Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

APA 7

Ìlérí tí Ọlọ́run Ṣe Láti Ẹnu Àwọn Wòlíì

Ìlérí tí Ọlọ́run Ṣe Láti Ẹnu Àwọn Wòlíì

ÀWỌN wòlíì tó jẹ́ òjíṣẹ́ Ọlọ́run ní ayé àtijọ́ máa ń gba ohun tí Ọlọ́run bá sọ gbọ́. Wọ́n gbà pé àwọn ìlérí Ọlọ́run máa ṣẹ, wọ́n sì ń gbé ìgbé ayé wọn lọ́nà tó fi hàn pé wọ́n ń retí ìgbà tí àwọn ìlérí náà máa ṣẹ. Ara ìlérí náà rèé.

Kété lẹ́yìn tí Ádámù àti Éfà ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run nínú ọgbà Édẹ́nì, Ọlọ́run ṣèlérí pé òun máa yan ẹnì kan tí yóò fọ́ orí “ejò náà,” èyí tó jẹ́ “dírágónì ńlá náà . . . , ejò ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà, ẹni tí a ń pè ní Èṣù àti Sátánì,” tó ṣì wọ́n lọ́nà, yóò sì pa á run pátápátá. (Jẹ́nẹ́sísì 3:14, 15; Ìṣípayá 12:9, 12) Ta wá ni Ẹni Tí Ń Bọ̀ náà tí yóò fọ́ orí Sátánì?

Ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún ọdún méjì [2,000] lẹ́yìn tí Jèhófà sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa Ẹni Tí Ń Bọ̀ náà, Jèhófà ṣèlérí fún Ábúráhámù tó jẹ́ wòlíì rẹ̀ pé ọ̀kan nínú àtọmọdọ́mọ rẹ̀ ni ẹni náà yóò jẹ́. Ọlọ́run sọ fún Ábúráhámù pé: “Nípasẹ̀ irú-ọmọ [tàbí àtọmọdọ́mọ] rẹ sì ni gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ilẹ̀ ayé yóò bù kún ara wọn nítorí òtítọ́ náà pé ìwọ ti fetí sí ohùn mi.”—Jẹ́nẹ́sísì 22:18.

Ní ọdún 1473 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, Ọlọ́run tún fi iṣẹ́ nípa “irú-ọmọ” náà rán Mósè tó jẹ́ wòlíì rẹ̀. Mósè jíṣẹ́ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì (Israila) pé: “Wòlíì kan láti àárín ìwọ fúnra rẹ, ní àárín àwọn arákùnrin rẹ, bí èmi, ni Jèhófà Ọlọ́run rẹ yóò gbé dìde fún ọ—òun ni kí ẹ̀yin fetí sí.” (Diutarónómì 18:15) Èyí fi hàn pé inú àwọn ọmọ Ábúráhámù ni wòlíì tó ń bọ̀ yìí yóò ti wá, ìyẹn wòlíì tó máa dà bíi Mósè.

Wòlíì ọ̀hún tún máa jẹ́ àtọmọdọ́mọ Dáfídì Ọba, yóò sì di ọba alágbára bíi ti Dáfídì. Ọlọ́run ṣèlérí fún Dáfídì Ọba pé: “Èmi yóò gbé irú-ọmọ rẹ dìde lẹ́yìn rẹ dájúdájú . . . èmi yóò fìdí ìtẹ́ ìjọba rẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in fún àkókò tí ó lọ kánrin.” (2 Sámúẹ́lì 7:12, 13) Ọlọ́run tún jẹ́ ká mọ̀ pé wòlíì tó jẹ́ àtọmọdọ́mọ Dáfídì yìí ni a ó tún máa pè ní “Ọmọ Aládé Àlàáfíà,” ó sì sọ pé: “Ọ̀pọ̀ yanturu ìṣàkóso ọmọ aládé àti àlàáfíà kì yóò lópin, lórí ìtẹ́ Dáfídì àti lórí ìjọba rẹ̀ láti lè fìdí rẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in àti láti gbé e ró nípasẹ̀ ìdájọ́ òdodo àti nípasẹ̀ òdodo, láti ìsinsìnyí lọ àti títí dé àkókò tí ó lọ kánrin.” (Aísáyà 9:6, 7) Èyí fi hàn pé Aṣáájú tó jẹ́ olódodo yìí yóò mú kí àlàáfíà àti ìdájọ́ òdodo tún pa dà wà kárí ayé. Ìgbà wo wá ni Aṣáájú náà yóò dé?

Irú-ọmọ” tí Ọlọ́run ṣèlérí yóò jẹ́ àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù yóò jẹ́ wòlíì bíi ti Mósè yóò wá látinú ìran Dáfídì yóò dé ní ọdún 29 Sànmánì Kristẹni yóò pa ejò náà, ìyẹn Sátánì, run

Áńgẹ́lì tó ń jẹ́ Gébúrẹ́lì (Jibrilu) sọ fún Dáníẹ́lì tó jẹ́ wòlíì Ọlọ́run pé: “Kí o mọ̀, kí o sì ní ìjìnlẹ̀ òye pé láti ìjáde lọ ọ̀rọ̀ náà láti mú Jerúsálẹ́mù padà bọ̀ sípò àti láti tún un kọ́ títí di ìgbà Mèsáyà Aṣáájú, ọ̀sẹ̀ méje yóò wà, àti ọ̀sẹ̀ méjì-lé-lọ́gọ́ta.” (Dáníẹ́lì 9:25) Iye ọ̀sẹ̀ náà jẹ́ ọ̀sẹ̀ mọ́kàndínláàádọ́rin [69]. Ọ̀sẹ̀ kọ̀ọ̀kan dúró fún ọdún méje. Nítorí náà, àròpọ̀ iye ọdún tó wà nínú ọ̀sẹ̀ mọ́kàndínláàádọ́rin yìí yóò wá jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́rin àti ọgọ́rin ó lé mẹ́ta [483]. Àwọn ọdún yìí bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 455 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, ó sì parí ní ọdún 29 Sànmánì Kristẹni. a

Ǹjẹ́ Mèsáyà (al-Masihu) yìí dé ní ọdún 29 Sànmánì Kristẹni lóòótọ́, ìyẹn Mèsáyà tí òun náà jẹ́ wòlíì bíi ti Mósè, tó sì tún jẹ́ “irú-ọmọ” tí wọ́n ti ń retí tipẹ́tipẹ́? Jẹ́ ká wò ó bóyá ó dé lóòótọ́.