APÁ 5
Àṣírí Iṣẹ́ Òkùnkùn
1. Báwo ni ìgbàgbọ́ nínú iṣẹ́ òkùnkùn ṣe gbilẹ̀ tó?
ÌWÉ náà, African Traditional Religion, sọ pé: “Ní ilẹ̀ Áfíríkà, fífi àkókò ṣòfò ló jẹ́ láti ṣẹ̀ṣẹ̀ máa jiyàn bóyá àwọn àjẹ́ wà tàbí pé wọn kò sí.” Ìwé ọ̀hún tún fi kún un pé: “Ẹni yòówù kó jẹ́, tó bá sáà ti jẹ́ ará Áfíríkà, yóò gbà pé àwọn àjẹ́ wà, wọn ò sì ṣeé fojú di.” Àti púrúǹtù àtọ̀mọ̀wé ló nígbàgbọ́ nínú iṣẹ́ òkùnkùn. Àwọn aṣáájú ẹ̀sìn Ìsìláàmù àti ẹ̀sìn Kristẹni pẹ̀lú nígbàgbọ́ nínú rẹ̀.
2. Gẹ́gẹ́ bí ohun tí ọ̀pọ̀ èèyàn gbà gbọ́, ibo ni agbára iṣẹ́ òkùnkùn ti ń wá?
2 Gẹ́gẹ́ bí ohun tí ọ̀pọ̀ èèyàn gbà gbọ́ nílẹ̀ Áfíríkà, agbára àìrí kan wà. Wọ́n ní agbára Ọlọ́run borí agbára àìrí yìí; àwọn ẹ̀mí àìrí àti àwọn baba ńlá sì lè lo agbára náà. Wọ́n tún sọ pé àwọn ẹ̀dá èèyàn kan wà tí àwọn pẹ̀lú mọ bí wọ́n ṣe lè rí agbára àìrí yìí gbà kí wọ́n sì lò ó fún iṣẹ́ òkùnkùn, bóyá láti fi ṣe rere (bí àwọn adáhunṣe) tàbí láti fi ṣe búburú (bí àjẹ́).
3. Kí ni iṣẹ́ oṣó, kí làwọn èèyàn sì gbà gbọ́ pé wọ́n lè fi ṣe?
3 Àwọn èèyàn sọ pé ọ̀tá ni wọ́n máa ń fi iṣẹ́ oṣó tí í ṣe iṣẹ́ òkùnkùn jẹ níyà. Wọ́n gbà gbọ́ pé àwọn oṣó ní agbára láti rán àdán, ẹyẹ, kòkòrò àti àwọn ẹranko mìíràn láti lọ ta jàǹbá fún ènìyàn. Ọ̀pọ̀ ló gbà gbọ́ pé àwọn oṣó máa ń fi iṣẹ́ òkùnkùn dá ìjà sílẹ̀, tí wọ́n máa ń fi ya ẹlòmíràn lágàn, tí wọ́n sì máa ń fi fa àìsàn àti ikú pàápàá.
4. Kí ni ọ̀pọ̀ èèyàn gbà gbọ́ nípa àwọn àjẹ́, kí sì làwọn kan tí wọ́n ti jẹ́ àjẹ́ rí ti fẹnu ara wọn jẹ́wọ́?
4 Èyí tó tún jọ ọ́ ni iṣẹ́ àjẹ́. Àwọn èèyàn gbà gbọ́ pé àwọn àjẹ́ máa ń bọ́ agọ̀ ara wọn sílẹ̀ ní òru, tí wọ́n á sì fò lọ bóyá láti lọ bá àwọn àjẹ́ mìíràn ṣèpàdé tàbí láti lọ pín ẹran ara èèyàn tó ṣì wà láàyè jẹ kí onítọ̀hún tó wá kú níkẹyìn. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé agọ̀ ara àwọn àjẹ́ wọ̀nyẹn máa ń wà lórí ibùsùn wọn níbi tí wọ́n sùn sí, ẹ̀rí tí wọ́n fi ń ti ọ̀rọ̀ yìí lẹ́yìn ni ohun tí wọ́n gbọ́ lẹ́nu àwọn tó fẹnu ara wọn jẹ́wọ́ tí wọ́n sì fi àjẹ́ ṣíṣe sílẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ìwé ìròyìn kan ní ilẹ̀ Áfíríkà fa ọ̀rọ̀ àwọn tó jẹ́ àjẹ́ nígbà kan rí (tí ọ̀pọ̀ jù lọ wọ́n jẹ́ ọ̀dọ́mọbìnrin) yọ, ó ní wọ́n sọ pé: “Mo ti pa àádọ́jọ [150] èèyàn nípa fífa jàǹbá ọkọ̀.” “Mo pa ọmọdé márùn-ún nípa fífa gbogbo ẹ̀jẹ̀ wọn mu.” “Mo pa ọ̀rẹ́kùnrin mi mẹ́ta nítorí pé wọ́n já mi sílẹ̀.”
5. Kí ni àwọn adáhunṣe wà fún, báwo ni wọ́n sì ṣe máa ń lo oògùn tiwọn?
5 Àwọn èèyàn sọ pé àwọn adáhunṣe máa ń dáàbò boni kúrò lọ́wọ́ ibi ni. Àwọn adáhunṣe máa ń lo òrùka ẹ̀rẹ tàbí kí wọ́n so owó ẹyọ mọ́rùn ọwọ́. Wọ́n máa ń jẹ oògùn tàbí kí wọ́n fi para láti dáàbò bo ara wọn. Wọ́n máa ń so àwọn nǹkan tí wọ́n gbà pé ó lágbára láti dáàbò bò wọ́n kọ́ inú ilé wọn tàbí kí wọ́n rì wọ́n mọ́lẹ̀. Tírà tí wọ́n fi àwọn ẹsẹ inú Kùránì kọ hàǹtú sí tàbí àwọn ońdè àti àdó ni òmíràn lára wọn gbẹ́kẹ̀ lé.
Irọ́ àti Ẹ̀tàn
6. Kí ni Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ ti ṣe rí, ojú wo ló sì yẹ ká fi wo agbára wọn?
6 Òótọ́ ni pé ọ̀tá pátápátá gbáà ni Sátánì àti àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ jẹ́ fún àwọn ẹ̀dá èèyàn. Wọ́n lágbára láti nípa lórí èrò inú àti ìgbésí ayé èèyàn, wọ́n sì ti kó wọ inú àwọn èèyàn àti ẹranko rí nígbà àtijọ́. (Mátíù 12:43-45) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò yẹ ká fojú kéré agbára wọn, kò yẹ ká ka agbára ọ̀hún sí bàbàrà ju bó ṣe yẹ lọ.
7. Kí ni Sátánì ń fẹ́ ká gbà gbọ́, báwo la sì ṣe ṣàkàwé èyí?
7 Sátánì jẹ́ ọ̀gá nínú ká tanni jẹ. Ó máa ń tan àwọn èèyàn kí wọ́n lè rò pé agbára òun pọ̀ ju ibi tí agbára òun mọ. Ẹ jẹ́ ká ṣàkàwé ohun tí à ń sọ: Nígbà ìjà kan tó wáyé láìpẹ́ yìí ní orílẹ̀-èdè kan ní ilẹ̀ Áfíríkà, àwọn sójà lo ìró ẹ̀rọ gbohùngbohùn láti fi dẹ́rù ba àwọn ọ̀tá wọn. Kí wọ́n tó kọ lu àwọn ọ̀tá, àwọn sójà yẹn á kọ́kọ́ fi ẹ̀rọ gbohùngbohùn gbé ìró àwọn àgbá bọ́ǹbù tó ń milẹ̀ tìtì àti ìró ìbọn jáde. Wọ́n fẹ́ kí àwọn ọ̀tá wọn rò pé ẹgbẹ́ ológun tó ní àwọn ohun ìjà tó lágbára ló dojú ìjà kọ wọ́n. Lọ́nà kan náà, Sátánì fẹ́ káwọn èèyàn gbà gbọ́ pé agbára òun kò láàlà. Ohun tó ń fẹ́ ṣe ni pé kó dẹ́rù ba àwọn èèyàn kí wọ́n lè máa ṣe ohun tó fẹ́ dípò ohun tí Jèhófà fẹ́. Nísinsìnyí, ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò irọ́ mẹ́ta tí Sátánì ń fẹ́ káwọn èèyàn gbà gbọ́.
8. Kí ni ọ̀kan lára irọ́ tí Sátánì ń tàn kálẹ̀?
8 Ọ̀kan lára irọ́ tí Sátánì ń tàn kálẹ̀ ni pé: Aburú kì í dédé ṣẹlẹ̀; gbogbo nǹkan búburú tó bá ṣẹlẹ̀ tí kò sì jẹ́ pé ẹnì kan ló ṣe é ní tààràtà ló jẹ́ pé agbára àìrí kan ló fà á. Bí àpẹẹrẹ, jẹ́ ká sọ pé àrùn ibà pa ọmọdé kan. Ìyá rẹ̀ lè mọ̀ pé ẹ̀fọn ló máa ń gbé àrùn ibà kiri. Ṣùgbọ́n ó tún lè gbà gbọ́ pé àjẹ́ ló rán ẹ̀fọn láti wá fa ẹ̀jẹ̀ ọmọ rẹ̀ mu.
9. Báwo ni Bíbélì ṣe fi hàn pé kì í ṣe Sátánì ló ń fa gbogbo ìṣòro?
9 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Sátánì lágbára láti fa àwọn ìṣòro kan, kò tọ̀nà láti gbà gbọ́ pé ó ní agbára láti fa gbogbo ìṣòro. Bíbélì sọ pé: “Eré ìje kì í ṣe ti ẹni yíyára, bẹ́ẹ̀ ni ìjà ogun kì í ṣe ti àwọn alágbára ńlá, bẹ́ẹ̀ ni oúnjẹ kì í ṣe ti àwọn ọlọ́gbọ́n pẹ̀lú, bẹ́ẹ̀ ni ọrọ̀ kì í ṣe ti àwọn olóye pẹ̀lú, bẹ́ẹ̀ ni ojú rere kì í ṣe ti àwọn tí ó ní ìmọ̀ pàápàá; nítorí pé ìgbà àti ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò rí tẹ́lẹ̀ ni ó ń ṣẹlẹ̀ sí gbogbo wọn.” (Oníwàásù 9:11) Sárésáré kan lè yára nínú eré sísá ju àwọn yòókù, ṣùgbọ́n ó ṣeé ṣe kí ó má gba ipò kìíní. Àwọn “ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò rí tẹ́lẹ̀” lè máà jẹ́ kí ó gba ipò kìíní. Ó ṣeé ṣe kó kọsẹ̀, kó sì ṣubú tàbí kó di pé ara rẹ̀ kò yá tàbí kí oríkèé rẹ̀ yẹ̀ lójijì. Àwọn nǹkan wọ̀nyí lè ṣẹlẹ̀ sí ẹnikẹ́ni. Kò fi dandan jẹ́ pé Sátánì tàbí àjẹ́ ló ń fà á; ó lè dédé ṣẹlẹ̀.
10. Kí làwọn kan sọ nípa àwọn àjẹ́, báwo la sì ṣe mọ̀ pé irọ́ gbáà nìyẹn?
10 Irọ́ kejì tí Sátánì tún ń tàn kálẹ̀ ni pé: Àwọn àjẹ́ máa ń bọ́ agọ̀ ara wọn sílẹ̀, tí wọ́n á
sì fò lọ lóru láti lọ pàdé àwọn àjẹ́ mìíràn tàbí láti lọ bá àwọn tí wọ́n bá fẹ́ pa jẹ. Ó dára, bi ara rẹ pé: ‘Bí àwọn àjẹ́ bá lè bọ́ agọ̀ ara wọn sílẹ̀, kí ni nǹkan náà gan-an tó ń jáde kúrò lára wọn?’ A ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ pé, ènìyàn fúnra rẹ̀ látòkèdélẹ̀ ni ọkàn, kì í ṣe ohun kan tí ó lè jáde kúrò lára ènìyàn. Síwájú sí i, ẹ̀mí jẹ́ agbára ìwàláàyè tó ń gbé ara ṣiṣẹ́ ṣùgbọ́n kò lè dá ohun kan ṣe fúnra rẹ̀ láìsí ara níbẹ̀.11. Kí nìdí tá a fi mọ̀ pé àwọn àjẹ́ kò lè bọ́ agọ̀ ara wọn sílẹ̀, ǹjẹ́ o gba èyí gbọ́?
11 Àti ọkàn o àti ẹ̀mí o, kò sí èyíkéyìí tó lè jáde kúrò nínú ara láti lọ ṣe ohunkóhun, ì báà jẹ́ rere tàbí búburú. Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn àjẹ́ kò lè bọ́ agọ̀ ara wọn sílẹ̀ láti jáde lọ máa rìn káàkiri. Ní ti gidi, wọn kò ṣe ohun tí wọ́n máa ń sọ pé àwọn ṣe tàbí ohun tí wọ́n máa ń ronú pé àwọn ti ṣe.
12. Báwo ni Sátánì ṣe máa ń jẹ́ kí àwọn èèyàn gbà pé àwọn ti ṣe ohun tí wọn kò ṣe?
12 Àlàyé wo la wá lè ṣe nípa ohun tí àwọn tó kà pé àjẹ́ làwọn sọ? Sátánì lè mú káwọn èèyàn gbà gbọ́ pé àwọn ti ṣe nǹkan tí wọn kò ṣe. Sátánì lè lo ìran láti fi mú kí ó ṣe àwọn èèyàn bíi pé àwọn ti rí nǹkan kan, pé àwọn ti gbọ́ nǹkan kan àti pé àwọn ti ṣe nǹkan kan tó jẹ́ pé wọn kò ṣe. Lọ́nà yìí, Sátánì retí láti yí àwọn èèyàn kúrò lọ́dọ̀ Jèhófà kí wọ́n lè ronú pé Bíbélì kò tọ̀nà.
13. (a) Ṣé iṣẹ́ òkùnkùn tó jẹ́ ti àwọn adáhunṣe dára? (b) Kí ni Ìwé Mímọ́ sọ nípa iṣẹ́ òkùnkùn?
13 Irọ́ kẹta ni pé: Iṣẹ́ òkùnkùn tó jẹ́ ti àwọn adáhunṣe, ìyẹn agbára àìrí tí wọ́n sọ pé ó lè borí agbára àwọn àjẹ́, dára. Bíbélì kò fìyàtọ̀ sí iṣẹ́ òkùnkùn ti àwọn adáhunṣe àti èyí tó jẹ́ ti àwọn àjẹ́. Gbogbo iṣẹ́ òkùnkùn ló kà léèwọ̀. Ronú nípa òfin tí Jèhófà fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì nípa iṣẹ́ òkùnkùn àtàwọn tó ń ṣe é:
-
“Ẹ kò sì gbọ́dọ̀ [ṣe iṣẹ́ òkùnkùn].”—Léfítíkù 19:26.
-
“Ní ti ọkùnrin kan tàbí obìnrin kan tí agbára ìbẹ́mìílò tàbí ẹ̀mí ìsàsọtẹ́lẹ̀ bá wà nínú rẹ̀, kí a fi ikú pa wọ́n láìkùnà.”—Léfítíkù 20:27.
-
“Kí a má ṣe rí láàárín rẹ . . . [oníṣẹ́ òkùnkùn] kan tàbí ẹnikẹ́ni tí ń wá àwọn àmì Diutarónómì 18:10-14.
ìṣẹ̀lẹ̀ tàbí oníṣẹ́ oṣó, tàbí ẹni tí ń fi èèdì di àwọn ẹlòmíràn tàbí ẹnikẹ́ni tí ń wádìí ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ abẹ́mìílò.”—
14. Kí nìdí tí Jèhófà fi ṣe òfin tó ka iṣẹ́ òkùnkùn léèwọ̀?
14 Àwọn òfin yìí mú un ṣe kedere pé Ọlọ́run kò fẹ́ kí àwọn èèyàn rẹ̀ ṣe iṣẹ́ òkùnkùn. Jèhófà fún àwọn èèyàn rẹ̀ ní òfin wọ̀nyí nítorí pé ó nífẹ̀ẹ́ wọn, kò sì fẹ́ kí wọ́n máa gbọ̀n jìnnìjìnnì nítorí ìbẹ̀rù àti ìgbàgbọ́ nínú ohun asán. Kò fẹ́ kí àwọn ẹ̀mí èṣù pọ́n wọn lójú.
15. Báwo ni Bíbélì ṣe fi hàn pé Jèhófà lágbára ju Sátánì lọ?
15 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì kò sọ gbogbo kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa ohun tí àwọn ẹ̀mí èṣù lè ṣe àti ohun tí wọn kò lè ṣe, síbẹ̀ ó fi hàn pé Jèhófà Ọlọ́run lágbára ju Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ lọ fíìfíì. Jèhófà ló pàṣẹ pé kí wọ́n lé Sátánì kúrò ní ọ̀run. (Ìṣípayá 12:9) Tún kíyè sí i pé, Sátánì tọrọ àyè lọ́wọ́ Ọlọ́run láti lọ dán Jóòbù wò, ó sì ṣègbọràn sí ìkìlọ̀ tí Ọlọ́run fún un pé kò gbọ́dọ̀ pa Jóòbù.—Jóòbù 2:4-6.
16. Ọ̀dọ̀ ta ló yẹ ká ti wá ààbò?
16 Òwe 18:10 sọ pé: “Orúkọ Jèhófà jẹ́ ilé gogoro tí ó lágbára. Olódodo sá wọ inú rẹ̀, a sì dáàbò bò ó.” Nítorí náà, ọ̀dọ̀ Jèhófà ló yẹ ká ti wá ààbò. Àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run kì í fi oògùn tàbí ọfọ̀ dáàbò bo ara wọn lọ́wọ́ iṣẹ́ ibi Sátánì àti àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í bẹ̀rù pé àwọn oníṣẹ́ òkùnkùn kan ń sa oògùn sí àwọn. Àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run gba ohun tí Bíbélì sọ gbọ́ pé: “Ní ti Jèhófà, ojú rẹ̀ ń lọ káàkiri ní gbogbo ilẹ̀ ayé láti fi okun rẹ̀ hàn nítorí àwọn tí ọkàn-àyà wọn pé pérépéré síhà ọ̀dọ̀ rẹ̀.”—2 Kíróníkà 16:9.
17. Kí ni Jákọ́bù 4:7 mú dá wa lójú, ṣùgbọ́n kí la gbọ́dọ̀ ṣe?
17 Ìwọ pẹ̀lú lè ní ìgbọ́kànlé yìí bí o bá ń sin Jèhófà. Jákọ́bù 4:7 sọ pé: “Ẹ fi ara yín sábẹ́ Ọlọ́run; ṣùgbọ́n ẹ kọ ojú ìjà sí Èṣù, yóò sì sá kúrò lọ́dọ̀ yín.” Bí o bá ń sin Ọlọ́run tòótọ́ náà, tí o sì ń fi ara rẹ sábẹ́ rẹ̀, o lè ní ìdánilójú pé Jèhófà yóò dáàbò bò ọ́.