ORIN 128
Bí A Ṣe Lè Fara Dà Á Dópin
-
1. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fi hàn pé
A nílò ‘faradà.
Ojúlówó ni ìfẹ́ wa,
Ẹ̀kọ́ wa jinlẹ̀ púpọ̀.
Àwọn ìdánwò ‘gbàgbọ́ wa,
Ń mú ká lè fẹsẹ̀ múlẹ̀.
Kígbàgbọ́ wa fẹsẹ̀ múlẹ̀,
Ọjọ́ Jèhófà dé tán.
-
2. Ìfẹ́ tá a ní sí Jèhófà
Kò gbọ́dọ̀ tutù láé.
Bá a ti ń dojú kọ àdánwò,
Má ṣe bẹ̀rù, má fòyà.
Ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ nínú Jáà,
Yóò mú kó o lè fara dà á.
Ìgbàgbọ́ rẹ máa lágbára
Tó o bá lè ní ‘faradà.
-
3. Mọ̀ dájú pé àwọn tó bá
Fara dà á dé òpin
Ni yóò la ètò búburú
Ayé Sátánì kọjá
Sínú ayé tuntun tó ń bọ̀,
Orúkọ wọn yóò tàn yòò.
Máa bá a lọ ní fífara dà á
Kó o lè gba adé ògo.
(Tún wo Héb. 6:19; Jém. 1:4; 2 Pét. 3:12; Ìfi. 2:4.)