Ẹ MÁA ṢỌ́NÀ!
Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Bí Ọ̀gbẹlẹ̀ Ṣe Túbọ̀ Ń Ṣẹlẹ̀ Kárí Ayé?
“Àwọn tó wà lórílẹ̀-èdè Ṣáínà ròyìn pé ọdún yìí ni ooru tíì mú jù lọ, ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn ọdún yìí sì wà lára àsìkò tí ilẹ̀ ti gbẹ jù lọ.”—The Guardian, September 7, 2022.
“Ọdún karùn-ún rèé tí ọ̀gbẹlẹ̀ ti wà láwọn apá ibì kan ní Áfíríkà.”—UN News, August 26, 2022.
“Ó ṣeé ṣe kí ọ̀gbẹlẹ̀ wáyé ní ohun tó ju ìdajì àwọn orílẹ̀-èdè tó wà nílẹ̀ Yúróòpù, ọ̀dá òjò yìí ló sì máa burú jù lọ nínú gbogbo èyí tó ti ń ṣẹlẹ̀ láti nǹkan bí ọgọ́rùn-ún márùn-ún (500) ọdún sẹ́yìn.”—BBC News, August 23, 2022.
Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n ló sọ pé ọ̀gbẹlẹ̀ á ṣì máa wáyé, kódà á máa burú sí i. Ṣé ìrètí wà pé nǹkan ṣì máa dáa? Kí ni Bíbélì sọ?
Kí ni Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ nípa ọ̀gbẹlẹ̀
Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ nípa àsìkò wa yìí pé:
“Àìtó oúnjẹ . . . máa wà láti ibì kan dé ibòmíì.”—Lúùkù 21:11.
Ọ̀gbẹlẹ̀ sábà máa ń fa àìtó oúnjẹ. Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé àìtó oúnjẹ á máa fa ìyà àti ikú, bọ́rọ̀ sì ṣe rí lónìí gẹ́lẹ́ nìyẹn.—Ìfihàn 6:6, 8.
Ohun tó ń mú kí ọ̀gbẹlẹ̀ burú sí i
Bíbélì jẹ́ ká mọ ìdí tí ọ̀gbẹlẹ̀ fi ń burú sí i. Ó sọ pé:
“Kò sí ní ìkáwọ́ èèyàn tó ń rìn láti darí ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.”—Jeremáyà 10:23.
Ìyẹn túmọ̀ sí pé àwa èèyàn ò lè “darí ìṣísẹ̀ ara [wa],” ká sì ṣàṣeyọrí. Ohun kan ni pé, ohun táwọn èèyàn ń ṣe ló sábà máa ń fa ọ̀gbẹlẹ̀ àti ọ̀dá òjò.
Ọ̀pọ̀ àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì náà gbà pé ohun táwọn èèyàn ń ṣe ló ń fà á tí ayé fi túbọ̀ ń gbóná, ìyẹn sì ń mú kí ọ̀gbẹlẹ̀ túbọ̀ máa ṣẹlẹ̀ kárí ayé.
Ojúkòkòrò àti báwọn kan ṣe máa ń ṣòfin láìro ohun tó lè ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú ti fa ọ̀pọ̀ ìṣòro bí pípa igbó run, bíba afẹ́fẹ́ jẹ́ àti lílo àwọn ohun àmúṣọrọ̀ ayé yìí nílòkulò, ìyẹn sì ti fa ọ̀gbẹlẹ̀ torí pé ọ̀pọ̀ odò ló ń gbẹ.
Àmọ́ Bíbélì sọ ohun kan tó ń fini lọ́kàn balẹ̀.
Ṣé ìrètí wà pé nǹkan ṣì máa dáa?
Bíbélì ṣèlérí pé Ọlọ́run máa yanjú ìṣòro omi tó ń dín kù tá a ní báyìí. Àmọ́ báwo ló ṣe máa ṣe é?
1. Ọlọ́run máa “run àwọn tó ń run ayé.” (Ìfihàn 11:18) Ọlọ́run máa mú ọ̀kan lára ohun tó ń fa ọ̀gbẹlẹ̀ kúrò, ìyẹn àwọn èèyàn burúkú àtàwọn olójúkòkòrò tó ń bá àyíká jẹ́.—2 Tímótì 3:1, 2.
2. “Ilẹ̀ tí ooru ti mú kó gbẹ táútáú máa di adágún omi tí esùsú kún inú rẹ̀.” (Àìsáyà 35:1, 6, 7) Ọlọ́run máa tún àwọn ibi tí ọ̀gbẹlẹ̀ ti bà jẹ́ ṣe, á sì sọ ayé yìí di Párádísè tó lómi dáadáa.
3. “Ò ń bójú tó ayé, o mú kí ó ní ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ èso, kí ilẹ̀ rẹ̀ sì lọ́ràá dáadáa.” (Sáàmù 65:9) Ọlọ́run máa bù kún ayé, oúnjẹ gidi máa pọ̀ yanturu, omi tó dáa sì máa wà fún gbogbo èèyàn.