ORIN 37
Máa Sin Jèhófà Tọkàntọkàn
-
1. Jèhófà Ọba Aláṣẹ,
Ìwọ ni mo fẹ́ máa gbọ́ràn sí.
Mo nífẹ̀ẹ́ rẹ tọkàntọkàn.
Ìwọ ni màá fi ayé mi sìn.
Mo fẹ́ràn ìránnilétí rẹ,
Mo sì ń pàwọn àṣẹ rẹ mọ́.
(ÈGBÈ)
Jèhófà, mo nífẹ̀ẹ́ rẹ gan-an.
Màá fi gbogbo ọkàn mi sìn ọ́.
-
2. Gbogbo iṣẹ́ rẹ ń gbé ọ ga;
Láyé lọ́run, wọ́n ń fògo rẹ hàn.
Èmi náà fẹ́ máa fokun mi
Kéde orúkọ rẹ fáráyé.
Màá fi gbogbo ayé mi sìn ọ́,
Màá sì jẹ́ olóòótọ́ sí ọ.
(ÈGBÈ)
Jèhófà, mo nífẹ̀ẹ́ rẹ gan-an.
Màá fi gbogbo ọkàn mi sìn ọ́.
(Tún wo Diu. 6:15; Sm. 40:8; 113:1-3; Oníw. 5:4; Jòh. 4:34.)