Orin 154
A Ó Máa Fara Dà Á Nìṣó
Wà á jáde:
-
Bí ‘ṣòro bá dé
Báwo la ṣe lè fara dàá?
Jésù náà jìyà
Àmọ́ ìrètí fúnun láyọ̀.
Ìlérí, ìdájọ́
Baba ló ńronú lé.
(ÈGBÈ)
Ó yẹ ká máa fara dàá.
Ká gbèjà ìgbàgbọ́.
Ìfẹ́ rẹ̀ sí wa dájú.
A ó máa fara dàá títí dé òpin.
-
Ó lè ti pẹ́ gan-an
Táa ti ńdojú kọ ìṣòro;
Báa tilẹ̀ ńsunkún,
À ńr’ọ́jọ́ ‘wájú aláyọ̀.
Táó máa gbé láìséwu,
Aó máa fara dà á lọ.
(Ègbè)
Ó yẹ ká máa fara dàá.
Ká gbèjà ìgbàgbọ́.
Ìfẹ́ rẹ̀ sí wa dájú.
A ó máa fara dàá títí dé òpin.
-
A kò ní yẹsẹ̀
Aò bẹ̀rù, kò síyè méjì.
Aó máa fòótọ́ sìn
Títí di ọjọ́ Jèhófà.
Ká máa fara dàá lọ.
Ọjọ́ náà ti dé tán.
(Ègbè)
Ó yẹ ká máa fara dàá.
Ká gbèjà ìgbàgbọ́.
Ìfẹ́ rẹ̀ sí wa dájú.
A ó máa fara dàá títí dé òpin.
(Tún wo Ìṣe 20:19, 20; Ják. 1:12; 1 Pét. 4:12-14.)