Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹni Tọ́kàn Mi Fẹ́

Ẹni Tọ́kàn Mi Fẹ́

Wà á jáde:

  1. 1. Ìwọ ni

    Ẹni tọ́kàn mi yàn.

    Ìfẹ́ mi;

    Ẹnì kejì mi.

    Ìwà rere tó o ní

    Máa ń múnú mi dùn gan-an.

    Ò ń tọ́jú mi,

    O sì tún ń ṣìkẹ́ mi.

    O kú àdúrótì;

    Mo nífẹ̀ẹ́ rẹ dọ́kàn.

    Àdúrà mi ni pé

    Ká bára wa kalẹ́.

    (ÈGBÈ)

    Tá a bá ṣera wa lọ́kan,

    Tá a sì fọwọ́ sowọ́ pọ̀,

    Jèhófà máa jẹ́ kí ìfẹ́ wa dọ̀tun

    Lójoojúmọ́.

  2. 2. Ìwọ lọkàn mi fẹ́.

    Ìwọ lò ń gbọ́ tèmi.

    Mo nífẹ̀ẹ́ rẹ,

    Mo sì mọ̀ pó o nífẹ̀ẹ́ mi.

    Bá a ṣe ń sin Jèhófà

    Nìfẹ́ wa ń lágbára.

    Kò sóhun táá yà wá

    Lágbára Jèhófà.

    (ÈGBÈ)

    Tá a bá ṣera wa lọ́kan,

    Tá a sì fọwọ́ sowọ́ pọ̀,

    Jèhófà máa jẹ́ kí ìfẹ́ wa dọ̀tun

    Lójoojúmọ́.

    Tá a bá ṣera wa lọ́kan,

    Tá a sì fọwọ́ sowọ́ pọ̀,

    Jèhófà máa jẹ́ kí ìfẹ́ wa dọ̀tun

    Lójoojúmọ́.

    Mo nífẹ̀ẹ́ rẹ

    Dọ́kàn.