Ẹ̀KỌ́ 16
Kí Ni Ojúṣe Àwọn Ìránṣẹ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́?
Bíbélì sọ pé àwùjọ méjì ni àwọn ọkùnrin tó ń bójú tó àwọn iṣẹ́ nínú ìjọ Kristẹni pín sí, ìyẹn sì ni “àwọn alábòójútó àti àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́.” (Fílípì 1:1) Àwọn alábòójútó àti ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tó wà ní ìjọ kọ̀ọ̀kan máa ń tó bíi mélòó kan. Àwọn iṣẹ́ tó ń ṣe wá láǹfààní wo ni àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ ń ṣe?
Wọ́n ń ran ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà lọ́wọ́. Àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ jẹ́ àwọn ọkùnrin tó ń fi ọwọ́ pàtàkì mú ìjọsìn Ọlọ́run, wọ́n ṣeé fọkàn tán, wọ́n sì máa ń fara balẹ̀ ṣe nǹkan, àwọn kan lára wọn jẹ́ ọ̀dọ́, àwọn míì sì jẹ́ àgbà. Wọ́n ń bójú tó àwọn iṣẹ́ tó jẹ mọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba àti àwọn iṣẹ́ pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ míì tó ṣe pàtàkì àmọ́ tí kì í ṣe iṣẹ́ àbójútó ìjọ. Èyí jẹ́ kí àwọn alàgbà lè gbájú mọ́ iṣẹ́ kíkọ́ni àti ṣíṣe olùṣọ́ àgùntàn.
Wọ́n ń ṣe àwọn iṣẹ́ tó ń ṣeni láǹfààní. A máa ń yan àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ kan pé kí wọ́n jẹ́ olùtọ́jú èrò, kí wọ́n máa kí àwọn tó bá wá sí ìpàdé káàbọ̀. Àwọn míì máa ń bójú tó ẹ̀rọ tó ń gbé ohùn sáfẹ́fẹ́, ìwé ìròyìn tàbí àkọsílẹ̀ ìnáwó ìjọ, àwọn kan sì máa ń fún àwọn ará ìjọ ní ibi tí wọ́n á ti wàásù. Wọ́n tún máa ń ṣèrànwọ́ láti tún Gbọ̀ngàn Ìjọba ṣe. Àwọn alàgbà lè ní kí wọ́n ran àwọn àgbàlagbà lọ́wọ́. Iṣẹ́ èyíkéyìí tí wọ́n bá fún àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ pé kí wọ́n ṣe, wọ́n máa ń ṣe é tinútinú, èyí sì ń mú kí gbogbo èèyàn bọ̀wọ̀ fún wọn.—1 Tímótì 3:13.
Wọ́n ń fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni. Àwọn ìwà rere tó yẹ Kristẹni tí àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ ní ló mú ká yàn wọ́n sípò. Tí wọ́n bá ṣiṣẹ́ ní ìpàdé, ó máa ń mú kí ìgbàgbọ́ wa túbọ̀ lágbára. Bí wọ́n ṣe ń mú ipò iwájú lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ń jẹ́ kí ìtara wa pọ̀ sí i. Bí wọ́n ṣe ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn alàgbà ń mú kí ayọ̀ àti ìṣọ̀kan gbilẹ̀. (Éfésù 4:16) Tó bá yá, àwọn náà lè kúnjú ìwọ̀n láti di alàgbà.
-
Àwọn wo là ń pè ní ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́?
-
Kí làwọn ìránṣẹ́ máa ń ṣe láti mú kí nǹkan máa lọ déédéé nínú ìjọ?