ORÍ 87
Múra Sílẹ̀, Kó O sì Jẹ́ Ọlọ́gbọ́n
-
ÀPÈJÚWE ÌRÍJÚ ALÁÌṢÒDODO
-
FI ỌRỌ̀ TÓ O NÍ “WÁ Ọ̀RẸ́” FÚN ARA RẸ
Ó yẹ kí àpèjúwe tí Jésù ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe nípa ọmọ tó sọ nù kọ́ àwọn agbowó orí, àwọn akọ̀wé òfin àtàwọn Farisí pé Ọlọ́run ṣe tán láti dárí ji ẹlẹ́ṣẹ̀ tó bá ronú pìwà dà. (Lúùkù 15:1-7, 11) Ní báyìí, Jésù yíjú sí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. Ó sọ àpèjúwe ọkùnrin olówó kan tó gbọ́ pé ẹni tó ń bójú tó ilé òun tàbí ìríjú òun kò ṣe ohun tó yẹ kó ṣe.
Nínú àpèjúwe yẹn, wọ́n fẹ̀sùn kan ìríjú náà pé kò bójú tó àwọn ohun ìní ọ̀gá rẹ̀ dáadáa. Ni ọ̀gá bá sọ pé òun máa lé ìríjú náà lọ. Ìríjú yẹn wá ń dà á rò pé: “Kí ni kí n ṣe, ní báyìí tí ọ̀gá mi fẹ́ gba iṣẹ́ ìríjú lọ́wọ́ mi? Mi ò lágbára tó láti gbẹ́lẹ̀, ojú sì ń tì mí láti ṣagbe.” Kí wàhálà yẹn má bàa pọ̀ jù fún un, ó pinnu ohun tó máa ṣe, ó sọ pé: “Mo mọ ohun tí màá ṣe, kó lè jẹ́ pé tí wọ́n bá gba iṣẹ́ ìríjú lọ́wọ́ mi, àwọn èèyàn máa gbà mí sínú ilé wọn.” Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ló pe àwọn tó jẹ ọ̀gá rẹ̀ ní gbèsè, ó bi ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn pé: “Èló lo jẹ ọ̀gá mi?”—Lúùkù 16:3-5.
Ẹni àkọ́kọ́ dáhùn pé: “Ọgọ́rùn-ún (100) òṣùwọ̀n òróró ólífì”, ìyẹn nǹkan bí ọgọ́rùn-ún márùn-ún àti ọgọ́rin (580) gálọ́ọ̀nù òróró. Ó ṣeé ṣe kí ọkùnrin yìí ní oko tó ti ń ṣe òróró ólífì tàbí kó jẹ́ pé òwò òróró ló ń ṣe. Ìríjú náà sọ fún un pé: “Gba ìwé àdéhùn tí o kọ pa dà, jókòó, kí o sì kọ àádọ́ta (50) [ìyẹn òróró gálọ́ọ̀nù ọgọ́rùn-ún méjì àti àádọ́rùn-ún (290)] kíákíá.”—Lúùkù 16:6.
Ìríjú náà bi ẹlòmíì pé: “Ìwọ, èló ni gbèsè tí o jẹ?” Ó dáhùn pé: “Ọgọ́rùn-ún (100) òṣùwọ̀n ńlá àlìkámà,” ìyẹn nǹkan bí ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogún ó lé méjì (22,000) lítà. Ìríjú yẹn wá sọ fún un pé: “Gba ìwé àdéhùn tí o kọ pa dà, kí o sì kọ ọgọ́rin (80),” ìyẹn ni pé ó yọ òṣùwọ̀n ńlá àlìkámà ogún (20) kúrò nínú gbèsè tí ọkùnrin náà jẹ.—Lúùkù 16:7.
Torí pé ìríjú yẹn ló ṣì ń bójú tó ohun ìní ọ̀gá rẹ̀, ó láǹfààní láti dín owó tí wọ́n jẹ ọ̀gá rẹ̀ kù. Bó sì ṣe ń dín owó náà kù, ṣe ló ń mú wọn lọ́rẹ̀ẹ́ kí wọ́n lè ṣojú àánú sí i nígbà tí iṣẹ́ bá bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀.
Nígbà tó yá, ọ̀gá yẹn gbọ́ ohun tí ìríjú yìí ṣe. Ohun tó ṣe yìí máa fa àdánù lóòótọ́, àmọ́ ó wú ọ̀gá rẹ̀ lórí ó sì gbóríyìn fún un. “Bó tiẹ̀ jẹ́ pé aláìṣòdodo ni, ó lo ọgbọ́n tó gbéṣẹ́.” Jésù wá sọ pé: “Àwọn ọmọ ètò àwọn nǹkan yìí gbọ́n féfé sí ìran tiwọn ju àwọn ọmọ ìmọ́lẹ̀ lọ.”—Lúùkù 16:8.
Jésù ò sọ pé ohun tí ìríjú yẹn ṣe dáa, bẹ́ẹ̀ ni kò fọwọ́ sí i pé ká máa rẹ́ àwọn èèyàn jẹ. Kí wá ni kókó inú àpèjúwe yìí? Ó gba àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ níyànjú pé: “Ẹ fi ọrọ̀ àìṣòdodo wá ọ̀rẹ́ fún ara yín, kó lè jẹ́ pé, tó bá kùnà, wọ́n máa lè gbà yín sínú àwọn ibùgbé ayérayé.” (Lúùkù 16:9) Òótọ́ ni, àpèjúwe yìí kọ́ wa pé ó yẹ ká máa ronú jinlẹ̀ ká sì jẹ́ ọlọ́gbọ́n. Ó yẹ káwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run, ìyẹn “àwọn ọmọ ìmọ́lẹ̀” máa fọgbọ́n lo ohun ìní wọn, kí wọ́n sì máa ronú nípa ìyè àìnípẹ̀kun tí Ọlọ́run ṣèlérí lọ́jọ́ iwájú.
Jèhófà Ọlọ́run àti Ọmọ rẹ̀ nìkan ló lè gba ẹnì kan sínú Ìjọba ọ̀run tàbí sínú Párádísè tó máa wà láyé lábẹ́ Ìjọba yẹn. Ó yẹ ká mú wọn lọ́rẹ̀ẹ́ báyìí ní ti pé ká máa fi àwọn ohun ìní wa ti iṣẹ́ Ìjọba náà lẹ́yìn. Èyí á sì mú ká ní ìyè àìnípẹ̀kun lọ́jọ́ iwájú nígbà tí wúrà, fàdákà tàbí àwọn ohun ìní wa ò bá wúlò mọ́, tá a sì pàdánù wọn.
Jésù tún ṣàlàyé pé àwọn tó bá jẹ́ olóòótọ́ bí wọ́n ṣe ń bójú tó ọrọ̀ tàbí ohun ìní wọn máa jẹ́ olóòótọ́ tí wọ́n bá ń bójú tó ohun tó ṣe pàtàkì jùyẹn lọ. Ni Jésù bá sọ pé: “Torí náà, tí ẹ kò bá tíì fi hàn pé olóòótọ́ ni yín tó bá kan ọrọ̀ àìṣòdodo, ta ló máa fi ohun tó jẹ́ òtítọ́ [ìyẹn ohun tó jẹ mọ́ Ìjọba yẹn] sí ìkáwọ́ yín?”—Lúùkù 16:11.
Jésù fẹ́ káwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ mọ̀ pé ohun kékeré kọ́ ló máa ná wọn tí wọ́n bá máa gbà wọ́n “sínú àwọn ibùgbé ayérayé.” Èèyàn ò lè máa sin Ọlọ́run tọkàntọkàn kó sì tún jẹ́ ẹrú fún ọrọ̀ àìṣòdodo tàbí ohun ìní rẹ̀. Jésù wá parí ọ̀rọ̀ ẹ̀ pé: “Kò sí ìránṣẹ́ tó lè jẹ́ ẹrú ọ̀gá méjì, àfi kó kórìíra ọ̀kan, kó sì nífẹ̀ẹ́ ìkejì tàbí kó fara mọ́ ọ̀kan, kó má sì ka ìkejì sí. Ẹ ò lè jẹ́ ẹrú Ọlọ́run àti Ọrọ̀.”—Lúùkù 16:9, 13.