Àwọn Ìbùkún Kíkọ́ Èdè Míì
Wà á jáde:
1. O lè ti máa ronú pé,
‘Ṣé mo lè lọ ṣá?’
Gbàdúrà, sì ṣàṣàrò,
‘Jèhófà, kínni kí n ṣe?’
Wáyè kó sí ṣàṣàrò,
Wàá ṣè ìpinnu tó tọ́.
Tóo bá ti lè ré kọjá,
Wàá láyọ̀ ‘pinnu tó o ṣe!
(ÈGBÈ)
O ń láti ré kọjá.
Má ṣe ṣàníyàn kankan.
Torí tó bá ti ré kọjá,
Aó bùkún ‘pinnu tó o ṣe.
Ré kọjá.
Ré kọjá sí Makedóníà rẹ!
2. Iṣẹ́ ìwàásù dùn mọ́ni,
Pẹ̀láṣeyọrí tó pọ̀.
Yóò mú ‘dùnnú wá fún ọ
Pájèjì tẹ́wọ́ gbà ẹ̀.
Wàá túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà
Lójoojúmọ́ ayé.
Yóò wà lárọ̀ọ̀wọ́tó rẹ
Láti darí rẹ sí ọ̀nà tó tọ́.
(ÈGBÈ)
O ń láti ré kọjá
Má ṣe ṣàníyàn kankan.
Torí tó bá ti ré kọjá
Ìṣúra á jẹ́ tìrẹ.
Bóo bá ń ṣiyèméjì
‘Ṣé mo pinnu tó dáa?’
(ÈGBÈ)
O ní láti ré kọjá.
Aó bù kún ‘pinnu tóo ṣe.
Ré kọjá.
Ré kọjá.
O ní láti ré kọjá sí Makedóníà rẹ!