ÀLÀYÉ ÀWỌN ẸSẸ BÍBÉLÌ
Jẹ́nẹ́sísì 1:26—“Jẹ́ Ká Dá Èèyàn ní Àwòrán Wa”
“Lẹ́yìn náà, Ọlọ́run sọ pé: “Jẹ́ ká dá èèyàn ní àwòrán wa, kí wọ́n jọ wá, kí wọ́n sì máa jọba lórí àwọn ẹja inú òkun, àwọn ẹ̀dá tó ń fò lójú ọ̀run, àwọn ẹran ọ̀sìn, lórí gbogbo ayé àti lórí gbogbo ẹran tó ń rákò tó sì ń rìn lórí ilẹ̀.’”—Jẹ́nẹ́sísì 1:26, Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun.
“Ọlọrun si wipe, Jẹ ki a dá enia li aworan wa, gẹgẹ bi irí wa: ki nwọn ki o si jọba lori ẹja okun, ati lori ẹiyẹ oju-ọrun, ati lori ẹranko, ati lori gbogbo ilẹ, ati lori ohun gbogbo ti nrakò lori ilẹ.’”—Jẹ́nẹ́sísì 1:26, Bíbélì Mímọ́.
Ohun Tí Jẹ́nẹ́sísì 1:26 Túmọ̀ Sí
Ọlọ́run dá àwa èèyàn ní àwòrán ara rẹ̀, ìyẹn ló jẹ́ ká ní àwọn ànímọ́ tó ní, bí ìfẹ́, àánú àti ìdájọ́ òdodo. Ìdí nìyẹn táwa èèyàn fi lè fara wé Ọlọ́run.
“Ọlọ́run sọ pé: ‘Jẹ́ ká dá èèyàn ní àwòrán wa.’” Kí Jèhófà Ọlọ́run a tó dá ohunkóhun tàbí ẹnikẹ́ni, ó kọ́kọ́ dá áńgẹ́lì alágbára kan tá a wá mọ̀ sí Jésù. Nípasẹ̀ Jésù “ni a dá gbogbo ohun mìíràn ní ọ̀run àti ní ayé.” (Kólósè 1:16) Jésù fìwà jọ Ọlọ́run torí pé “òun ni àwòrán Ọlọ́run tí a kò lè rí.” (Kólósè 1:15) Ìdí nìyẹn tí Ọlọ́run fi lè sọ fún Jésù pé: “Jẹ́ ká dá èèyàn ní àwòrán wa.”
‘Kí wọ́n sì máa jọba lórí àwọn ẹran ọ̀sìn àti lórí gbogbo ayé.’ Ọlọ́run ò dá àwọn ẹranko ní àwòrán rẹ̀. Ọlọ́run ò dá wọn pé kí wọ́n ní àwọn ànímọ́ tí àwa èèyàn ní irú bí ìfẹ́. Bákan náà, Ọlọ́run ò dá ẹ̀rí ọkàn mọ́ wọn. Síbẹ̀, Ọlọ́run ń bójú tó wọn. Ìdí nìyẹn tí Ọlọ́run fi sọ pé kí èèyàn máa “jọba lórí” àwọn ẹranko. Ọ̀rọ̀ tó sọ yìí tún lè túmọ̀ sí “ní àṣẹ lórí” (Yorùbá Bible). Torí náà, Jèhófà fún àwa èèyàn ní ojúṣe láti máa bójú tó àwọn ẹranko. (Sáàmù 8:6-8; Òwe 12:10) Jèhófà fẹ́ ká máa bójú tó ilẹ̀ ayé àti gbogbo ohun alààyè tó wà nínú rẹ̀.
Àwọn Ẹsẹ Tó Ṣáájú Àtèyí Tó Tẹ̀ Lé Jẹ́nẹ́sísì 1:26
Orí méjì àkọ́kọ́ nínú ìwé Jẹ́nẹ́sísì ṣàlàyé bí Ọlọ́run ṣe dá ọ̀run, ilẹ̀ ayé àtàwọn ohun ẹlẹ́mìí tó wà láyé. Àgbàyanu ni gbogbo ohun tí Jèhófà dá, àmọ́ àwa èèyàn ló ṣàrà ọ̀tọ̀ jù nínú gbogbo ohun tó dá sáyé. Nígbà tí Ọlọ́run dá ohun gbogbo tán, ó “rí gbogbo ohun tó ti ṣe, sì wò ó! ó dára gan-an.”—Jẹ́nẹ́sísì 1:31.
Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa ìtàn ìṣẹ̀dá tó wà nínú ìwé Jẹ́nẹ́sísì, wo fídíò kékeré yìí.
Èrò tí kò tọ́ nípa Jẹ́nẹ́sísì 1:26
Èrò tí kò tọ́: Àwọn ọkùnrin nìkan ló lè gbé àwọn ànímọ́ Ọlọ́run yọ.
Òtítọ́: Ọ̀rọ̀ náà “ọkùnrin” tó fara hàn nínú ọ̀pọ̀ ìtumọ̀ Bíbélì èdè Gẹ̀ẹ́sì lè mú kí òǹkàwé rò pé àwọn ọkùnrin nìkan ni ẹsẹ yìí ń tọ́ka sí. Àmọ́, ọkùnrin àti obìnrin ni ọ̀rọ̀ èdè Hébérù tá a lò nínú ẹsẹ yìí ń tọ́ka sí. Àtọkùnrin àtobìnrin ló lè gbé àwọn ànímọ́ Ọlọ́run yọ. Àwọn méjèèjì ló láǹfààní láti rí ojú rere Ọlọ́run, kí wọn sì jogún ìyè àìnípẹ̀kun.—Jòhánù 3:16.
Èrò tí kò tọ́: Irú ara tá a ní ni Ọlọ́run náà ní.
Òtítọ́: “Ọlọ́run jẹ́ Ẹ̀mí,” ìyẹn túmọ̀ sí pé kò ṣeé fojú rí. (Jòhánù 4:24) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì máa ń sọ pé Ọlọ́run ní ojú, ọwọ́, ọkàn àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, ńṣe ni Bíbélì máa ń fi àwọn ọ̀rọ̀ yìí kọ́ wa nípa Ọlọ́run lọ́nà tó máa gbà yé àwa èèyàn.—Ẹ́kísódù 15:6; 1 Pétérù 3:12.
Èrò tí kò tọ́: Jẹ́nẹ́sísì 1:26 sọ pé Jésù ni Ọlọ́run.
Òtítọ́: Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àjọṣe bàbá sọ́mọ wà láàárín Ọlọ́run àti Jésù, wọn kì í ṣe ẹnì kan náà. Jésù sọ pé Ọlọ́run tóbi ju òun lọ. (Jòhánù 14:28) Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i wo fídíò náà, Ṣé Jésù Kristi Ni Ọlọ́run? tàbí kó o ka àpilẹ̀kọ náà “Kí Nìdí Tí A Fi Pe Jésù Ní Ọmọ Ọlọ́run?”
Tó o bá fẹ́ mọ ohun tó wà nínú ìwé Jẹ́nẹ́sísì wo fídíò kékéré yìí.
a Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run. (Sáàmù 83:18) Wo àpilẹ̀kọ náà “Ta Ni Jèhófà?”