Orin 139
Kọ́ Wọn Kí Wọ́n Lè Dúró Gbọn-in
Wà á jáde:
-
Bá a ṣé ń kọ́ àgùntàn Jèhófà
À ń láyọ̀ pé wọ́n ń dàgbà.
À ń rọ́wọ́ rẹ̀ bó ṣe ń darí wọn
Wọ́n ń sòótọ́ di tara wọn.
(ÈGBÈ)
Jèhófà, gbọ́ àdúrà wa
Jọ̀ọ́ f’àbò rẹ bò wọ́n Baba.
Lórúkọ Jésù, a bẹ̀ ọ́: Kí wọ́n yege;
Kí gbogbo wọn lè dúró gbọn-in.
-
‘Joojúmọ́ là ń gbàdúrà fún wọn,
Kí ‘gbàgbọ́ wọn má ṣe yẹ̀.
À ń kọ́ wọn, a sì ń ṣìkẹ́ wọn;
Wọ́n ń lókun, Jáà ń bù kún wọn.
(ÈGBÈ)
Jèhófà, gbọ́ àdúrà wa
Jọ̀ọ́ f’àbò rẹ bò wọ́n Baba.
Lórúkọ Jésù, a bẹ̀ ọ́: Kí wọ́n yege;
Kí gbogbo wọn lè dúró gbọn-in.
-
Jọ̀ọ́ jẹ́ kí wọ́n máa gbẹ́kẹ̀ lé ọ,
Ìwọ àti Ọmọ rẹ.
Pẹ̀lú ‘fa-radà àtìgbọràn,
Kí wọ́n lè jogún ìyè.
(ÈGBÈ)
Jèhófà, gbọ́ àdúrà wa
Jọ̀ọ́ f’àbò rẹ bò wọ́n Baba.
Lórúkọ Jésù, a bẹ̀ ọ́: Kí wọ́n yege;
Kí gbogbo wọn lè dúró gbọn-in.
(Tún wo Lúùkù 6:48; Ìṣe 5:42; Fílí. 4:1.)