Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍLẸ̀-ÈDÈ DOMINICAN

Ajose Trujillo ati Soosi Katoliiki

Ajose Trujillo ati Soosi Katoliiki

IRÚ àjọṣe wo ló wà láàárín Ọ̀gbẹ́ni Trujillo àti Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì? Ẹnì kan tó jẹ́ alálàyé lórí ọ̀rọ̀ òṣèlú sọ pé: “Lọ́dún 1930 sí 1961 tí Trujillo fi ṣàkóso, ọ̀rọ̀ ìjọba àtàwọn aṣáájú ẹ̀sìn ṣọ́ọ̀ṣì ní Orílẹ̀-èdè Dominican wọ̀ gan-an, aláṣẹ bóofẹ́bóokọ̀ yìí ran àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì lọ́wọ́, àwọn náà sì ń ti ìjọba rẹ̀ lẹ́yìn.”

Lọ́dún 1954, Trujillo lọ sí ìlú Róòmù, ó sì tọwọ́ bọ̀wé àdéhùn pẹ̀lú Póòpù. Ọ̀gbẹ́ni Germán Ornes tó fìgbà kan rí jẹ́ ọ̀rẹ́ tí Trujillo máa ń finú hàn, sọ pé: “Torí pé ọwọ́ Ṣọ́ọ̀ṣì ilẹ̀ Dominican wọ ọwọ́ pẹ̀lú ìjọba Trujillo, ìtìlẹ́yìn ńlá gbáà ni [àdéhùn náà] jẹ́ fún ‘Ọ̀gá Àgbà’ náà, [ìyẹn Trujillo]. Àwọn aṣáájú ẹ̀sìn ṣọ́ọ̀ṣì lábẹ́ àṣẹ Bíṣọ́ọ̀bù Àgbà tó ń jẹ́ Ricardo Pittini àti Octavio Beras sì ni òléwájú lára àwọn tó ń ṣagbátẹrù ìjọba náà.”

Ọ̀gbẹ́ni Ornes tún sọ pé: “Póòpù máa ń fi ìkíni ọlọ́rẹ̀ẹ́sọ́rẹ̀ẹ́ ránṣẹ́ sí Trujillo ní gbogbo ìgbà tó bá yẹ. . . . Lọ́dún 1956, Kádínà Francis Spellman tó jẹ́ aṣojú pàtàkì fún Póòpù mú ìkíni ọlọ́yàyà wá fún àwọn tó pé jọ síbi Àpérò Tó Dá Lórí Àṣà Ẹ̀sìn Kátólíìkì, èyí tí wọ́n ṣe nílùú Ciudad Trujillo, tí Ọ̀gbẹ́ni Trujillo sì ṣe onígbọ̀wọ́ rẹ̀. Ìlú New York ni Kádínà Spellman gbà wá síbi àpérò náà, Balógun fúnra rẹ̀ [ìyẹn Trujillo] ló sì lọ kí i káàbọ̀ tìlù tìfọn. Àwòrán bí wọ́n ṣe dì mọ́ra ló wà lójú ewé àkọ́kọ́ gbogbo ìwé ìròyìn ilẹ̀ Dominican lọ́jọ́ kejì.”

Lọ́dún 1960, ìwé ìròyìn Time sọ pé: “Títí di báyìí, ọ̀rọ̀ àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì àti Trujillo wọ̀ gan-an. Bíṣọ́ọ̀bù Àgbà ilẹ̀ Amẹ́ríkà tó ń jẹ́ Ricardo Pittini ti di ẹni ọdún mẹ́tàlélọ́gọ́rin [83] báyìí, kò sì ríran mọ́, àmọ́ lọ́dún mẹ́rin sẹ́yìn, ó fọwọ́ sí lẹ́tà kan tí wọ́n kọ sí àwọn oníwèé ìròyìn New York Times láti fi gbóṣùbà fún Trujillo pé ‘àwọn ará ìlú “apàṣẹwàá” yìí fẹ́ràn rẹ̀, wọ́n sì ń bọ̀wọ̀ fún un.’”

Àmọ́ lẹ́yìn ọgbọ̀n [30] ọdún táwọn ẹlẹ́sìn Kátólíìkì ti ń ṣagbátẹrù ìjọba Trujillo tó burú jáì yìí, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í yíhùn pa dà nígbà tí wọ́n rí i pé ìjọba ti fẹ́ bọ́ sọ́wọ́ ẹlòmíì. Alálàyé lórí ọ̀rọ̀ òṣèlú yẹn sọ pé: “Bí àwọn aṣáájú ẹ̀sìn ṣọ́ọ̀ṣì tí wọ́n jẹ́ ọ̀rẹ́ kòríkòsùn pẹ̀lú Trujillo ṣe rí i pé ohùn àwọn tó ń ṣàtakò apàṣẹwàá yìí ti ń ranlẹ̀ sí i àti pé wọ́n ti fẹ́ yí ètò ìjọba pa dà sí tiwa-n-tiwa, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í pa dà lẹ́yìn Trujillo.”

Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, ó wá di dandan pé kí àwọn aṣáájú ẹ̀sìn ṣọ́ọ̀ṣì tọrọ àforíjì lọ́wọ́ àwọn èèyàn ilẹ̀ Dominican lọ́dún 2011. Ara ọ̀rọ̀ tí wọ́n kọ sínú lẹ́tà tó fara hàn nínú ìwé ìròyìn Dominican Today ni pé: ‘A gbà pé a ti ṣàṣìṣe, a ò rọ̀ mọ́ ìgbàgbọ́ wa, a ò ṣe ojúṣe wa, a ò sì ṣiṣẹ́ wa bí iṣẹ́. Torí náà, a tọrọ àforíjì lọ́wọ́ gbogbo ẹ̀yin ará ìlú Dominican pé kẹ́ ẹ jọ̀wọ́ gba tiwa rò, kẹ́ ẹ sì forí jì wá.’