Ṣé Jòhánù Arinibọmi Wà Lóòótọ́?
Àwọn ìwé Ìhìn Rere sọ̀rọ̀ nípa ọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jòhánù Arinibọmi, ẹni tó wàásù nípa Ìjọba Ọlọ́run ní Jùdíà. Ṣé ohun tí àwọn òpìtàn sọ nípa ọkùnrin yìí bá ohun tí Bíbélì sọ mu? Ẹ jẹ́ ká gbé àwọn kókó díẹ̀ yẹ̀ wò:
Bíbélì sọ pé: “Jòhánù Arinibọmi wá, ó ń wàásù ní aginjù Jùdíà, ó ń sọ pé: ‘Ẹ ronú pìwà dà, torí Ìjọba ọ̀run ti sún mọ́lé.’” (Mátíù 3:1, 2) Ǹjẹ́ àwọn ìwé ìtàn jẹ́rìí sí i pé òótọ́ ni ẹsẹ Bíbélì yìí sọ? Bẹ́ẹ̀ ni.
Òpìtàn ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní tó ń jẹ́ Flavius Josephus ṣàpèjúwe ọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ “Jòhánù, tí orúkọ àpèlé rẹ̀ ń jẹ́ Arinibọmi,” ẹni “tó gba àwọn Júù níyànjú láti máa gbé ìgbé ayé òdodo,” kí wọ́n “ní ìtara ìsìn fún Ọlọ́run” kí wọ́n sì “wá ṣe ìrìbọmi.”—Jewish Antiquities, Book XVIII.
Bíbélì ṣàlàyé pé Jòhánù bá Hẹ́rọ́dù Áńtípà wí, ẹni tó jẹ́ olùṣàkóso àgbègbè Gálílì àti Pèríà. Júù aláfẹnujẹ́ ni Hẹ́rọ́dù, ó sì sọ pé òun ń ṣègbọràn sí Òfin Mósè. Jòhánù sọ pé bí Hẹ́rọ́dù ṣe fẹ́ Hẹrodíà, tó jẹ́ ìyàwó arákùnrin rẹ̀ kò bójú mu rárá. (Máàkù 6:18) Ohun tí Bíbélì sọ yìí bá ohun tí àwọn ìwé míì sọ mu.
Òpìtàn Josephus sọ pé ìfẹ́ Hẹrodíà “kó sí” Áńtípà lórí àti pé “kíá ló sọ fún un pé òun fẹ́ kó di ìyàwó òun.” Hẹrodíà gbà, ó sì fi ọkọ rẹ̀ sílẹ̀, bó ṣe lọ fẹ́ Áńtípà nìyẹn.
Bíbélì sọ pé “àwọn èèyàn Jerúsálẹ́mù àti gbogbo Jùdíà àti gbogbo ìgbèríko tó yí Jọ́dánì ká máa ń lọ sọ́dọ̀ [Jòhánù], ó ń ṣèrìbọmi fún wọn ní odò Jọ́dánì.”—Mátíù 3:5, 6.
Josephus jẹ́ ká mọ̀ pé òótọ́ lóhun tí ẹsẹ Bíbélì yẹn sọ, ó kọ̀wé pé ńṣe ni “àwọn èrò” ń wọ́ wá láti rí Jòhánù àti pé “ohun tí Jòhánù ń kọ́ wọn wọ̀ wọ́n lọ́kàn gan-an [tàbí, ó ru wọ́n lọ́kàn sókè] lọ́nà tó ga jù lọ.
Ó ṣe kedere pé òpìtàn ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní náà Josephus gbà pé Jòhánù Arinibọmi ti gbé ayé rí, torí náà, ó yẹ káwa náà gbà bẹ́ẹ̀.