ORIN 72
À Ń Kéde Òtítọ́ Ìjọba Náà
-
1. Ìgbà kan wà tí a kò mọ
Ọ̀nà tó yẹ kí a máa rìn.
Jèhófà tan ìmọ́lẹ̀
Òótọ́ Ìjọba rẹ̀ fún wa.
A wá ríi pé Jèhófà fẹ́
Ká kọ́wọ́ ti Ìjọba rẹ̀.
Ká kéde rẹ̀ fáráyé,
Ká sì tún gbórúkọ mímọ́ rẹ̀ ga.
À ńwàásù fún gbogbo èèyàn
Nílé délé, lójú ọ̀nà.
À ńkọ́ wọn ní ẹ̀kọ́ òótọ́
Tó ńsọni di òmìnira.
À ńsapá ní gbogbo ayé
Káwọn tó ńsin Jáà lè pọ̀ síi.
Ká máa ṣiṣẹ́ níṣọ̀kan
Títí Jèhófà yóò sọ pé ó tó.
(Tún wo Jóṣ. 9:9; Àìsá. 24:15; Jòh. 8:12, 32.)