Gbàdúrà sí Jèhófà
Wà á jáde:
1. Ó máa ń súni tíṣòro bá dé,
Ìṣòro yẹn sì lè wá múni soríkọ́.
Àwọn míì tiẹ̀ tún lè máa tọ́jà ẹ;
Gbàdúrà sí Jèhófà,
Gbàdúrà sí i.
(ÈGBÈ)
Ṣohun tó tọ́, fara dà á,
Sì fọkàn tán Jèhófà.
Ṣe sùúrù; a óò ṣẹ́gun
Tá a bá gbàdúrà sí i.
Tó bá ti fẹ́ sú wa,
Ó ṣe tán láti ṣèrànwọ́.
Á tọ́ wa sọ́nà, má mikàn.
Ṣáà máa gbàdúrà sí i;
Mú kínú Jáà dùn.
Jẹ́ kó darí ẹ.
2. Ojoojúmọ́ nìṣòro ń yọjú,
Ọ̀pọ̀ nǹkan wà ńlẹ̀ tó o sì tún fẹ́ fowó ṣe.
Síbẹ̀, a máa láyọ̀ tá a bá ń ṣoore.
Ká máa múnú àwọn míì dùn;
Múnú wọn dùn.
(ÈGBÈ)
Nígbàgbọ́, má bẹ̀rù,
Sì fọkàn tán Jèhófà.
A máa ṣàṣeyọrí
Tá a bá gbàdúrà sí i.
Bó rẹ̀ wá, a óò lókun.
Ó ṣe tán láti ṣèrànwọ́,
Ó pẹ́ tó ti ń tọ́ wa sọ́nà.
Ṣáà máa gbàdúrà sí i;
Mú kínú Jáà dùn.
Jẹ́ kó darí ẹ.
(ÈGBÈ)
Sì fọkàn tán Jèhófà.
A máa ṣàṣeyọrí
Tá a bá gbàdúrà sí i.
Bó rẹ̀ wá, a óò lókun.
Ó ṣe tán láti ṣèrànwọ́,
Ó pẹ́ tó ti ń tọ́ wa sọ́nà.
Ṣáà máa gbàdúrà sí i;
Mú kínú Jáà dùn.
Dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹ̀.