Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀KỌ́ 2

Kí Nìdí Tí Wọ́n Fi Ń Pè Wá Ní Ẹlẹ́rìí Jèhófà?

Kí Nìdí Tí Wọ́n Fi Ń Pè Wá Ní Ẹlẹ́rìí Jèhófà?

Nóà

Ábúráhámù àti Sérà

Mósè

Jésù Kristi

Ọ̀pọ̀ èèyàn rò pé ẹ̀sìn tuntun ni ẹ̀sìn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àmọ́, ṣáájú ẹgbẹ̀rún méjì ó lé ọgọ́rùn-ún méje (2,700) ọdún sẹ́yìn ni Bíbélì ti pe àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà ní “ẹlẹ́rìí” rẹ̀. (Àìsáyà 43:10-12) Ṣáájú ọdún 1931, orúkọ tí wọ́n ń pè wá ni àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Kí nìdí tí a fi wá ń jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà?

Orúkọ náà ń jẹ́ káwọn èèyàn mọ Ọlọ́run wa. Àwọn ìwé àfọwọ́kọ àtijọ́ fi hàn pé orúkọ Ọlọ́run, ìyẹn Jèhófà, fara hàn ní ọ̀pọ̀ ẹgbẹ̀rún ìgbà nínú Bíbélì. Nínú ọ̀pọ̀ Bíbélì, wọ́n ti fi orúkọ oyè bí Olúwa tàbí Ọlọ́run rọ́pò orúkọ yìí. Síbẹ̀, nígbà tí Ọlọ́run tòótọ́ fara han Mósè, ó lo orúkọ tó ń jẹ́ gangan, ìyẹn Jèhófà, ó sì sọ pé: “Èyí ni orúkọ mi títí láé.” (Ẹ́kísódù 3:15) Ọ̀nà yìí ni Ọlọ́run gbà fi hàn pé òun yàtọ̀ sí gbogbo àwọn ọlọ́run èké. Inú wa dùn pé wọ́n ń fi orúkọ mímọ́ ti Ọlọ́run pè wá.

Orúkọ náà ń jẹ́ káwọn èèyàn mọ iṣẹ́ wa. Ọ̀pọ̀ èèyàn nígbà àtijọ́ fi ẹ̀rí hàn pé àwọn ní ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà, èyí sì bẹ̀rẹ̀ látọ̀dọ̀ ọkùnrin olóòótọ́ náà Ébẹ́lì. Láti ọ̀pọ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún ni àwọn èèyàn bíi Nóà, Ábúráhámù, Sérà, Mósè, Dáfídì àti àwọn míì ti wà lára ọ̀pọ̀ “àwọsánmà àwọn ẹlẹ́rìí” yìí. (Hébérù 11:4–12:1) Bíi ti ẹni tó ń ṣe ẹlẹ́rìí nílé ẹjọ́ fún ẹni tí kò jẹ̀bi ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án, a fẹ́ kí àwọn èèyàn mọ òtítọ́ nípa Ọlọ́run wa.

À ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù. Bíbélì pe Jésù ní ‘ẹlẹ́rìí olóòótọ́ tó ṣeé gbára lé.’ (Ìfihàn 3:14) Jésù fúnra rẹ̀ sọ pé òun ‘jẹ́ kí àwọn èèyàn mọ orúkọ Ọlọ́rùn’ òun sì ń “jẹ́rìí sí òtítọ́” nípa Ọlọ́run. (Jòhánù 17:26; 18:37) Nítorí náà, àwọn ojúlówó ọmọlẹ́yìn Kristi gbọ́dọ̀ máa jẹ́ orúkọ mọ́ Jèhófà kí wọ́n sì jẹ́ kí àwọn èèyàn mọ orúkọ náà. Ohun tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe nìyẹn.

  • Kí nìdí tí àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì fi wá ń jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà?

  • Ìgbà wo ni Jèhófà ti bẹ̀rẹ̀ sí í ní àwọn ẹlẹ́rìí lórí ilẹ̀ ayé?

  • Ta ni Ẹlẹ́rìí tó ga jù lọ tí Jèhófà ní?