Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Orile-ede Dominican

Orile-ede Dominican

LỌ́DÚN 1492, ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Christopher Columbus wakọ̀ lọ sí àwọn ilẹ̀ kan tó pè ní Ayé Tuntun. Àwọn ilẹ̀ tuntun náà fani mọ́ra, ó lè rí tajé ṣe níbẹ̀, ó sì lè ṣàwárí àwọn nǹkan tuntun. Orúkọ tó fún ọ̀kan lára àwọn erékùṣù tó gúnlẹ̀ sí ni La Isla Española tàbí Hispaniola. Ìdá méjì nínú mẹ́ta erékùṣù náà jẹ́ ti Orílẹ̀-èdè Dominican báyìí. Ní báyìí, ọ̀pọ̀ àwọn tó ń gbé lórílẹ̀-èdè yẹn ti wá ṣàwárí ohun tó yàtọ̀ pátápátá sí ti Columbus, ìyẹn ni ayé tuntun níbi tí òdodo yóò ti gbilẹ̀ títí láé lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run. (2 Pét. 3:13) Ìtàn alárinrin tá a fẹ́ sọ yìí dá lórí àwọn èèyàn tó lọ́kàn rere tí wọ́n ṣe àwárí tó pabanbarì náà.

NÍ APÁ YÌÍ

Alaye Soki Nipa Orile-Ede Dominican

Ka oro soki nipa orile-ede naa atawon to n gbebe.

Bi Ise Iwaasu Se Bere

Bawo lo se pe to kawon misonnari to bere si i ko awon eeyan lekoo Bibeli ni Orile-ede Dominican?

“A Maa Ri Won”

Leyin odun metala, Pablo González ri awon to n wa.

Won Fi Won Sewon, Won si Fofin De Won

Bawo ni awon Elerii Jehofakan se fara da ifiyajeni ni opo odun ti won fi wa lewon?

Ise Iwaasu Ko Dawo Duro

Kabeeji ati efo tete lawon akede n ko sinu iroyin won dipo wakati ati ipadabewo.

Won Da Wa Sile, Won Tun Fofin De Wa

Leyin odun mefa ti won fi fofin de ise Awa Elerii Jehofa ni Orile-ede Dominican, won fun wa lominira lodun 1956, sugbon ko ju osu mokanla lo.

Ajose Trujillo ati Soosi Katoliiki

Leyin opo odun ti awon asaaju esin soosi ti je ore korikosun apasewaa ile Dominican, won pa da leyin re, won si toro aforiji lowo awon ara ilu.

Atako Lilekoko

Won satako sawon Elerii loooto, amo se won bori won?

Ta Ni Olori?

Lara ohun ti won lo ki ounje temi le wa ko si see pin kiri nigba ifofinde ni ero ti won fi n se adako iwe, garawa ororo nla, apo idoho ati paki.

Won O Beru Pe Won Le Mu Won

Bo tie je pe won fofin de ipade awon Elerii ni Orile-ede Dominican, won da orisirisi ogbon ti won fi n sepade, ijoba o si ri won mu.

Ifarada Mu Itura Wa

Leyin opo odun ti ijoba ti n satako, awon Elerii to wa ni Orile-ede Dominican ri iranwo gba lati ibi ti won o fokan si.

“Mo Figboya Ja Bii Kinniun”

Eemeji otooto ni Luis Eduardo Montás gbiyanju lati pa aare apasewaa to wa lorile-ede re, ibi to ti n wa bo se fe pa a lo ti ri eko otito Bibeli.

“O Da Mi Loju Pe Ijoba Olorun Maa De”

Won fi Efraín De La Cruz si ogba ewon meje otooto, won si lu u ni alubami tori pe o n waasu ihin rere. Ki lo se ti itara re ko fi din ku fun ogota [60] odun?

“Mi O Ni Yee Je Elerii Jehofa”

Olori esin kan kilo fun Mary Glass pe ori re maa da ru to ba ka Bibeli. Amo o ka a, o si wa ri idi ti won fi ni ko ma ka a.

Ominira Lati Waasu

Leyin ti won pa Trujillo, awon misonnari pupo si i de, won si bere si i waasu. Won mu etanu lodi si awon Elerii Jehofa kuro lokan awon eeyan diedie.

Mura Tan Lati Duro

Laika gbogbo rogbodiyan oselu si, ise iwaasu ko dawo duro. Ki lo je ko se kedere pe awa Elerii Jehofa ti “mura tan lati duro” si Orile-ede Dominican?

A Nilo Awon Oniwaasu Pupo Si I

Ta o ba soro nipa awon to wa si Orile-ede Dominican lati waasu, a je pe itan awa Elerii Jehofa nibe ko tii pe niyen.

Won Nifee Awon Ara Won

Leyin ti iji lile Georges sose kaakiri Orile-ede Dominican lodun 1998, bi awon Elerii Jehofa se fife seranwo tu opo eeyan ninu o si fiyin fun oruko Jehofa Olorun.

Ohun Ta A Se Nigba Ta A Po Si I

Bi awon Elerii se n po si i, bawo ni won se ri si i pe won ni ile to po to fun ijosin ati awon arakunrin ti otito jinle ninu won taa maa mupo iwaju?

Wiwaasu Lede Creole Ti Ile Haiti

Awon Elerii Jehofa n waasu ihin rere Ijoba naa fawon to n so ede Creole ti ile Haiti. Bi ojo se n gori ojo, won da awon ijo atawon kilaasi ti won ti n fi ede naa koni sile.

Imititi Ile Lorile-Ede Haiti

Eka ofiisi awon Elerii Jehofa ni Orile-ede Dominican pese iranwo lopo repete leyin imititi ile to waye lodun 2010 lorile-ede Haiti. Opo eeyan yonda ara won lati seranwo.

A N Reti Awon Ohun To Maa Funni Layo

Lati odun 1945 wa, ise iwaasu ati sisoni di omo eyin ti lo jinna gan-an ni Orile-ede Dominican. O ye ka maa foju sona fun ojo iwaju alayo.

Jehofa Mu Ki Opo Eeyan Wa Kekoo

Ni gbogbo igba ti Leonardo Amor fi wa niluu La Vega, ko seni to wa kekoo otito inu Bibeli. Nje awon eeyan naa a le yi pa da bayii?

Awon Mejilelogun Fi Soosi Sile

Won ni ‘eko nipa esu’ lawon Elerii Jehofa fi n doju igbagbo awon araalu de. Amo Bibeli lawon Elerii fi dahun ibeere tawon eeyan bi won lona to teni lorun.

Jagunjagun Ti Ko Gba Pe Olorun Wa Di Iranse Olorun

Ogbeni Juan Crispín ko gba tele pe Olorun wa, o ronu pe rukerudo lo maa tun aye se. Ki lo mu ko yi pa da di iranse Olorun?

Aditi To Koko Kekoo Otito

Arakunrin José Pérez ni aditi to koko di Elerii ni Orile-ede Dominican. Bawo ni José se ‘gbo’ iwaasu to si loye eko Bibeli ni kikun?

Bi Mo Se Mo Ohun Ti Maa Fi Aye Mi Se

José Estévez ati idile re ti ni nnkan gidi ti won n fi aye won se. Bawo ni won se foju ara won ri i pe Jehofa maa n mu awon ileri re se?

Mi O Fe Sin Olorun Mo

Bo tile je pe Martín Paredes n kekoo ko le di alufaa, igba ka wa ti ko fe sin Olorun mo. Bawo ni iwe kan to ya lowo olusiro owo nile iwe re se yi aye re pa da?