Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

GEORGIY PORCHULYAN | ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ

“Jèhófà Fìfẹ́ Hàn Sí Mi Jálẹ̀ Ìgbésí Ayé Mi”

“Jèhófà Fìfẹ́ Hàn Sí Mi Jálẹ̀ Ìgbésí Ayé Mi”

Ọmọ ọdún mẹ́tàlélógún (23) ni mí nígbà tí wọ́n rán mi lọ sí àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ ní Magadan, lórílẹ̀-èdè Siberia. Kò ju ọdún kan lọ tí mo ṣèrìbọmi tí ohun tí mo sọ yìí ṣẹlẹ̀. Mo rántí pé ìgbà àkọ́kọ́ tí mo máa sọ ohun tí mo gbà gbọ́ fáwọn tá a jọ wà lẹ́wọ̀n, díẹ̀ ló kù kó dìjà torí kò tíì pẹ́ tí mo kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, mo sì máa ń sọ̀rọ̀ láìronú nígbà míì.

 Àmọ́ kí ló mú kí èmi tí mo jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ Kọ́múníìsì tẹ́lẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í dara pọ̀ mọ́ àwọn ẹlẹ́ṣìn tí ìjọba kà sí ọ̀tá? Báwo sì ni ìfẹ́ tí Jèhófà fi hàn sí mi àti ìdálẹ́kọ̀ọ́ tí mo gbà látọ̀dọ̀ ẹ̀ ṣe ràn mí lọ́wọ́ láti tún ìwà mi ṣe láwọn ọdún tí mo wà ní àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ àti nígbà tí mo wà nígbèkùn?

Ó Wù Mí Kí Ìdájọ́ Òdodo Wà, Kọ́kàn Mi sì Balẹ̀

 Ọdún 1930 ni wọ́n bí mi ní abúlé kékeré kan tó ń jẹ́ Tabani tó wà ní apá àríwá orílẹ̀-èdè Maldova. Àgbẹ̀ làwọn òbí wa, wọn ò sì fi bẹ́ẹ̀ ní lọ́wọ́. Síbẹ̀, wọ́n ṣiṣẹ́ kára láti tọ́jú àwa ọmọ wọn mẹ́fẹ̀ẹ̀fà. Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ti ìlú Rọ́ṣíà ni màmá mi ń lọ, bàbá mi sì jẹ́ Kátólíìkì. Mo rántí pé àwọn méjèèjì sábà máa ń bára wọn jiyàn gan-an nípa ìwà táwọn àlùfáà ń hù.

 Nígbà tí mo jáde nílé ìwé lọ́mọ ọdún méjìdínlógún (18), mo dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ àwọn ọ̀dọ́ kan tí wọ́n ń pè ní Komsomol tó ń ṣagbátẹrù ìjọba Kọ́múníìsì. Ìdí tí wọ́n fi dá ẹgbẹ́ náà sílẹ̀ ni láti dá àwọn ọ̀dọ́ lẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n lè dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ náà, kò sì pẹ́ tí mo fi di akọ̀wé ẹgbẹ́ yìí ládùúgbò mi. Ohun tó jẹ́ kí ẹgbẹ́ náà wù mí ni bí wọ́n ṣe sọ pé gbogbo wa máa jẹ́ ọmọ ìyá, ìdájọ́ òdodo máa wà, wọ́n á sì máa ṣe nǹkan ní ìlànà orí-ò-jorí. Àmọ́ nígbà tí mo rí ìwà ìbàjẹ́ àti ìrẹ́jẹ táwọn èèyàn ń hù, ṣe ni gbogbo nǹkan tojú sú mi.

 Nígbà tó yá, ìjọ́ba Soviet Union a bẹ̀rẹ̀ sí ti àwọn ṣọ́ọ̀ṣì, wọ́n sì fòfin de àwọn ẹ̀sìn kan. Torí pé ọmọ ẹgbẹ́ Komsomol ni mí, ó di dandan kí n fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àṣẹ yẹn. Mo rántí pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan wà ní abúlé wa. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé olóòótọ́ ni wọ́n, wọn kì í sì í fa wàhálà, mo kà wọ́n sí agbawèrèmẹ́sìn. Kẹ́ ẹ sì máa wò ó, mi ò mọ̀ pé ọ̀kan lára wọn ló máa dáhùn àwọn ìbéèrè tó wà lọ́kàn mi.

 Ẹ̀gbọ́n bàbá mi kan wà tó ń gbé lábúlé wa, Dimitriy lorúkọ wọn, Ẹlẹ́rìí Jèhófà sì ni wọ́n. Lọ́jọ́ kan ní ọdún 1952, wọ́n bi mí pé, “Georgiy, kí lo fẹ́ fi ayé ẹ ṣe?” Ìbéèrè tí wọ́n bi mí yẹn jẹ́ kí n rí i pé ọ̀rọ̀ mi jẹ wọ́n lógún gan-an. Ká sòótọ́, ọ̀pọ̀ ìbéèrè ló wà lọ́kàn mi tí mi ò tíì rí ìdáhùn sí. Bí àpẹẹrẹ, mo máa ń ronú pé, ‘Tí Ọlọ́run bá wà lóòótọ́, kí nìdí tó fi fàyè gba kí ìyà máa jẹ àwa èèyàn báyìí?’ Odindi ọjọ́ mẹ́jọ tó tẹ̀ lé e ni ẹ̀gbọ́n bàbá mi fi ń fi Bíbélì dáhùn àwọn ìbéèrè mi, kódà àwọn ìgbà kan wà tá a sọ̀rọ̀ di aago mẹ́ta òru!

Àwọn alẹ́ ọjọ́ kan wà tí Georgiy àti Dimitriy jọ sọ̀rọ̀ nipa Bíbélì títí di òru

 Lẹ́yìn ìjíròrò wa, mo pinnu láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Bí mo ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́, mo wá rí i pé Baba wa ọ̀run nífẹ̀ẹ́ mi gan an. (Sáàmù 27:10) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìmọ̀ Bíbélì tí mo ní ò pọ̀, mo nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ìfẹ́ yìí sì jẹ́ kí n gbé ìgbésẹ̀ tó ye. Mo fi ẹgbẹ́ Kọ́múníìsì tí mo wà sílẹ̀ láìka bí alága ẹgbẹ́ náà ṣe ń halẹ̀ mọ́ mi. Nígbà tó sì di September 1952, ìyẹn oṣù mẹ́rin lẹ́yìn tí mo bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, mo ya ara mi sí mímọ́, mo sì ṣèrìbọmi.

Mo Kojú Àdánwò

 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìjọba ti fòfin de iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà yẹn, ìfẹ́ tí mo ní fún Jèhófà mú kí n yọ̀ǹda ara mi láti máa pín àwọn ìtẹ̀jáde wa fáwọn ará tó ń gbé láwọn abúlé míì. Ohun tí mo ṣe yẹn léwu gan-an torí táwọn ará abúlé tí mò ń lọ bá rí àjèjì, wọ́n lè sọ fáwọn aláṣẹ. Kódà, àwọn ará kan ò fọkàn tán mi, ṣe lẹ̀rù ń bà wọ́n pé ó ṣeé ṣe kí n jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọlọ́pàá ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ tó ń díbọ́n bí Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àmọ́ kò pẹ́ tí wọ́n fi mọ̀ pé mi ò kíí ṣe ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́. Lẹ́yìn oṣù méjì péré tí mo ṣèrìbọmi àwọn ọlọ́pàá mú mi, wọ́n sì fẹ̀sùn kàn mí pé mò ń pín ìwé tí wọ́n ti fòfin dè.

 Fún nǹkan bí ọdún kan tí wọ́n fi tì mí mọ́lé láìtíì gbọ́ ẹjọ́ mi, ṣe ni àwọn ọlọ́pàá ń fọ̀rọ̀ wá mi lẹ́nu wò tí wọ́n sì ń ṣe àwọn nǹkan tá mú kí n sẹ́ ìgbàgbọ́ mi. Àmọ́, ìgbàgbọ́ mi ò yingin torí pé mo nífẹ̀ẹ́ Jèhófà gan-an. Nígbà tó yá, wọ́n gbé ọ̀rọ̀ mi lọ sílé ẹjọ́ kan ní ìlú Odessa lórílẹ̀-èdè Ukraine, wọ́n sì ní káwọn òbí mi, ẹ̀gbọ́n mi àtàwọn àbúrò mi náà wá sílé ẹjọ́, bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọn kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà yẹn.

 Níbi ìgbẹ́jọ́ náà, ṣe ni wọ́n fi mí hàn bí ẹni tí wọ́n tàn wọnú ẹgbẹ́ burúkú kan. Ohun táwọn aláṣẹ fẹ́ ni pé káwọn òbí mi, ẹ̀gbọ́n mi àtàwọn àbúrò mi rí mi bí ẹni tí ò mọ ohun tó ń ṣe. Ẹ̀rù ba àwọn òbí mi gan-an, ṣe ni wọ́n bú sẹ́kún, wọ́n sì ní kí n má ṣe ajẹ́rìí mọ́. Àmọ́ ẹ̀rù ò bà mí, mo wá sọ fún màámi pé: “Ẹ fọkàn balẹ̀, mo mọ ohun tí mò ń ṣe. Mo ti rí ohun tí mò ń fi gbogbo ìgbésí ayé mi wá, mi ò sì lè jẹ́ kó bọ́ mọ́ mi lọ́wọ́.” (Òwe 23:23) Ìmọ̀ tí mo ní nípa Bíbélì ò tó nǹkan, síbẹ̀ ohun tí mo ti kọ́ nípa Jèhófà ti jẹ́ kí n pinnu pé mi ò ní fi í sílẹ̀ láé. Nǹkan bí ọdún mẹ́fà lẹ́yìn náà, àwọn òbí mi bẹ̀rẹ̀ sí í mọyì ẹ̀kọ́ òtítọ́ tí mò ń kọ́, àwọn náà sì di Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

Níṣojú àwọn òbí Georgiy, ilé ẹjọ́ fẹ̀sùn kàn án pé ó ti dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ burúkú kan

 Wọ́n rán mi lọ ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15) pẹ̀lú iṣẹ́ àṣekára, wọ́n sì fi ọkọ̀ ojú irin gbé mi lọ sí àárín gbùngbùn ibi táwọn tó ń ṣiṣẹ́ àṣekára pọ̀ sí, ní Kolyma lórílẹ̀-èdè Siberia. Àwọn ẹ̀ṣọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n fìyà jẹ wá gan-an, wọ́n lù wá, wọn ò sì fún wa lóúnjẹ. Kódà, mo bẹ̀rẹ̀ sí í ronú pé ibẹ̀ ni màá kú sí.

Jèhófà Bójú Tó Mi, Ó sì Dá Mi Lẹ́kọ̀ọ́

 Kò pẹ́ tí mo débẹ̀ làwọn kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n (34) tí mo bá lẹ́wọ̀n fọgbọ́n bi mí pé: “Ṣé Jónádábù kankan wà nínú àwùjọ ẹ?” Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni mo mọ̀ pé arákùnrin mi ni wọ́n torí àwọn nìkan ló lè sọ irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀. Àwọn arákùnrin tó nírìírí yìí kọ́ mi bí mo ṣe lè fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò, wọ́n sì tún ràn mí lọ́wọ́ kí n lè ní ìfòyemọ̀ àtàwọn ànímọ́ míì tó yẹ Kristẹni.

 Iṣẹ́ ẹni tó ń tún ẹ̀rọ ṣe ni mò ń ṣe ní àgọ́ tá a wà. Lọ́jọ́ kan, ọ̀kan lára àwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́ tó ń jẹ́ Matphey fọ́nnu pé òun lè sọ orúkọ àádọ́ta (50) àwọn ẹni mímọ́ látorí. Nígbà tí mo sọ ohun tí kò dáa nípa àwọn tó pè ní ẹni mímọ́ yẹn, ṣe ló fẹ́ gbá mi lẹ́ṣẹ̀ẹ́, ni mo bá sá lọ. Nígbà tí mo rí i pé àwọn ará ń rẹ́rìn-ín, inú bí mi, mo bá bi wọ́n pé: “Kí ló ń pa yín lẹ́rìn-ín? Ṣebí mo fẹ́ wàásù ni!” Wọ́n wá rán mi létí pé ohun tó ṣe pàtàkì jù ni bá a ṣe lè wàásù lọ́nà tá ò fi ní múnú bí àwọn èèyàn. (1 Pétérù 3:15) Matphey máa ń tako àwọn olóṣèlú, àmọ́ orí ẹ̀ wú nígbà tó rí bí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófa ṣe ń bọ̀wọ̀ fáwọn ẹ̀ṣọ́ àtàwọn aláṣẹ. Nígbà tó yá, ó bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Mo ṣì rántí alẹ́ ọjọ́ tó ṣèrìbọmi ní bòókẹ́lẹ́ nínú àgbá kan tí omu tútù wà nínú ẹ̀.

 Kò pẹ́ tá a dé àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ ni wọ́n ránṣẹ́ pe èmi àti àwọn arákùnrin méjì kan pé ká wá síbi ìdálẹ́kọ̀ọ́ kan tó dá lórí ọ̀rọ̀ òṣèlú. A ò kọ́kọ́ gbà láti lọ, torí a gbà pé tá a bá lọ, a ti dá sọ́rọ̀ òṣèlú nìyẹn. (Jòhánù 17:16) Torí náà, wọ́n fi wá sínú àhámọ́ tó ṣókùnkùn fún ọ̀sẹ̀ méjì. Nígbà tí wọ́n dá wa sílẹ̀, àwọn arákùnrin kan ṣàlàyé fún wa pé, ti pé a lọ síbi ìdálẹ́kọ̀ọ́ yẹn kò túmọ̀ sí pé a ti dá sọ́rọ̀ òṣèlú. Kàkà bẹ́ẹ̀, àǹfààní nìyẹn máa jẹ́ fún wa láti wàásù. Àwọn arákùnrin yìí ràn wá lọ́wọ́ láti máa ronú lórí àwọn ìlànà Bíbélì ká tó ṣèpinnu.

 Bí wọ́n ṣe fi sùúrù dá mi lẹ́kọ̀ọ́ jẹ́ kó túbọ̀ dá mi lójú pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ mi gan-an. Mo rántí ìgbà kan tí wọ́n ní kí ẹlẹ́wọ̀n kan tó jẹ́ àlùfáà ṣọ́ọ́ṣì máa bójú tó àkáǹtì. Nígbàkigbà tó bá rí mi lásìkò oúnjẹ, á kí mi pé, “Báwo ni o, ọmọ Èṣù!” Ni ẹlẹ́wọ̀n kan bá gbà mí nímọ̀ràn pé kémi náà máa dá a lóhùn pé,“Dáadáa ni o, Bàbá mi!” Ó ṣeni láàánú pé mo gba ìmọ̀ràn ẹ̀, ìyẹn sì mú kí wọ́n lù mí bí ẹni máa kú. Nígbà táwọn ará gbọ́ ohun tó ṣẹlẹ̀ sí mi yẹn, wọ́n jẹ́ kí n rí i pé ohun tí mo ṣe yẹn kù díẹ̀ káàtó. (Òwe 29:11) Torí náà, mo pa dà lọ bẹ àlùfáà yẹn.

 Kí wọ́n tó rán mi lọ sí àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́, a sábà máa ń ṣe àwọn ìpàdé wa láàárọ̀ kùtù tàbí lálẹ́ káwọn èèyàn má bàa rí wa. Àmọ́ nígbà tá a dé àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ kò síbi tá a lè fara pa mọ́ sí. Torí náà, ojoojúmọ́ la máa ń kóra jọ níbi táwọn ẹ̀ṣọ́ ti lè rí wa láti jíròrò àwọn ẹsẹ Bíbélì tá a ti kọ sínú ìwé kékeré tó wà lọ́wọ́ wa. Ìdí tá a fi ń ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé á jẹ́ ká lè há àwọn ẹsẹ Bíbélì kan sórí ká sì lè máa rántí wọn nígbà gbogbo. Tí ẹ̀ṣọ́ kan bá wá síbi tá a wà, ṣe la máa ń sáré gbé àwọn ìwé wa mì.

Àwọn ará ń ka Bíbélì níbi táwọn ẹ̀ṣọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n ti lè rí wọn torí wọn ò ríbi fara pa mọ́ sí

Jèhófà Ò Fi Mí Sílẹ̀ Bí Mo Tiẹ̀ Wà Nígbèkùn

Níbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1960, nígbà tí wọ́n dá Georgiy sílẹ̀ lágọ̀ọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́

 Lẹ́yìn tí wọ́n dá mi sílẹ̀ ní àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ lọ́dún 1959, wọ́n rán mi lọ sígbèkùn ní Karaganda lórílẹ̀-èdè Kazakhstan. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn aláṣẹ ṣì ń ṣọ́ mi lọ́wọ́ lẹ́sẹ̀, mo tọrọ àyè ogún (20) ọjọ́ láti lọ ṣègbéyàwó. Mo wá rìnrìn àjò lọ sí agbègbè Tomsk lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà torí mo mọ arábìnrin kan tó ń jẹ́ Maria níbẹ̀. Èèyàn dáadáa ni, ó sì nífẹ̀ẹ́ Jèhófà gan-an. Ohun kan ni pé mi ò kíí fọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ, torí náà, mo sọ fún un pé: “Maria, mo fẹ́ ká ṣègbéyàwó torí mi ò ráyè ìfẹ́sọ́nà.” Ó gbà, a sì ṣègbéyàwó ráńpẹ́. Maria mọrírì bí mo ṣe ti fara da ọ̀pọ̀ àdánwò, ó sì wù ú láti ràn mí lọ́wọ́ láti máa sin Jèhófà nìṣó.—Òwe 19:14.

 Láwọn ọdún 1960, a ò lè wàásù láti ilé délé, àmọ́ a máa ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti wàásù lọ́nà àìjẹ́ bí àṣà. Yàtọ̀ síyẹn, tá a bá lọ kí àwọn èèyàn tàbí tá a wà lásìkò ìsinmi, a máa ń fi àkókò yẹn wàásù fáwọn èèyàn. A tún máa ń lo onírúurú àwọn ọ̀nà míì láti bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀. Bí àpẹẹrẹ, a máa ń lọ sí àwọn ilé tí wọ́n fẹ́ tà, àá ṣe bíi pé a fẹ́ ra ilé náà, àá wá lo àǹfààní yẹn láti bá onílé sọ̀rọ̀ nípa Bíbélì. Èmi àti ìyàwó mi sì ti tipa bẹ́ẹ̀ ran àwọn mẹ́fà lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, wọ́n sì ti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

 Nígbà míì, a máa ń wàásù lásìkò ìbò. Bí àpẹẹrẹ, lọ́jọ́ kan táwọn ọlọ́pàá ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ wá síbi tí èmi àtàwọn arákùnrin kan ti ń ṣiṣẹ́. Wọ́n wá bi wá níṣojú àwọn bí ẹgbẹ̀rún kan tá a jọ ń ṣiṣẹ́ pé, kí nìdí táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í fi lọ́wọ́ sí òṣèlú. Ọ̀gá wa àtàwọn òṣìṣẹ́ míì wá gbèjà wa, wón sọ fún àwọn ọlọ́pàá yẹn pé olóòótọ́ ni wá, a kì í sì fiṣẹ́ ṣeré. Ohun tí wọ́n ṣe yìí fún wa nígboyà gan-an, ó sì jẹ́ ká lè lo àwọn ẹsẹ Bíbélì tá a mọ̀ lórí láti ṣàlàyé ohun tá a gbà gbọ́. Àlàyé tá a ṣe yẹn wú mẹ́rin lára àwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́ lórí, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ bíbélì. Kódà, kò pé ọdún kan lẹ́yìn náà táwọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin fi ṣèrìbọmi.

 Níbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1970, ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn di Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Kazakhstan. Torí náà, a ronú pé á dáa ká ṣètò àpéjọ àkọ́kọ́ lórílẹ̀-èdè náà. Àmọ́ báwo la ṣe máa ṣe é táwọn aláṣẹ ò ní mọ̀? Ó lẹ́nì kan tó fẹ́ ṣe ìgbéyàwó ní abúlé kékeré kan tí ò jìnnà sí ìlú Almaty. La bá pinnu pé ká kúkú ṣe àpéjọ yẹn lọ́jọ́ kan náà pẹ̀lú ìgbéyàwó náà. Àbí ẹ ò rí nǹkan, ìgbéyàwó àti àpéjọ la ṣe lọ́jọ́ kan náà, àwọn tó lé ní ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (300) ló sì wà níbi ètò tá a ṣe yìí. Ìyàwó mi àtàwọn arábìnrin míì ṣiṣẹ́ kára gan-an láti se oúnjẹ aládùn kí wọ́n sì ṣe ibi tá a lò lọ́ṣọ̀ọ́. Àwọn tó wá síbẹ̀ mọyì àsọyé Bíbélì tí àwọn olùbánisọ̀rọ̀ tó tó méjìlá sọ. Ọjọ́ yẹn nìgbà àkọ́kọ́ láyé mi tí mo máa sọ àsọyé níwájú ọ̀pọ̀ èèyàn.

Ọlọ́run Dúró Tì Wá Nínú Gbogbo Àdánwò Wa

Georgiy, Maria ìyàwó ẹ̀ àti Lyudmila ọmọbìnrin wọn

 Alátìlẹyìn gidi ni Maria ìyàwó mi ọ̀wọ́n jẹ́ fún mi ní gbogbo ọjọ́ ìgbésí ayé ẹ̀. Oníwà pẹ̀lẹ́ ni, ó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, gbogbo ìgbà ló sì máa ń fi ire Ìjọba Ọlọ́run sípò àkọ́kọ́. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìyàwó mi kì í sábà ṣàìsàn, ọ̀sán kan òru kan ló ṣàdédé ní àrùn tó ń sọ egungun di hẹ́gẹhẹ̀gẹ, ló bá di pé kò lè dìde mọ́ fún nǹkan bí ọdún mẹ́rìndínlógún (16). Èmi àti Lyudmila ọmọbìnrin wa la jọ tọ́jú ẹ̀ títí tó fi kú lọ́dún 2014.

 Ó dùn mí gan-an pé kò sóhun tí mo lè ṣe bí mo ṣe ń wo ìyàwó mi tó ń jẹ̀rora lórí ìdùbúlẹ̀ àìsàn. Àmọ́, ojoojúmọ́ la máa ń ka Bíbélì àtàwọn ìtẹ̀jáde tó ń gbéni ró títí dọjọ́ tó kú. A tún sábà máa ń sọ̀rọ̀ nípa bí ayé tuntun ṣe máa rí. Àwọn ìgbà kan tiẹ̀ wà tí mo máa ń sunkún lẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹ̀. Àmọ́ gbogbo ìgbà tá a bá kà nípà àwọn ìlérí amọ́kànyọ̀ tí Jèhófà ṣe, ara máa ń tù wá, a sì máa ń jèrè okun pa dà.—Sáàmù 37:18; 41:3.

Georgiy àti Lyudmila nípàdé

 Látìgbà tí mo ti mọ Jèhófà ni mo ti ń rọ́wọ́ ẹ̀ láyé mi. (Sáàmù 34:19) Nígbà tí mo wà lọ́dọ̀ọ́ tí mi ò sì tíì nírìírí, Jèhófà fìfẹ́ hàn sí mi torí ó lo àwọn ará láti ràn mí lọ́wọ́ kí n lè túbọ̀ láwọn ànímọ́ tó dáa. Yàtọ̀ síyẹn, Jèhófà fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ tù mí nínú nígbà tí nǹkan ò rọrùn fún mi ní àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ àti nígbèkùn. Ó tún fún mi ní okun tí mo nílò láti tọ́jú Maria ìyàwó mi ọ̀wọ́n títí tó fi kú. Ní báyìí, mo lè fi gbogbo ẹnu sọ pé Jèhófà fìfẹ́ hàn sí mi jálẹ̀ ìgbésí ayé mi.—Sáàmù 31:19.

a Kazakhstan, Moldova àti Ukraine wà lára Soviet Union títí di ọdún 1991.