À Ń WÀÁSÙ A SÌ Ń KỌ́NI KÁRÍ AYÉ
Áfíríkà
-
ILẸ̀ 58
-
IYE ÈÈYÀN 1,082,464,150
-
IYE AKÉDE 1,453,694
-
IYE ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ BÍBÉLÌ 3,688,959
Iṣẹ́ Ìwàásù Lórí Alùpùpù
Ní àwọn ìgboro tó wà lápá gúúsù orílẹ̀-èdè Benin, alùpùpù ni wọ́n sábà máa ń lò láti fi gbé èrò. Zem làwọn ará ibẹ̀ máa ń pe àwọn alùpùpù yìí. Arákùnrin Désiré tó jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ fi ẹ̀rọ gbohùn-gbohùn méjì sára zem rẹ̀ káwọn èrò tó gbé lè máa gbọ́ àwọn ìtẹ̀jáde wa àti àwọn àwòkẹ́kọ̀ọ́ tá a gbohùn rẹ̀ sílẹ̀. Bó sì ṣe fẹ́ kó rí náà ló máa ń rí. Ohun tí wọ́n ń gbọ́ yìí máa ń wọ̀ ọ̀pọ̀ wọn lọ́kàn débi pé tí wọ́n bá dé ibi tó ti yẹ kí wọ́n sọ̀, wọn ò ní fẹ́ bọ́ọ́lẹ̀ mọ́ àfi tí wọ́n bá gbọ́ ọ parí. Arákùnrin Désiré sọ pé: “Lóòótọ́, mo fẹ́ kí èrò tí mó gbé sanwó kí wọ́n sì bọ́ọ́lẹ̀, àmọ́ mo mọ̀ pé káwọn èèyàn gbọ́ ìhìn rere yìí ṣe pàtàkì ju owó lọ. Yàtọ̀ síyẹn, àìmọye ìwé ni mo máa ń fi sóde lọ́nà yìí.”
Ọmọ Náà Kò Juwọ́ Sílẹ̀
Ọmọbìnrin ọlọ́dún mẹ́fà ni Nolla, orí àwọn òkè tó wà ní orílẹ̀-èdè Bùrúńdì ni òun àti ìdílé rẹ̀ ń gbé. Lọ́jọ́ kan, ìdílé Nolla ń fi àdògán kékeré kan dáná lọ́wọ́, àwọn ọkùnrin méjì tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ nílé kejì wá béèrè pé kí wọ́n fọnná fún àwọn kí àwọn fi dáná tàwọn. Nolla ló ń ko iná náà lọ́wọ́ nígbà tí wọ́n dé, ó sì gbà wọ́n láyè láti fọnná. Kò pẹ́ lẹ́yìn ìyẹn ni Nolla kọjá níbi táwọn ọkùnrin náà wà, ó wá rí i pé sìgá ni wọ́n fi iná yẹn ràn. Ó dun Nolla gan-an, ló bá sọ fún àwọn ọkùnrin náà pé: “Ká ní mo mọ̀ pé sìgá lẹ fẹ́ fi iná yẹn ràn ni, mi ò bá má fún yín.” Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Nolla ò tíì bẹ̀rẹ̀ ilé-ìwé ó rántí pé òun rí ìwé ìròyìn kan tí wọ́n ya àwòrán sìgá sí ní Gbọ̀ngàn Ìjọba. Kíá ló sáré lọ Gbọ̀ngàn Ìjọba tó sì mú ẹ̀dà méjì lára Ilé Ìṣọ́ June 1, 2014 tó sọ̀rọ̀ nípa sìgá mímu, ó wá fún àwọn ọkùnrin náà, ó sì ní kí wọ́n kà á lójú ẹsẹ̀. Ìgbà tó yá, Nolla pa dà rí àwọn ọkùnrin náà, ó sì fún wọn ní ìwé ìkésíni sí àpéjọ àgbègbè. Akitiyan ọmọ yìí àti bí kò ṣe juwọ́ sílẹ̀ ya àwọn ọkùnrin yìí lẹ́nu débi pé wọ́n wá sí àpéjọ náà fún ọjọ́ méjì. Nígbà ìsinmi ọ̀sán, Nolla pè wọ́n kí wọ́n wá jẹun lọ́dọ̀ ìdílé òun. Ohun tí wọ́n rí, tí wọn sì gbọ́ ní àpéjọ yẹn wọ̀ wọ́n lọ́kàn débi pé àwọn méjèèjì bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
Iṣẹ́ Ìwàásù ní Ọgbà Ẹ̀wọ̀n
Àwọn alàgbà tó wà ní orílẹ̀-èdè Làìbéríà ń wàásù ìhìn rere náà ní àwọn ọgbà ẹ̀wọ̀n ìjọba tó wà níbẹ̀. Arákùnrin Yves tó jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe ní Monrovia, ìyẹn olú-ìlú Làìbéríà, sọ pé: “Àwọn ẹlẹ́wọ̀n mẹ́ta ló di akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi lóṣù March, ìyẹn mú kí iye àwọn akéde tó wà ní Monrovia Central Prison di mẹ́fà báyìí.” Báwo làwọn akéde yìí ṣe ń wàásù? Arákùnrin Yves ṣàlàyé pé: “Wọ́n máa ń jáde òde-ẹ̀rí láwọn ọjọ́ Wednesday àti Sátidé nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n yẹn. Wọ́n á wá lọ láti yàrá ẹ̀wọ̀n kan sí ìkejì láti sọ ìrètí tó wà nínú Bíbélì fáwọn ẹlẹ́wọ̀n bíi tiwọn.” Àìmọye àwọn ẹlẹ́wọ̀n ló ń gbádùn ìdákẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí wọ́n sì ń wá sí ìpàdé tá à ń ṣe lọ́gbà ẹ̀wọ̀n. Àwọn ẹlẹ́wọ̀n mọ́kàndínlọ́gọ́rin [79] ló sì gbádùn àsọyé tí aṣojú ẹ̀ka ọ́fíísì sọ lọ́gbà ẹ̀wọ̀n náà. Àwọn ọgbà ẹ̀wọ̀n mẹ́fà míì tún ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì fún àwùjọ àwọn ẹlẹ́wọ̀n, ńṣe lèyí sì ń nípa rere lórí àwọn ẹlẹ́wọ̀n náà.
“Ẹ Jọ̀ọ́, Ẹ Wá Ràn Wá Lọ́wọ́”
Iṣẹ́ ribiribi làwọn ará wa ṣe káwọn tó nífẹ̀ẹ́ sí Bíbélì láwọn ibi àdádó yẹn lè wá sí Ìrántí Ikú Kristi. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ẹ̀yà San tí wọ́n tún ń pè ní Bushmen ló kọ́kọ́ ń gbé ní gúúsù Áfíríkà. Ṣe ni wọ́n máa ń kó kiri bí wọ́n ṣe ń ṣọdẹ tí wọ́n sì ń ṣa àwọn èso tí wọ́n bá rí jẹ. Arákùnrin Glenn tó jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe ní àríwá orílẹ̀-èdè Nàmíbíà ṣètò bí wọ́n ṣe ṣe Ìrántí Ikú Kristi ti ọdún 2015 ní abúlé àwọn San kan tó wà ní àdádó. Abúlé yìí fi kìlómítà ọgọ́rùn-ún méjì àti àádọ́rin [270] jìnnà sí ìlú Rundu. Ẹ̀ẹ̀kejì tí wọ́n máa ṣe Ìrántí Ikú Aísáyà 35:5, 6. Arákùnrin Glenn ní ọ̀pọ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó ń tẹ̀ síwájú ní agbègbè yẹn. Ó ròyìn pé: “Láti nǹkan bí ọdún méjì ni mo ti máa ń wá síbí lóṣooṣù. Màá pàgọ́ síbí fún ọjọ́ mélòó kan. Torí ọ̀nà tó jìn àti èdè tó yàtọ̀ síra, ó ṣòro fáwọn ará ibí láti tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí. Ẹ jọ̀ọ́, ẹ wá ràn wá lọ́wọ́. Nígbà tí mo lọ bá àwọn aláṣẹ àdúgbò fún ètò Ìrántí Ikú Kristi ti ọdún yìí, ọ̀kan nínú àwọn ìgbìmọ̀ ìlú bi mí bóyá àá fẹ́ kọ́ ilé ìjọsìn wa sí àdúgbò àwọn. Ó sọ pé àwọn á pèsè ilẹ̀, àwọn á sì fi owó ara wọn kọ́ ọ. Gbogbo ohun tí àwa máa ṣe ò ju pé ká mú ‘pásítọ̀’ wá, tàbí kẹ̀ ká kọ́ ọ̀kan lára àwọn kó lè di pásítọ̀.”
Kristi ní abúlé yìí rèé. Bíi ti ìgbà àkọ́kọ́, àwọn olórí abúlé yìí gbà káwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lo yàrá kóòtù àdúgbò láìgba kọ́bọ̀. Iye èèyàn tó pé jọ jẹ́ igba ó lé méjìlélọ́gbọ̀n [232] láìka ti àrọ̀ọ̀rọ̀dá òjò tó rọ̀ kí ìpàdé náà tó bẹ̀rẹ̀ àti nígbà tó ń lọ lọ́wọ́. Èdè Khwe làwọn ará abúlé yìí máa ń sọ, èdè ọ̀hún ò sì rọrùn sọ. Àmọ́ ẹnì kan ṣe ògbufọ̀ àsọyé náà látèdè Gẹ̀ẹ́sì sí èdè Khwe. Torí kò sí Bíbélì ní èdè Khwe, wọ́n fí àwọn àwòrán mèremère ṣàlàyé àwọn ẹsẹ Bíbélì bí