ORIN 53
À Ń Múra Láti Lọ Wàásù
-
1. Ilẹ̀ mọ́.
A ti ń múra
Láti jáde lọ wàásù.
Àmọ́ òjò ṣú,
Ó wá bẹ̀rẹ̀ sí í rọ̀.
Ó lè dà bíi ká dúró sílé,
ká máa sùn.
(ÈGBÈ))
Èrò tó dáa ló yẹ kí a ní,
Ká sì múra sílẹ̀.
Ká bẹ Jáà pé kó ràn wá lọ́wọ́;
Yóò gbé wa ró.
Àwọn áńgẹ́lì wà lẹ́yìn wa,
Jésù ló ń darí wọn.
Pẹ̀lú ọ̀rẹ́ tòótọ́ lẹ́gbẹ̀ẹ́ wa,
A ó ṣe é yọrí.
-
2. A ó láyọ̀
Tí a bá ń fi
Ìmọ̀ràn wọ̀nyí sọ́kàn.
Jèhófà sì ń rí
Gbogbo bá a ṣe ńsapá.
A mọ̀ pé kò ní gbàgbé ìfẹ́
tá à ń fi hàn.
(ÈGBÈ))
Èrò tó dáa ló yẹ kí a ní,
Ká sì múra sílẹ̀.
Ká bẹ Jáà pé kó ràn wá lọ́wọ́;
Yóò gbé wa ró.
Àwọn áńgẹ́lì wà lẹ́yìn wa,
Jésù ló ń darí wọn.
Pẹ̀lú ọ̀rẹ́ tòótọ́ lẹ́gbẹ̀ẹ́ wa,
A ó ṣe é yọrí.
(Tún wo Oníw. 11:4; Mát. 10:5, 7; Lúùkù 10:1; Títù 2:14.)