Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Ọdún Kérésìmesì?
Ohun tí Bíbélì sọ
Bíbélì kò sọ ìgbà tí wọ́n bí Jésù fún wa, kò sì sọ pé ká máa ṣe ayẹyẹ ọjọ́ ìbí Jésù. Ìwé agbédègbẹ́yọ̀ Cyclopedia ti McClintock àti Strong, sọ pé: “Ọdún Kérésìmesì kì í ṣe ohun tí Ọlọ́run pa láṣẹ, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ohun tó jọ ọ́ nínú Májẹ̀mú Tuntun.”
Kàkà bẹ́ẹ̀, tá a bá wo ohun tí ìtàn sọ nípa ọdún Kérésìmesì dáadáa, a ó rí i pé inú ẹ̀sìn àwọn abọ̀rìṣà ló ti wá. Bíbélì fi hàn pé ẹ̀ṣẹ̀ ni tá a bá ń sìn Ọlọ́run ní ọ̀nà tí kò tẹ́wọ́ gbà.—Ẹ́kísódù 32:5-7.
Ìtàn nípa ibi tí àwọn àṣà ọdún Kérésìmesì ti wá
Ayẹyẹ Ọjọ́ Ìbí Jésù: “Àwọn Kristẹni ìjímìjí kò ṣayẹyẹ ọjọ́ ìbí [Jésù] torí pé àṣà ìbọ̀rìṣà ni wọ́n ka ṣíṣe ayẹyẹ ọjọ́ ìbí ẹnikẹ́ni sí.”—Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The World Book Encyclopedia.
Oṣù December 25: Kò sí ẹ̀rí tó fi hàn pé oṣù December 25 ni wọ́n bí Jésù. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ àwọn aṣáájú Ṣọ́ọ̀ṣì ló mú oṣù December 25 torí kó lè bọ́ sí ọjọ́ kan náà tí àwọn abọ̀rìṣà máa ń ṣe àwọn àjọ̀dún wọn nígbà òtútù tàbí ní nǹkan bí ìgbà òtútù.
Fífúnni lẹ́bùn, pọ̀pọ̀ṣìnṣìn ọdún àti àríyá: Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The Encyclopedia Americana sọ pé: “Àsè àwọn ará Róòmù tí wọ́n máa ń ṣe ní ìdajì oṣù December ni ayẹyẹ Saturnalia, ọ̀kan pàtàkì ni ayẹyẹ yìí jẹ́ nínu ọ̀pọ̀ ayẹyẹ tí pọ̀pọ̀ṣìnṣìn ti máa ń wáyé nígbà ọdún Kérésìmesì. Bí àpẹẹrẹ, nínú ayẹyẹ yìí ní wọ́n ti rí àṣà síse àsè rẹpẹtẹ, fífúnni lẹ́bùn àti jíjó àbẹ́là.” Ìwé Encyclopædia Britannica sọ pé “ńṣe ni àwọn èèyàn máa ń pa iṣẹ́ àti okòwò wọn tì” nígbà ọdún Saturnalia.
Iná Kérésì: Ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí ìwé The Encyclopedia of Religion sọ, àwọn ará Yúróòpù máa ń fi “iná àtàwọn oríṣiríṣi igi tó máa ń tutù yọ̀yọ̀ jálẹ̀ ọdún” ṣe ilé wọn lọ́ṣọ̀ọ́ torí kí wọ́n lè ṣe àjọ̀dún ọjọ́ ìbí oòrùn kí wọ́n sì gbógun ti àwọn ẹ̀mí búburú.
Igi àfòmọ́ oníṣàáná àti igi holly: “Àwọn Druid (àwọn àlùfáà inú ẹ̀sìn Celtic ilẹ̀ Britain ìgbàanì) gbà gbọ́ pé igi àfòmọ́ oníṣàáná ní agbára àràmàǹdà lára. Wọ́n máa ń bọ igi holly tó máa ń tutù yọ̀yọ̀ jálẹ̀ ọdún gẹ́gẹ́ bí àmì pé oòrùn ti pa dà wá bó ṣe sọ.”—Ìwé The Encyclopedia Americana.
Igi Kérésìmesì: “Àṣà igi bíbọ wọ́pọ̀ láàárín àwọn abọ̀rìṣà ilẹ̀ Yúróòpù, àṣà yìí sì ń bá a lọ lẹ́yìn tí wọ́n di ẹlẹ́sìn Kristẹni.” Ọ̀kan lára àwọn àṣà igi bíbọ tó ṣì ń bá a lọ ni àṣà “gbígbé igi Kérésì sí ẹnu ọ̀nà àbáwọlé tàbí ìta ilé ní ọjọ́ ọdún Kérésìmesì.”—Ìwé Encyclopædia Britannica.