ÌRÁNTÍ IKÚ JÉSÙ
Jésù Máa Fòpin sí Ìwà Ìkà
Jésù mọ ìrora tí ìwà ìkà àti àìṣèdájọ́ òdodo máa ń fà. Bí àpẹẹrẹ nígbà tó wà láyé, wọ́n parọ́ mọ́ ọn, wọ́n nà án láìṣẹ̀, wọ́n dá ẹjọ́ rẹ̀ lọ́nà tí kò tọ́, wọ́n fẹ̀sùn èké kàn án pé ọ̀daràn ni, wọ́n pa á ní ìpa ìkà. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò jẹ̀bi ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án, ó ṣe ohun tó fi hàn pé kò mọ tara ẹ̀ nìkan torí ó fínnúfíndọ̀ fi “ẹ̀mí rẹ̀ ṣe ìràpadà ní pàṣípààrọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn.” (Mátíù 20:28; Jòhánù 15:13) Ní báyìí, Jésù ti di Ọba Ìjọba Ọlọ́run, ó máa mú kí ìdájọ́ òdodo gbilẹ̀ kárí ayé, áá sì fòpin sí ìwà ìkà.—Àìsáyà 42:3.
Báwo ni ayé ṣe máa rí tí Jésù bá fòpin sí ìwà ìkà? Bíbélì sọ pé:
“Àwọn ẹni burúkú ò ní sí mọ́; wàá wo ibi tí wọ́n wà tẹ́lẹ̀, wọn ò ní sí níbẹ̀. Àmọ́ àwọn oníwà pẹ̀lẹ́ ni yóò jogún ayé, inú wọn yóò sì máa dùn jọjọ nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlàáfíà.”—Sáàmù 37:10, 11.
Báwo la ṣe lè fi hàn pé a mọyì ohun tí Jésù ti ṣe fún wa àtohun tó máa ṣe lọ́jọ́ iwájú? Bó ṣe wà nínú Lúùkù 22:19, Jésù sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ pé kí wọ́n máa rántí ikú òun. Lọ́dọọdún, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń pàdé pọ̀ láti rántí ikú ẹ̀ ní àyájọ́ ọjọ́ tó kú. Torí náà, a fẹ́ kó o dara pọ̀ mọ́ wa láti rántí ikú Jésù lọ́jọ́ Sunday, March 24, 2024.