BÁ A ṢE LÈ BẸ̀RẸ̀ Ọ̀RỌ̀ WA
Ẹ̀KỌ́ 3
Jẹ́ Onínúure
Ìlànà: “Ìfẹ́ máa ń ní . . . inú rere.”—1 Kọ́r. 13:4.
Ohun Tí Jésù Ṣe
1. Wo FÍDÍÒ yìí, tàbí kó o ka Jòhánù 9:1-7. Lẹ́yìn náà, kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:
-
Ṣé Jésù kọ́kọ́ la ojú ọkùnrin náà ni àbí ó kọ́kọ́ wàásù fún un?—Wo Jòhánù 9:35-38.
Kí La Rí Kọ́ Lára Jésù?
2. Tá a bá ṣe ohun tó fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ ẹni tá à ń wàásù fún, ó máa wù ú láti gbọ́rọ̀ wa.
Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Jésù
3. Máa fọ̀rọ̀ ro ara ẹ wò. Gbìyànjú láti mọ bí nǹkan ṣe rí lára ẹni tó o fẹ́ wàásù fún.
-
Bi ara ẹ pé: ‘Kí ló ṣeé ṣe kó jẹ́ ìṣòro ẹni náà? Kí ni mo lè ṣe láti ràn án lọ́wọ́ kára lè tù ú?’ Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, wàá lè fi inú rere hàn sí i látọkàn wá.
-
Tẹ́nì kan bá sọ ìṣòro ẹ̀ fún ẹ tàbí tó sọ bí nǹkan ṣe rí lára ẹ̀, má bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀ nípa nǹkan míì. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni kó o fara balẹ̀ gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹ̀, ìyẹn á jẹ́ kó mọ̀ pé o nífẹ̀ẹ́ òun.
4. Máa sọ̀rọ̀ tó dáa lẹ́nu. Tí àánú ẹnì kan bá ń ṣe ẹ́ tó o sì fẹ́ ràn án lọ́wọ́, ó máa hàn nínú bó o ṣe ń bá a sọ̀rọ̀. Ronú dáadáa nípa nǹkan tó o fẹ́ sọ àti bó o ṣe máa sọ ọ́, má sì sọ̀rọ̀ tó lè bí i nínú.
5. Máa ṣoore. Tó o bá rí i pé ẹnì kan nílò ìrànlọ́wọ́, gbìyànjú kó o ràn án lọ́wọ́. Tá a bá fi inú rere hàn sáwọn èèyàn, ó lè mú kó wù wọ́n láti gbọ́ ọ̀rọ̀ wa.