ORIN 58
À Ń Wá Àwọn Ọ̀rẹ́ Àlàáfíà
-
1. Jésù pàṣẹ pé: ‘Ẹ wàásù òótọ́.’
Lójò lẹ́ẹ̀rùn ló máa ń wàásù
látòwúrọ̀, tílẹ̀ fi ṣú.
Ó ń pe àwọn èèyàn níbi gbogbo.
Ó nífẹ̀ẹ́ wọn, ó sì ń kọ́ wọn
lọ́rọ̀ Ọlọ́run.
Nílé délé, lójú ọ̀nà,
À ń wàásù fún gbogbo èèyàn
Pé ìṣòro aráyé máa tó dópin.
(ÈGBÈ)
Kárí ayé,
À ń wá àwọn ọ̀rẹ́ àlàáfíà.
A sì tún ń wá
Àwọn èèyàn tó fẹ́ ìgbàlà.
Gbogbo ‘pá wa
Ni a máa sà.
-
2. Ká tẹra mọ́ ‘wàásù, àkókò ń lọ,
Ká sì fi kún ìsapá wa
kọ́pọ̀ èèyàn lè rígbàlà.
Ìfẹ́ ló ń mú ká pa dà wá wọn lọ.
Ká lè ràn wọ́n lọ́wọ́, ká sì
tún ayé wọn ṣe.
Nílùú délùú, níbi gbogbo,
Tá a bá rẹ́ni tó gbọ́rọ̀ wa,
Inú wa máa ń dùn, a sì máa ń báṣẹ́ lọ.
(ÈGBÈ)
Kárí ayé,
À ń wá àwọn ọ̀rẹ́ àlàáfíà.
A sì tún ń wá
Àwọn èèyàn tó fẹ́ ìgbàlà.
Gbogbo ‘pá wa
Ni a máa sà.
(Tún wo Àìsá. 52:7; Mát. 28:19, 20; Lúùkù 8:1; Róòmù 10:10.)