Ìròyìn Ayọ̀ Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run!

Kí ni ìròyìn ayọ̀ látọ̀dọ̀ Ọlọ́run? Kí nìdí tó fi yẹ ká gbà á gbọ́? Ìwé yìí dáhùn àwọn ìbéèrè tí ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń béèrè nípa Bíbélì.

Bó O Ṣe Lè Jàǹfààní Látinú Ìwé Yìí

Ìwé yìí á mú kó o gbádùn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Wo bó o ṣe lè rí ẹsẹ Bíbélì tí wọ́n tọ́ka sí nínú Bíbélì rẹ.

Ẹ̀KỌ́ 1

Kí Ni Ìròyìn Ayọ̀ Náà?

Kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìròyìn tó wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run, ìdí tó fi jẹ́ kánjúkánjú àti ohun tó yẹ kó o ṣe.

Ẹ̀KỌ́ 2

Ta Ni Ọlọ́run?

Ṣé Ọlọ́run ní orúkọ, ǹjẹ́ ó nífẹ̀ẹ́ wa?

Ẹ̀KỌ́ 3

Ṣé Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Ni Ìròyìn Ayọ̀ Ti Wá Lóòótọ́?

Báwo la ṣe mọ̀ pé òótọ́ ni ọ̀rọ̀ inú Bíbélì?

Ẹ̀KỌ́ 4

Ta Ni Jésù Kristi?

Kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìdí tí Jésù fi kú, ohun tí ìràpadà jẹ́ àti ohun tí Jésù ń ṣe ní báyìí.

Ẹ̀KỌ́ 5

Kí Ni Ọlọ́run Ní Lọ́kàn Tó Fi Dá Ayé Yìí?

Bíbélì ṣàlàyé ìdí tí Ọlọ́run fi dá ayé, ìgbà tí ìyà máa dópin, bí ọjọ́ ọ̀la ṣe máa rí àti àwọn tó máa gbé lórí ilẹ̀ ayé.

Ẹ̀KỌ́ 6

Ìrètí Wo Ló Wà fún Àwọn Tó Ti Kú?

Kí ló ń ṣẹlẹ̀ sí wa tá a bá kú? Ṣé a tún lè pa dà rí àwọn èèyàn wa tó ti kú?

Ẹ̀KỌ́ 7

Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run?

Ta ni Ọba Ìjọba Ọlọ́run, kí ni ìjọba náà sì máa ṣe?

Ẹ̀KỌ́ 8

Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Fi Fàyè Gba Ìwà Ibi àti Ìyà?

Báwo ni ìwà ibi ṣe bẹ̀rẹ̀, kí sì nìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gbà á títí di báyìí? Ṣé ìyà máa dópin láé?

Ẹ̀KỌ́ 9

Báwo Ni Ìdílé Rẹ Ṣe Lè Láyọ̀?

Jèhófà, Ọlọ́run aláyọ̀ fẹ́ kí ìdílé láyọ̀. Kà nípa àwọn ìmọ̀ràn Bíbélì tó lè mú kí ọkọ, aya, òbí àtàwọn ọmọ ṣe ojúṣe wọn.

Ẹ̀KỌ́ 10

Báwo Lo Ṣe Lè Mọ Ìsìn Tòótọ́?

Ṣé ìsìn tòótọ́ kan ṣoṣo ló wà? Wo ohun márùn-ún téèyàn lè fi dá ìsìn tòótọ́ mọ̀.

Ẹ̀KỌ́ 11

Báwo Ni Àwọn Ìlànà Bíbélì Ṣe Ń Ṣe Wá Láǹfààní?

Jésù ṣàlàyé ìdí tá a fi nílò ìtọ́sọ́nà àtàwọn ìlànà Bíbélì méjì tó ṣe pàtàkì jù.

Ẹ̀KỌ́ 12

Báwo Lo Ṣe Lè Sún Mọ́ Ọlọ́run?

Kẹ́kọ̀ọ́ kó o lè mọ̀ bóyá gbogbo àdúrà ni Ọlọ́run máa ń gbọ́, mọ bó ṣe yẹ ká máa gbàdúrà àti ohun míì tó lè mú kó o sún mọ́ Ọlọ́run.

Ẹ̀KỌ́ 13

Ìròyìn Ayọ̀ Wo Ló Wà Nípa Ìsìn?

Ṣé ìgbà kan máa wà tí gbogbo èèyàn á jọ máa sin Ọlọ́run kan ṣoṣo?

Ẹ̀KỌ́ 14

Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Fi Ní Ètò Kan?

Bíbélì sọ bá a ṣe ṣètò àwọn Kristẹni tòótọ́ àti ìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀.

Ẹ̀KỌ́ 15

Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Máa Kẹ́kọ̀ọ́ Nìṣó Nípa Jèhófà?

Báwo ni ohun tó o mọ̀ nípa Ọlọ́run àti nípa Bíbélì ṣe máa ṣe àwọn ẹlòmí ì láǹfààní? Irú àjọṣe wo lo máa ní pẹ̀lú Ọlọ́run?