Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

APÁ KẸSÀN-ÁN

Ẹ Jọ Máa Sin Jèhófà Nínú Ìdílé Yín

Ẹ Jọ Máa Sin Jèhófà Nínú Ìdílé Yín

“Ẹ jọ́sìn Ẹni tí ó dá ọ̀run àti ilẹ̀ ayé.”Ìṣípayá 14:7

Àwọn ohun tí o kọ́ nínú ìwé yìí ti jẹ́ kí o rí i pé ọ̀pọ̀ ìlànà tó lè ran ìwọ àti ìdílé rẹ lọ́wọ́ wà nínú Bíbélì. Jèhófà fẹ́ kí o máa láyọ̀. Ó ṣèlérí pé tí o bá fi ìjọsìn rẹ̀ sí ipò àkọ́kọ́, ‘gbogbo nǹkan mìíràn wọ̀nyí ni a ó fi kún un fún ọ.’ (Mátíù 6:33) Ó wù ú gan-an pé kí o jẹ́ ọ̀rẹ́ òun. Máa lo gbogbo àǹfààní tí o bá ní láti mú kí àjọṣe rẹ pẹ̀lú Ọlọ́run túbọ̀ lágbára. Èyí ni àǹfààní tó dára jù lọ tí èèyàn lè ní.Mátíù 22:37, 38.

1 TÚBỌ̀ SÚN MỌ́ JÈHÓFÀ

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ:“‘Èmi yóò . . . jẹ́ baba yín, ẹ ó sì jẹ́ ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin mi,’ ni Jèhófà . . . wí.” (2 Kọ́ríńtì 6:18) Ọlọ́run fẹ́ kí o di ọ̀rẹ́ òun tímọ́tímọ́. Ọ̀nà kan tí a lè gbà di ọ̀rẹ́ Jèhófà ni pé ká máa gbàdúrà sí i. Jèhófà gbà wá níyànjú pé ká “máa gbàdúrà ní àìsinmi.” (1 Tẹsalóníkà 5:17, Bíbélì Mímọ́) Ó máa ń wù ú láti fetí sílẹ̀ tí o bá ń sọ èrò inú rẹ lọ́hùn-ún àtàwọn ohun tó ń jẹ ọ́ lọ́kàn. (Fílípì 4:6) Tí o bá ń gbàdúrà pẹ̀lú àwọn tó wà nínú ìdílé rẹ, wọ́n á mọ bí o ṣe sún mọ́ Ọlọ́run tó.

Láfikún sí bíbá Ọlọ́run sọ̀rọ̀, ó tún yẹ kí o máa tẹ́tí sí i. O lè tẹ́tí sí Ọlọ́run tí o bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ àtàwọn ìwé tàbí ìtẹ̀jáde tó dá lórí Bíbélì. (Sáàmù 1:1, 2) Máa ronú jinlẹ̀ lórí àwọn ohun tí o bá kọ́. (Sáàmù 77:11, 12) Lára ọ̀nà tí o lè gbà máa tẹ́tí sí Ọlọ́run ni pé kí o máa wá sí ìpàdé àwa Ẹlẹ́rìí ­Jèhófà déédéé.Sáàmù 122:1-4.

Ọ̀nà pàtàkì míì tí o lè gbà mú kí àjọṣe rẹ pẹ̀lú Ọlọ́run dára sí i ni pé kí o máa bá àwọn míì sọ̀rọ̀ nípa Jèhófà. Bí o bá túbọ̀ ń ṣe bẹ́ẹ̀, wàá túbọ̀ máa sún mọ́ ọn.Mátíù 28:19, 20.

OHUN TÍ O LÈ ṢE:

  • Máa wá àyè láti gbàdúrà kí o sì máa ka Bíbélì lójoojúmọ́

  • Nínú ìdílé yín, ẹ máa fi àwọn nǹkan tẹ̀mí ṣáájú eré ìnàjú àti fàájì

2 Ẹ MÁA ṢE ÌJỌSÌN ÌDÍLÉ

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ: “Ẹ sún mọ́ Ọlọ́run, yóò sì sún mọ́ yín.” (Jákọ́bù 4:8) Ó yẹ kí ẹ ṣètò bí ẹ ó ṣe máa jọsìn Ọlọ́run nínú ìdílé yín, kí ẹ sì máa tẹ̀ lé ètò náà. (Jẹ́nẹ́sísì 18:19) Àmọ́ kò mọ síbẹ̀ o. Ó tún yẹ kí o máa rántí Ọlọ́run nínú gbogbo ohun tí o bá ń ṣe lójoojúmọ́. O lè mú kí ìdílé rẹ túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run tí o bá ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ “nígbà tí o bá jókòó nínú ilé rẹ àti nígbà tí o bá ń rìn ní ojú ọ̀nà àti nígbà tí o bá dùbúlẹ̀ àti nígbà tí o bá dìde.” (Diutarónómì 6:6, 7) Pinnu pé wàá tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jóṣúà tó sọ pé: “Ní tèmi àti agbo ilé mi, Jèhófà ni àwa yóò máa sìn.”Jóṣúà 24:15.

OHUN TÍ O LÈ ṢE:

  • Ẹ jọ máa kẹ́kọ̀ọ́ déédéé, kí ẹ̀kọ́ náà sì dá lórí àwọn ohun tí ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú ìdílé yín nílò