Àwọn Òfin Ọlọ́run Lórí Ìmọ́tótó Là Wọ́n Lójú Gan-an
Nígbà tó ku díẹ̀ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì wọ Ilẹ̀ Ìlérí ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ààbọ̀ (3500) ọdún sẹ́yìn, Ọlọ́run sọ pé òun máa dáàbò bò wọ́n lọ́wọ́ àwọn “àrùn burúkú” tí wọ́n mọ̀ ní Íjíbítì. (Diutarónómì 7:15) Ọ̀nà kan tó gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ó ṣàlàyé ohun tí wọ́n á máa ṣe láti dènà àrùn àti bí wọ́n á ṣe wà ní mímọ́ tónítóní. Bí àpẹẹrẹ:
Òfin orílẹ̀-èdè náà sọ pé wọ́n gbọ̀dọ̀ máa wẹ̀, kí wọ́n sì máa fọ aṣọ wọn.—Léfítíkù 15:4-27.
Tó bá dọ̀rọ̀ ìgbọ̀nsẹ̀, Ọlọ́run sọ fún wọn pé: “Kí ibi ìkọ̀kọ̀ kan wà tí wàá máa lò lẹ́yìn ibùdó, ibẹ̀ sì ni kí o lọ. Kí igi tó ṣeé fi gbẹ́lẹ̀ wà lára àwọn ohun èlò rẹ. Tí o bá lóṣòó ní ìta láti yàgbẹ́, kí o fi igi náà gbẹ́lẹ̀, kí o sì bo ìgbẹ́ rẹ.”—Diutarónómì 23:12, 13.
Ẹni tí wọ́n bá fura sí pé ó lárùn tó lè ranni máa ń gbé lọ́tọ̀, ìyẹn ni pé kò ní wà pẹ̀lú àwọn èèyàn tó kù fún àkókò kan. Kí àwọn tí ara wọn bá ti yá, tí àìsàn tó ń ṣe wọ́n sì ti lọ tó lè pa dà sáàárín àwọn èèyàn yòókù, wọ́n gbọ́dọ̀ fọ aṣọ wọn, kí wọ́n sì fi omi wẹ̀ kí wọ́n tó lè di “mímọ́.”—Léfítíkù 14:8, 9.
Ẹnikẹ́ni tó bá fọwọ́ kan òkú máa dá wà lọ́tọ̀.—Léfítíkù 5:2, 3; Nọ́ńbà 19:16.
Òfin tí Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti jẹ́ kí wọ́n máa ṣe àwọn ohun tí ìmọ̀ ìṣègùn wá gbé jáde lórí ọ̀rọ̀ ìmọ́tótó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún lẹ́yìn ìgbà ayé wọn.
Láwọn ilẹ̀ yòókù, wọn ò lajú rárá tó bá dọ̀rọ̀ ìmọ́tótó. Bí àpẹẹrẹ:
Ńṣe ni wọ́n ń ṣèdọ̀tí káàkiri. Omi tó dọ̀tí, oúnjẹ tó ti bà jẹ́ àtàwọn pàǹtírí lóríṣiríṣi mú kí gbogbo àyíká wọn dọ̀tí, ó sì fa àrùn àti ikú àwọn ọmọdé tó pọ̀ lápọ̀jù.
Àwọn oníṣègùn láyé àtijọ́ ò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀ nípa kòkòrò àrùn, kódà àwọn kan ò tiẹ̀ mọ̀ nípa rẹ̀ rárá. Lára ohun táwọn ará Íjíbítì ń lò bí “oògùn” ni ẹ̀jẹ̀ aláǹgbá, ìgbẹ́ ẹyẹ òfú, òkú eku, ìtọ̀ àti búrẹ́dì tó ti bu. Kódà ìgbẹ́ èèyàn àti ti ẹranko wà lára ohun tí wọ́n máa ń lò láti fi tọ́jú aláìsàn.
Oríṣiríṣi kòkòrò àrùn ló ń wọ ara àwọn ará Íjíbítì àtijọ́ látinú omi Odò Náílì àtàwọn ibi tí wọ́n ti ń fi omi rẹ̀ ṣiṣẹ́ àgbẹ̀, èyí sì ń dá àìsàn sí wọn lára. Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀pọ̀ ọmọ ọwọ́ ní Íjíbítì ló ń kú nítorí ìgbẹ́ gbuuru àtàwọn àìsàn míì tí oúnjẹ tó nídọ̀tí máa ń fà.
Tàwọn ọmọ Ísírẹ́lì yàtọ̀ pátápátá, ara wọn le ju tàwọn èèyàn ilẹ̀ yòókù lọ nítorí pé wọ́n ń pa Òfin Ọlọ́run mọ́.