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ wọn.
Òótọ́: Bíbélì sọ pé: “Jèhófà Ọlọ́run rẹ ni ìwọ gbọ́dọ̀ jọ́sìn, òun nìkan ṣoṣo sì ni ìwọ gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ fún.” (Lúùkù 4:8) Ẹni tó bá ń jọ́sìn àwọn baba ńlá ń ṣe ohun tí Ọlọ́run kò fẹ́. Àti pé, Bíbélì sọ pé ‘àwọn òkú kò mọ nǹkan kan rárá.’ Wọn ò mọ̀ bóyá ẹnì kan ń jọ́sin àwọn, bẹ́ẹ̀ ni wọn ò lè ràn wá lọ́wọ́ tàbí kí wọ́n ṣe ìpalára fún ẹnikẹ́ni.—Oníwàásù 9:5, 10; Aísáyà 8:19.