ÀLÀYÉ ÀWỌN ẸSẸ BÍBÉLÌ
Ìfihàn 21:4—“Ọlọ́run Yóò sì Nu Omijé Gbogbo Nù Kúrò ni Ojú Wọn”
“Ó máa nu gbogbo omijé kúrò ní ojú wọn, ikú ò ní sí mọ́, kò ní sí ọ̀fọ̀ tàbí ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn nǹkan àtijọ́ ti kọjá lọ.”—Ìfihàn 21:4, Ìtumọ̀ Ayé Tuntun.
“Ọlọ́run yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn; kì yóò sì sí ikú mọ́, tàbí ọ̀fọ̀, tàbí ẹkún, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ìrora mọ́: nítorí pé ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.”—Ìfihàn 21:4, Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní.
Ìtumọ̀ Ìfihàn 21:4
Ọlọ́run ṣèlérí pé kì í ṣe ìṣòro tó ń bá aráyé fínra nìkan lòun máa mú kúrò, òun á tún yanjú gbogbo ohun tó ń fa ìṣòro náà.
“Ó máa nu gbogbo omijé kúrò ní ojú wọn.” Ọ̀rọ̀ yìí jẹ́ kó túbọ̀ dá wa lójú pé ìlérí tí Jèhófà a gbẹnu wòlíì Àìsáyà sọ pé òun “máa nu omijé kúrò ní ojú gbogbo èèyàn” máa ṣẹ. (Àìsáyà 25:8; Ìfihàn 7:17) Ọ̀rọ̀ yìí tún jẹ́ ká rí i pé gbogbo àwọn tó ń sunkún torí pé èèyàn wọn kú tàbí torí wọ́n ní ẹ̀dùn ọkàn ni Ọlọ́run ń rí, ọ̀rọ̀ wọn sì jẹ ẹ́ lọ́kàn.
“Ikú ò ní sí mọ́.” Gbólóhùn náà tún lè túmọ̀ sí “ikú máa pòórá.” Ọlọ́run sọ pé òun máa mú ikú àti ìrora tí ikú ń fà kúrò. Bákan náà, ó máa jí àwọn tó ti kú dìde. (1 Kọ́ríńtì 15:21, 22) Paríparí ẹ̀, Ọlọ́run máa sọ ikú “di asán.”—1 Kọ́ríńtì 15:26.
“Kò ní sí ọ̀fọ̀ tàbí ẹkún tàbí ìrora mọ́.” Ti pé Ọlọ́run ṣèlérí pé kò ní sí ìrora mọ́, kò túmọ̀ sí pé a ò ní mọ nǹkan lára mọ́. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ìrora kan máa ń jẹ́ ká mọ̀ pé ara wa nílò àwọn nǹkan kan tàbí ewu wà nítòsí. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìlérí yìí jẹ́ ká mọ̀ pè kò ní sí ìrora tí ẹ̀ṣẹ̀ b àti àìpé ń fà mọ́, irú bí ẹ̀dùn ọkàn, ìdààmú, ara ríro àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.—Róòmù 8:21, 22.
“Àwọn nǹkan àtijọ́ ti kọjá lọ.” Ohun tó parí ẹsẹ Bíbélì yìí jẹ́ ká rí ìyípadà tó ń mọ́kàn yọ̀ tó máa bá àwa èèyàn. Ìwé ìwádìí kan sọ pé: “Ìgbé ayé ọ̀tún máa rọ́pò ìgbé ayé àtijọ́, níbi tí ikú, ọ̀fọ̀, ẹkún àti ìrora ti ń han àwa èèyàn léèmọ̀.” Tó bá dìgbà yẹn, àwa èèyàn máa gbádùn ayé wa títí láé lórí ilẹ̀ ayé bí Ọlọ́run ṣe fẹ́ kó rí gẹ́lẹ́.—Jẹ́nẹ́sísì 1:27, 28.
Àwọn Ẹsẹ Tó Ṣáájú Àtèyí Tó Tẹ̀ Lé Ìfihàn 21:4
Níbẹ̀rẹ̀ orí 21, àpọ́sítélì Jòhánù sọ ohun tó rí nínú ìran, ó ní: “Mo rí ọ̀run tuntun àti ayé tuntun.” (Ìfihàn 21:1) Ó lo ọ̀rọ̀ àfiwé láti ṣàlàyé ìyípadà tàwọn ẹsẹ Bíbélì míì náà sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀. (Àìsáyà 65:17; 66:22; 2 Pétérù 3:13) Ìjọba Ọlọ́run, ìyẹn “ọ̀run tuntun,” máa rọ́pò gbogbo ìjọba èèyàn, á sì ṣàkóso lórí “ayé tuntun,” ìyẹn àwùjọ àwọn èèyàn tó máa gbé láyé.—Àìsáyà 65:21-23.
Kí ló jẹ́ ká mọ̀ pé ayé ni ìran tí Jòhánù rí yìí ti máa ṣẹ? Lákọ̀ọ́kọ́, ọ̀rọ̀ tó bẹ̀rẹ̀ ìlérí Ọlọ́run yìí ni: “Àgọ́ Ọlọ́run wà pẹ̀lú aráyé.” (Ìfihàn 21:3) Ìyẹn jẹ́ ká rí i pé àwa èèyàn tó wà láyé ni Ọlọ́run ṣe ìlérí yìí fún kì í ṣe àwọn áńgẹ́lì tó wà lọ́run. Ìkejì, ìran náà sọ pé “ikú ò ní sí mọ́.” (Ìfihàn 21:4) Àwa tá a wà láyé la máa ń kú, kì í ṣe àwọn tó wà lọ́run. (Róòmù 5:14) Torí náà ó bọ́gbọ́n mu tá a bá gbà pé àwọn nǹkan tó máa ṣẹlẹ̀ láyé ni ìran yẹn sọ nípa ẹ̀.
Wo fídíò yìí kó o lè mọ ohun tó wà nínú ìwé Ìfihàn.
a Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run. (Sáàmù 83:18) Ka àpilẹ̀kọ náà “Ta ni Jèhófà?”
b Nínú Bíbélì ẹ̀ṣẹ̀ ni ohunkóhun tó ta ko ìlànà Ọlọ́run, ì báà jẹ́ ọ̀rọ̀, èrò tàbí ìṣe. (1 Jòhánù 3:4) Ka àpilẹ̀kọ náà “Kí Ni Ẹ̀ṣẹ̀?”